Bàbá Fẹ́ràn Rẹ láti ọwọ́ Pete BriscoeÀpẹrẹ

Ọjọ́ 12
Baba Rẹ Tí Kò Yí Padà Jẹ́ Olótìítọ́
Ìfẹ́ Rẹ kì í kùnà,
Kìí fi ẹni sílẹ̀,
Kò ní tán lára mi láé. —“One Thing Remains” nipasẹ Jesus Culture
Àwọn bàbá kì í fi bẹ́ẹ̀ ráyè. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń ṣe iṣẹ́ tí ó gba pé kí wọ́n pa ọkàn pọ̀, kí wọ́n lo gbogbo okun wọn àti àkókò wọn. Ní ìgbà míràn, wọ́n máa ń lo àkókò wọn fún eré ìdárayá, gólòfì, àti eré bọ́ọ̀lù orí tẹlifíṣọ̀n tí wọ́n máa ń ṣe ní òpin ọ̀sẹ̀… tí wọ́n ń fi àwọn apá ibò mìràn nínú ìgbésí ayé wọn sílẹ̀ (bíi àwọn ọmọ wọn), tí wọ́n ń pa tì tí wọ́n sì ń gbàgbé.
Ọlọ́run kò ní bílíọ̀nù ènìyàn láti bá sọ̀rọ̀ nìkan, ó tún ní àgbáyé tó kù láti bá ṣeré. Ó ṣeé ṣe wípé àwọn inú iṣẹ́ tí àwọsánmà wu Ọlọ́run ju ohunkohun tí a ní láti ṣe! Síbẹ̀, kí ni Bíbélì sọ fún wa nípa ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwa ènìyàn?
“Olúwa, Olúwa, Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, Ẹni tí ń lọ́ra láti bínú, tí ó kún fún inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti ìṣòtítọ́, tí ń pa ìfẹ́ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún, tí ó sì ń dárí ìṣìnà àti ìrélànàkọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ jì.” (Ẹ́kísódù 34:6-7)
Nítorí pé Ọlọ́run ni Ọlọ́run, kò sí ohun tí ó lè pín ọkàn rẹ̀ níyà; kò sí ohun tí ó lè sú u. Ó ní gbogbo ohun tí ó nílò nísinsìnyí. Kò sí ìdí kankan tí ó fi ní láti fi ọ́ sílẹ̀, tàbí kó pa ọ́ tì, tàbí kí ó lọ sí ibòmíràn.
Ó jẹ́ olùṣòtítọ́.
Bàbá mi jẹ́ olóòótọ́ ènìyàn. Kódà, mo mọ ohun tí mo máa sọ nípa rẹ̀ ní ibi ìsìnkú rẹ̀: "Ó jẹ́ olótìítọ́ sí Olùgbàlà rẹ̀, sí ìyàwó rẹ̀, àti sí ìpè rẹ̀. A ní ayọ̀ pé irú àpẹẹrẹ ìṣòtítọ́ bẹ́ẹ̀ wà nínú ìdílé wa." Àmọ́ ní ìfiwéra pẹ̀lú Ọlọ́run, ìdúróṣinṣin bàbá mi ò tó nǹkan. Ọlọ́run kì í yí padà, kì í kùnà, kì í sì í yí'sẹ̀.
Ní ìgbà tí a bá gbàgbọ́ nínú ìdúróṣinṣin Rẹ̀, àlàáfíà àti ìtura máa ń dé sórí ọkàn wa tí ó ń bẹ̀rù. Kò ní lọ sí ibì kankan; yóò pa àwọn ìlérí Rẹ̀ mọ́; yóò sì mú àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ṣẹ. Èyí ni ó mú kí ìgbàgbọ́ wa ṣeé ṣe àti jẹ́ òtítọ́.
Bàbá, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ fún ìdúróṣinṣin Rẹ tí kò ṣeé díye lé, fún jíjẹ́ Ẹni tí kì í yẹ̀ nínú ìgbésí ayé mi, fún rere tàbí fún búburú. Mo gba àdúrà pé kí O ràn mí lọ́wọ́ kí n lè fi ìlérí wíwà Rẹ̀ sí ọkàn, kí O sì ràn mí lọ́wọ́ kí n lè rántí Rẹ̀ ní ìgbà tí mo bá nílò Rẹ̀ jù lọ. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

A ti kọ́ wa láti kékeré pé Ọlọ́run ni Bàbá wa àti pé àwa jẹ́ ọmọ Rẹ̀. Ṣùgbọ́n níní ìbátan pẹ̀lú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Bàbá kì í rọrùn nígbà gbogbo—àgàgà bí àwọn bàbá wa ti orí ilẹ̀ ayé bá ń sapá láti fi ìfẹ́ tí a ń fẹ́ hàn wá. Nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́rìndínlógún yìí, Pete Briscoe fa àfiyèṣí wa ṣọ́dọ̀ Ọlọ́run tó ń tẹ́ gbogbo àwọn èròngbà ìfẹ́ lọ́rùn—ó ń fi hàn bí Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé ó jẹ́ Bàbá wa rere àti Bàbá wa pípé.
More