Bàbá Fẹ́ràn Rẹ láti ọwọ́ Pete BriscoeÀpẹrẹ

Ọjọ́ 16
Láti Kókó-ọ̀rọ̀ sí Ìgbàgbọ́
Kìí ṣe àwọn apákan Bíbélì tí kò yé mi ni ó ń kọ mí ní ominú, àwọn apá ibi tí ó yé mi ni. —Mark Twain
Ìsíníyè ni ojúṣe ń bá kó égbẹ́ pọ̀. Ìmọ̀ ni àǹfààní ń bá k'ẹ́gbẹ́. Báyìí gan-an ni ó rí pẹ̀lú Ọlọ́run gẹ́gẹ́bí Bàbá wa tí ó pé. A lè kọ́ gbogbo kókó-ọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run láìnira. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ a ṣetán láti jẹ́ kí Ẹ̀mímímọ́ gbé ní inú wa ní ọ̀nà tí ó jẹ́ pé àwọn kókó-ọ̀rọ̀ náà yíó di ìgbàgbọ́?
Ìlú Jerúsálẹ́mù kò ṣí ipò padà láti orí kókó-ọ̀rọ̀ sí ìgbàgbọ́. Bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn wòlíì wá láti ìgbà dé ìgbà, àwọn ènìyàn Jerúsálẹ́mù sì yàn láti gbé láìní Ọlọ́run.
Egbé ni fún ilú aninilára nì,
ọlọ̀tẹ̀ àti aláìmọ́!
Òun kò fetísí ohùn náà,
òun kò gba ẹ̀kọ́.
Òun kò gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA,
òun kò súnmọ́ ọ̀dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀. (Sẹfanáyà 3: 1-2)
Káàsà. Àdánù ńlá! Mímọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run dàbíi ìfìwépè sí ọdún àgbàayanu ńla. Ìwọ ṣí ìfìwépè náà, ó kà báyìí pé:
Ìwọ! Wá jẹ àsè pẹ̀lú Mi! Wá sinmi pẹ̀lú Mi! Wá bí o ṣe wà gẹ́lẹ́, kí o sì wà pẹ̀lú Mi! Fí ìdáhún ránṣẹ́ ní kánkán, Ọlọ́run.
Bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, ní báyìí, láti mú kí ọkàn rẹ fi ojú sun ọ̀kan lára àwọn àbùdá Rẹ̀—kókó-ọ̀rọ̀ kan tí Ó fẹ́ kí o sọ di ìgbàgbọ́ lónìí:
- Ó wà ní ìtòsí
- Ó ń tu'ni nínú
- Ó ń ya ẹni sí ọ̀tọ̀
- Ó ń pèsè
- Ó ń dun ni nínú
- Ó nífẹ̀ẹ́
- Aláànú ni
- Olóoore-ọ̀fẹ́ ni
- Ó ní sùúrù
- Ó yẹ fún ìyìn
- Ó jẹ́ olóòtọ́
- Ó ń dáríjì
- Ó pé
- Ó ní ìfẹ́
Baba, gba òtítọ́ kan yìí nípa ẹni tí O jẹ́ kí O sì mú kí ó bá ayé mi dọ́gba. Mo sinmi nínú Rẹ báyìí. Mo dá ìlàlàkà mi dúró. Mo bèèrè pé, nínú Jèsú Ìwọ yíó darí mi, fún mi ní ìgbẹkẹ̀lé nínú Rẹ, Ìwọ yíó sì fà mí sí inú ìbáṣepọ̀ tí ó jinlẹ̀ pẹ̀lú Rẹ nítorí òtítọ́ yìí. Àmín.
Gba àwọn ẹ̀kọ́ sí í láti ọwọ́ Pete pẹ̀lú àyọkà ojoojúmọ́ sí inú àpò-ìfìwéjíṣẹ́ rẹ!
Àṣàrò:
1) Èwo nínú àbùdà Ọlọ́run gẹ́gẹ́bí Baba ló sọ sí ọ ní ọkàn jú? Kíni ìdí?
2) Bàwo ni àgbélèbú ṣe jẹ́ ìfihàn alágbára ti àbùdá Ọlọ́run gẹ́gẹ́bíi Baba?
3) Ní àwọn ọ̀nà wo ní ẹ̀kọ́ yìí ti fi ìdí ìbáṣepọ̀ rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run bíi Bàbá rẹ múlẹ̀ sí i?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

A ti kọ́ wa láti kékeré pé Ọlọ́run ni Bàbá wa àti pé àwa jẹ́ ọmọ Rẹ̀. Ṣùgbọ́n níní ìbátan pẹ̀lú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Bàbá kì í rọrùn nígbà gbogbo—àgàgà bí àwọn bàbá wa ti orí ilẹ̀ ayé bá ń sapá láti fi ìfẹ́ tí a ń fẹ́ hàn wá. Nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́rìndínlógún yìí, Pete Briscoe fa àfiyèṣí wa ṣọ́dọ̀ Ọlọ́run tó ń tẹ́ gbogbo àwọn èròngbà ìfẹ́ lọ́rùn—ó ń fi hàn bí Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé ó jẹ́ Bàbá wa rere àti Bàbá wa pípé.
More