Eks 34:5-7

Eks 34:5-7 YBCV

OLUWA si sọkalẹ ninu awọsanma, o si bá a duro nibẹ̀, o si pè orukọ OLUWA. OLUWA si rekọja niwaju rẹ̀, o si nkepè, OLUWA, OLUWA, Olọrun alãnu ati olore-ọfẹ, onipamọra, ati ẹniti o pọ̀ li ore ati otitọ; Ẹniti o npa ãnu mọ́ fun ẹgbẹgbẹrun, ti o ndari aiṣedede, ati irekọja, ati ẹ̀ṣẹ jì, ati nitõtọ ti ki ijẹ ki ẹlẹbi lọ laijiyà; a ma bẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn omọ, ati lara awọn ọmọ ọmọ, lati irandiran ẹkẹta ati ẹkẹrin.