Bàbá Fẹ́ràn Rẹ láti ọwọ́ Pete BriscoeÀpẹrẹ

The Father Loves You by Pete Briscoe

Ọjọ́ 10 nínú 16

ọjọ́ kewa

Sùúrù pípé tí Bàbá

Olúwa, fún mi ni sùúrù, ki o si fi fun mi NÍSINSÌNYÍ!

Rántí wípé nígbà tí mo mẹ́nu bá pé àwọn ènìyàn sábà máa ń gbé ojú ìwòye wọn nípa Ọlọ́run karí bí àwọn baba wọn ti orí ilẹ̀ ayé ṣe rí? Nígbàtí ọpọlọpọ awọn kan wà ti wọn ni awọn baba tí ó gbayì ti o sì nifẹ, bẹ́ẹ̀ ni diẹ ninu awọn èniyàn ni àdàmọ̀-di-bàbá kan ti o ń binu nígbà gbogbo si idile rẹ. Boya o fí ìgbónára ohun tí ó koju kanra mọ àwọn tí kò tó láti wo ojú rẹ. Tabi boya o gbe awọn eniyan ti o sunmọ ká ibi gíga tí kò tọ́ sì wọn tí aisedede wọn sì fà ìkanra. Láì-bìkítà orisun, awọn ibinu bàbá le mu awọn eniyan ro pe Ọlọrun Baba dabiwọnbaba—binu si gbogbo eniyan ati ohun gbogbo. Iyẹn kii ṣe aṣiṣe nikan ṣugbọn o lodi si ohun ti Bibeli sọ fun wa!

Ọlọ́run fi ara re han Mose gegebi Baba ti o " Ó lọra lati bínú..." ( Ẹ́kísódù 34:6). Dafidi si kọrin Baba pelu awon ọ̀rọ̀ wonyi

OLUWA jẹ́ aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́... Bí Bàbá tí ìṣe ìyọnu sì àwọn ọmọ, bẹ́ẹ̀ ní OLUWA ń ṣe ìyọnu sì àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀; nítorí ó mọ bí a ṣe dá wa, ó rántí pé erùpẹ̀ ni àwa ( Orin Dafidi 103:8, 13-14)

Ọlọ́run bàbá ni sùúrù .

Mo n kọ eyi ni ọna lile. Mo ti ṣe akọ́ni-mọ̀ọ́gbá fún àwọn ọdún diẹ ninu awọn ikẹkọ bọọlu inu agbọn. Nígbàtí ọmọ mi Liam wá ní kekere ni ile-iwe alakọbẹrẹ, tí ó ní àwọn awọn ọdun diẹ láti ló sì ẹkọ ni iwaju rẹ kì ó tó jade, mo (ni ìdójútini) nireti pe yoo lè ṣe bí mo ṣe ńṣe gẹ́lẹ́ nigbati mo ń gbá bọ́ọ̀lù ni kọlẹji! Mó rí nǹkan tí ó ńṣe, bẹ́ẹ̀ ni mo ń retí ohun míràn, láti ọwọ rẹ, ìṣe mi pẹlu rẹ dà bi "akọ́ni-mọ̀ọ́gbá” lingo, mo wo oju rẹ ó wú ó sì kún fún omijé. Oh, bawo ni í bá ṣe rí ní ìgbà míràn bí mo ṣe ni lọ́kàn pé kí ó jẹ Ọlọ́run fúnra Rẹ ni ó jẹ akọ́ni-mọ̀ọ́gbá ẹgbẹ́ yẹn kí ó má jẹ èmi! Èmi kò ni sùúrù pẹlu rẹ rara, nireti pe yoo jẹ ohun ti ó yẹ kí ó jẹ ni ọjọ kan.

Ọlọrun mọ awọn ailera wa. Ó mọ bí a ṣe dá wa, kò mú nǹkan lè koko fún wa tàbí kó yẹra fún wa bí àwọn míràn ṣe máà ń ṣe nígbà tí a bá ṣe àṣìṣe. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé, Ó rí wa bí a ṣe wà “nínú Kristi” ó sì mọ dájú láti mú wa jẹ ẹniti o yẹ ká jẹ́. .Ó mọ ìlànà ìlọsíwájú àti ìdàgbàsókè wa, ó sì ní sùúrù pẹ̀lú wa dáradára bí a ṣe ń gbé ìgbésẹ̀ ni ọna wa.Emi ko mọ nipa tìrẹ, ṣugbọn inu mi dun pe a ni Baba bi iyẹn!

Bàbá, sùúrù rẹ pọ jọjọ, ó rinlẹ̀ ó sì kún fún ifẹ. Emi ko yẹ iru ẹni tí ó yẹ kí a bìkítà fún, nitorinaa mó dupẹ lọwọ Rẹ pé Ó bìkítà fún mi to lati ṣe bii iyẹn si mi. Mó gbàdúrà pé sùúrù yi yoo fi ara hàn nínú ìgbésí ayé mi àti nínú ìbálòpọ̀ mi pẹ̀lú awọn miiran ki wọn le ri ohun ti O ti ṣe ninu ayé mi! Amin.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

The Father Loves You by Pete Briscoe

A ti kọ́ wa láti kékeré pé Ọlọ́run ni Bàbá wa àti pé àwa jẹ́ ọmọ Rẹ̀. Ṣùgbọ́n níní ìbátan pẹ̀lú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Bàbá kì í rọrùn nígbà gbogbo—àgàgà bí àwọn bàbá wa ti orí ilẹ̀ ayé bá ń sapá láti fi ìfẹ́ tí a ń fẹ́ hàn wá. Nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́rìndínlógún yìí, Pete Briscoe fa àfiyèṣí wa ṣọ́dọ̀ Ọlọ́run tó ń tẹ́ gbogbo àwọn èròngbà ìfẹ́ lọ́rùn—ó ń fi hàn bí Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé ó jẹ́ Bàbá wa rere àti Bàbá wa pípé.

More

A fẹ́ dúpẹ́ l'ọ́wọ́ Pete Briscoe fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ si, jọ̀wọ́ lọ sí: http://petebriscoe.org/