Bàbá Fẹ́ràn Rẹ láti ọwọ́ Pete BriscoeÀpẹrẹ

Ọjọ́ 11
Gbígbé Oríyìn Fún Àwọn Tí Ó Yẹ Fún
“Mímọ̀” ní ọ̀nà tí Bíbélì jẹ́ ohun tí ó jinnú lọ́kàn ẹnìkọ̀ọ̀kan. Ó túmọ̀ sí pé kí ènìyàn ní ìrírí. Kì í ṣe ìmọ̀ orí, ọpọlọ tó péye, tàbí agbára iṣan ara. Jòhánù 8:32 sọ wípé, "Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì sọ yín di òmìnira". Ìwọ kó ipa nínú; o ní ìrírí ayé, ìwọ yóò sì sọ ọ́ di "ìtàn ìgbésí ayé." Nítorí náà, ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn rẹ di ìtàn ìgbésí ayé rẹ. —Tim Hansel, Holy Sweat
Ní gbogbo àkókò yìí, à ń wo àwọn onírúurú ẹni tí Ọlọ́run Baba jẹ́, a ń sọ nípa ohun tí Ó fẹ́ẹ́ ṣe nínú ayé wa, a sì ń ṣe àgbéyẹ̀wò bí Ó ṣe fẹ́ kí a máa ṣe sí Òun. Ó dájú pé àwọn nǹkan pàtàkì nìyìí tí ó yẹ kí o máa rò…
Ṣùgbọ́n ibi kọ́ ni ọ̀rọ̀ parí sí.
Ohun kan ni láti ní ìmọ̀ gbogbo nǹkan wọ̀nyí ní orí wa (láti mọ àwọn nǹkan nípa Ọlọ́run), ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ gbáà ní yóò jẹ́ bí a kò bá rìn jìnnà ju èyí lọ! Ìṣípayá Ọlọ́run a máa ń mú irúfẹ́ èsì kan jáde láti inú ọkàn àwọn tí ó fi etí sí ìtọ́sọ́nà Rẹ̀. Nígbàtí Mósè gba ìṣípayá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ó rí ara rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú Ọlọ́run tí ó mọ̀ nísinsìnyí. Kíni ó wáá ṣe?
Mósè sì wólẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sì jọ́sìn. (Ẹ́kísódù 34:8)
Ó rí i pé Ọlọ́run yẹ fún ìyìn.
Mósè fi gbogbo ara yin Ọlọ́run. Kì í wulẹ̀ ṣe pé ó kàn ń rò ó lọ́kàn lásán. Ó ń rí Ọlọ́run ní ọ̀nà tí ó ṣe yàtọ̀ gédégédé, ó ń mọ Ọlọ́run fún ara rẹ̀. Kì í ṣe pé èyí fi Ọlọ́run sí ààyè Rẹ̀ àti àwa náà sí ààyè wa nìkan, ó tún ń yí ọkàn wa padà, ó sì ń jẹ́ kí a túnbọ̀ sún mọ́ Ẹlẹ́dàá wa síi tímọ́tímọ́.
Lẹ́yìn tí Mósè yin Ọlọ́run, Ọlọ́run wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn ẹlòmíràn nípasẹ̀ Mósè. Ọlọ́run ti fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí Baba. Mósè rí ara rẹ̀ bí ọmọ. Wọ́n sì jùmọ̀ ń tẹ̀síwájú nínú òtítọ́ fún ògo Ọlọ́run.
Baba, ní ìgbàkigbà tí mo bá ní àǹfààní láti mọ̀ nípa Rẹ, mo gbàdúrà pé kí O mú ohun tí mo fi sínú orí mi, kí O sì gbé e sínú ọkàn mi. Jẹ́ kí èyí kí ó Rí BẸ́Ẹ̀ nínú ayé mi. Mo fẹ́ máa rí ọ lójoojúmọ́! Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ, O sì yẹ fún GBOGBO ìyìn mi! Àmín.
Nípa Ìpèsè yìí

A ti kọ́ wa láti kékeré pé Ọlọ́run ni Bàbá wa àti pé àwa jẹ́ ọmọ Rẹ̀. Ṣùgbọ́n níní ìbátan pẹ̀lú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Bàbá kì í rọrùn nígbà gbogbo—àgàgà bí àwọn bàbá wa ti orí ilẹ̀ ayé bá ń sapá láti fi ìfẹ́ tí a ń fẹ́ hàn wá. Nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́rìndínlógún yìí, Pete Briscoe fa àfiyèṣí wa ṣọ́dọ̀ Ọlọ́run tó ń tẹ́ gbogbo àwọn èròngbà ìfẹ́ lọ́rùn—ó ń fi hàn bí Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé ó jẹ́ Bàbá wa rere àti Bàbá wa pípé.
More