Bàbá Fẹ́ràn Rẹ láti ọwọ́ Pete BriscoeÀpẹrẹ

Ọjọ́ 14
Ìṣe-Pàtàkì Ìdájọ́-Òdodo
Gbogbo ènìyàn ni ó fẹ́ ríi pé a ṣe ìdájọ́-òdodo fún ẹlòmíràn. —Bruce Cockburn
Nínú àwọn ìdílé kan, bàbá a máa bá ọmọ wí ní ọ̀nà tí kò tọ́. Bóyá ó rorò jù mọ́ ọmọ fún èdè-àìyé-èdè ráńpẹ́ nínú ilé, tàbí bóyá ó fà sẹ́yìn láti ṣe ohun rere fún wọn láìsí ìdí pàtàkì kankan.
Àwọn bàbá nípa ti ara a máa ṣi agbára tí a fún wọn lò. Bí àwa bá wáá so ìrú àìpèníye yìí kan òye wa nípa Ọlọ́run, a ó kàn máa ṣàròyé nípa àṣẹ Rẹ̀, èrò-ọkàn, àti pàápàá jùlọ, ìdájọ-òdodo Rẹ̀.
Bí ẹnìkan bá ń bẹ tí ó yẹ kí ó rò pé Ọlọ́run kò ṣe dáadáa, Jóòbù ni ìbá jẹ́. Ọkùnrin yẹn pàdánù ohun gbogbo tí ó ní—ṣùgbọ́n kò mi'kàn, ó sì dúró nínú òdodo rẹ̀. Ọ̀rẹ́ rẹ̀, Élíhù, gbìyànjú láti wo òye ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ nípa fífi ìdí ìdájọ́-òdodo Ọlọ́run múlẹ̀:
“Nítorípé ẹ̀san iṣẹ́ ènìyàni ni yíó san fún un;
yíó sì mú olúkúlùkù kí ó rí gẹ́gẹ́ bí ipa-ọ̀nà rẹ̀.
Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yíó hùwàkiwà,
bẹ́ẹ̀ni Olódùmarè kì yíó yí ìdájọ́ po.” (Jóòbù 34:11-12)
Ó jẹ́ Olótìtọ́.
Ọlọ́run fẹ́ràn àwọn ènìyàn Rẹ̀, àmọ́ ìyẹn kò pa ìdánilójú pé Ọ jẹ́ olótìtọ́ dà. Ó pé, nítorínáà ohun gbogbo tí Ó ṣe tọ́, ó sì dára—ìyẹn ni wípé kò lè fí ojú fo ẹ̀ṣẹ̀ dá.
Nítorínáà a lè dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ̀ pé a ṣe ìdájọ́-òdodo lórí àgbélébùú. A kò fi ojú fo ẹ̀ṣẹ̀ dá ní ọjọ́ ọ̀fọ̀ nì nígbàtí Jésù san ìdíyelé kí a baá lè dáríjì wá. Iṣẹ́ ìfarajìn yìí fihàn pé Ọlọ́run jẹ́ onífẹ̀ẹ́ àti olótítọ́. Bí a bá wà nínú Krístì, ìjìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ wa wà lórí Krístì.
Ṣùgbọ́n fún àwọn tí ó kọ ẹ̀bùn yìí, ìjìyà wọn yíó yára kánkán, yíó sì pé.
Baba, máṣe jẹ́ kí ìwà-ìrẹ́jẹ ayé yìí bá ìwòye mi nípa Rẹ jẹ́. Fún mi ní ojú tí ń wo àgbélèbú gẹ́gẹ́bíi ibi ìṣẹ̀mbáyé tí agbára Rẹ àti ìdájọ́-òdodo àti ìfẹ́ ti kójọ papọ̀ ní pípé fún mi. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

A ti kọ́ wa láti kékeré pé Ọlọ́run ni Bàbá wa àti pé àwa jẹ́ ọmọ Rẹ̀. Ṣùgbọ́n níní ìbátan pẹ̀lú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Bàbá kì í rọrùn nígbà gbogbo—àgàgà bí àwọn bàbá wa ti orí ilẹ̀ ayé bá ń sapá láti fi ìfẹ́ tí a ń fẹ́ hàn wá. Nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́rìndínlógún yìí, Pete Briscoe fa àfiyèṣí wa ṣọ́dọ̀ Ọlọ́run tó ń tẹ́ gbogbo àwọn èròngbà ìfẹ́ lọ́rùn—ó ń fi hàn bí Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé ó jẹ́ Bàbá wa rere àti Bàbá wa pípé.
More