Bàbá Fẹ́ràn Rẹ láti ọwọ́ Pete BriscoeÀpẹrẹ

Ọjọ́ 1
Ọ̀kan Kò J'ọ̀kan Ní Àwọn Nǹkan Wọnyi
Kì í ṣe ẹni tí bàbá mi jẹ́ ló ṣe pàtàkì; bí kò ṣe ẹni tí mo rántí pé ó jẹ́ ló ṣe pàtàkì. —Anne Sexton
Àwọn ènìyàn sábà máa ń gbé ìwòye wọn nípa Ọlọ́run lórí ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá pè ní "baba" nínú ayé yìí. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ àwọn bàbá ayé lè ní àwòrán dáradára bí tí Baba wa ti mbẹ l'ọ̀run bí? Ṣé Ọlọ́run náà rí bíi tiwọn bí?
Ó gbé ara lè nǹkan
Fún ti àwọn kan lára wa, 'baba' ṣe okùnfà ìmọ̀lára ìtura àti ààbò. Àwọn míràn sì wà tó jẹ́ 1 bí wọ́n ṣe ń ronú nípa bí bàbá wọn ṣe ń gbé ìṣìsẹ́ ni wọ́n á lọ sá pamọ́. Ó tilẹ̀ le yí ojú padà sí baba rẹ ki o si sọ fún pé "Ti Ọlọrun ba ri bi arúgbó mi yí, Emi ko fẹ ohunkohun lati ṣe pẹlu rẹ.”
Nítorí náà nígbà tí a bá ń sọ nípa "Ọlọ́run Baba,"èrò ọkàn wa,— kì í ṣe ẹ̀dùn ọkàn wa— ni ó gbọ́dọ̀ jẹ́ gàba . A gbọ́dọ̀ mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín bàbá wa orí ilẹ̀ ayé àti Baba wa ti mbẹ li ọ̀run. Ẹ̀mí Mímọ́ yóò nílò Bíbélì - kìí ṣe imolara tàbí ìrírí ayé wa - láti jẹ́ atọ́nà wa bí a ti ń mọ ohun tí "Ọlọ́run Baba túmọ̀ sí.”
Gbé ohun tí Mósè béèrè nínú ìwé Ẹ́kísódù yẹ̀ wò, kí o sì ṣe àmúlò rẹ bí a ṣe ń ṣe àwárí nínú ìwé Mímọ́ nípa amuyẹ́ àti ìtaniyọ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí baba:
Bí Ó bá ní inú dídùn sími, kọ́ mi ní àwọn ọ̀nà rẹ kí n lè mọ̀ ọ́, kí n sì máa rí ojú rere arẹ (Ẹ́kísódù 33:13)
Nínú àwọn ẹ̀kọ́ tí ó tẹle ìbéèrè Mósè, Ọlọ́run dáhùn láti ṣe àfihàn àwọn ìwà bàbà tí kò dín ni mẹ́rìnlá nípa Òun fúnra Rẹ̀ —ọ̀kọ̀ọ̀kan èyí tí a ṣe àmúgbòrò rẹ káàkiri nínú Bíbélì.
Àwọn abuda wọ̀nyí jẹ àpẹẹrẹ ìyanu fún ohun tí awọn bàbà jẹ níbi lórí ilẹ̀ ayé, ṣùgbọ́n wọn kò pinnu láti jẹ̀bi ìrìn àjò ti ó mú ìtìjú wá sínú ojúṣe dáradára.dípò bẹ́ẹ̀, kí wọ́n fún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run ní ìṣìírí pẹ̀lú ìròyìn àgbàyanu làti ọ̀dọ̀ òbí wa tí ó kún ojú òṣùwọ̀n láti máà tọju wa, b'uyì fún wa, àti láti pọ́n wá lé. .
Baba, mo gbàdúrà pé kí òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Rẹ mú gbogbo èrò òdì tí mo ní nípa Rẹ kúrò. Mo fẹ́ mọ̀ Ọ́, mo sì fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Rẹ lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu tí kò ní sí èrò òdì. Jọ̀wọ́ ràn mí lọ́wọ́ láti fọ èrò inú mi mọ́ kí Ẹ̀mí Rẹ lè darí mi sí òtítọ́. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

A ti kọ́ wa láti kékeré pé Ọlọ́run ni Bàbá wa àti pé àwa jẹ́ ọmọ Rẹ̀. Ṣùgbọ́n níní ìbátan pẹ̀lú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Bàbá kì í rọrùn nígbà gbogbo—àgàgà bí àwọn bàbá wa ti orí ilẹ̀ ayé bá ń sapá láti fi ìfẹ́ tí a ń fẹ́ hàn wá. Nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́rìndínlógún yìí, Pete Briscoe fa àfiyèṣí wa ṣọ́dọ̀ Ọlọ́run tó ń tẹ́ gbogbo àwọn èròngbà ìfẹ́ lọ́rùn—ó ń fi hàn bí Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé ó jẹ́ Bàbá wa rere àti Bàbá wa pípé.
More