Bàbá Fẹ́ràn Rẹ láti ọwọ́ Pete BriscoeÀpẹrẹ

The Father Loves You by Pete Briscoe

Ọjọ́ 13 nínú 16

Ọjọ́ 13

Ìdáríjì Láì Sí Ẹ̀bi

Ó mà ṣe o! Ó máa ń ṣòro gan-an láti má ṣe fi ìrísí ẹni hàn. —Ovid

Èrò pé mo jẹ̀bi pọ̀ gan-an… ó sì wúwo. Bí ìdákọ̀ró tí wọ́n so mọ́ ẹsẹ̀ wa, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti dá sẹ́yìn—ńlá àti kékeré—ó lè sọ wá di ẹni tí ojú ń tì. Èyí ni ó mú kí àwọn kan lára wa fi tọkàntọkàn gbà gbọ́ pé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa kò lè rí ìdáríjì gbà láti ọ̀dọ̀ ènìyàn (èyí tí ó lè jẹ́ òtítọ́), àti pé ní ìgbà míràn, Ọlọ́run pàápàá lè máà dárí jì wá (èyí tí kì í ṣe òtítọ́!). A lè máa rò pé Ọlọ́run kò nífẹ́ dárí jì wá, tàbí pé kò dárí jì wá rárá.

Àmọ́, bíi ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà tẹ́lẹ̀, a mọ̀ láti inú Bíbélì pé Ọlọ́run yàtọ̀ pátápátá sí èyí.

“…ẹni tí ń dárí ìṣìnà àti ìrélànàkọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ jì.” (Exodus 34:7)

Ó máa ń dárí ji'ni. Ọlọ́run Baba máa ń dárí ji ẹni tí ó bá gba Ọlọ́run gbọ́. Ó máa ń dárí gbogbo wa jì wá pátápátá.

Nítorí bí ọ̀run ti ga ju ayé lọ,
bẹ́ẹ̀ ni inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ ṣe tóbi fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀;
Bí ìlà-oòrùn ṣe jìnnà sí ìwọ̀-oòrùn,
títí di ìsinsìnyí, òun ti mú àwọn ìrélànàkọjá wa kúrò lọ́dọ̀ wa. (Sáàmù 103:11-12)

Ó lè gba pé kó o jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà wọ̀ ọ́ lọ́kàn fúngbà díẹ̀.

Bíbélì ṣe àpèjúwe bí Ọlọ́run ṣe máa ń dárí ji'ni. Ó dé òpin rẹ̀ nínú Májẹ̀mú Tuntun nínú ẹni Jésù Kristi nípa ọ̀nà ikú àti àjíǹde Rẹ̀. Ìdí ni pé Bàbá aláàánú ni.

Òun[Jésù] ni Ẹni tí a fi lé ikú lọ́wọ́ nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, tí a sì jí dìde fún ìpolongo òdodo wa. (Róòmù 4:25)

Ọlọ́run, èmi kò yẹ fún ìfẹ́ Rẹ, tàbí ìdáríjì Rẹ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ GAN-AN fún bí Ẹ ṣe ń fi ìyọ́nú hàn sí mi, fún bí Ẹ ṣe ń fi inú rere hàn sí mi, àti fún bí Ẹ ṣe ń mú sùúrù fún mi. Kì í ṣe pé Ẹ gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ mi nìkan, Ẹ tún gbà mí là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ náà! Ẹ ṣeun fún ìdáríjì Yín. Mo gbà á gbọ́. Àmín.

Nípa Ìpèsè yìí

The Father Loves You by Pete Briscoe

A ti kọ́ wa láti kékeré pé Ọlọ́run ni Bàbá wa àti pé àwa jẹ́ ọmọ Rẹ̀. Ṣùgbọ́n níní ìbátan pẹ̀lú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Bàbá kì í rọrùn nígbà gbogbo—àgàgà bí àwọn bàbá wa ti orí ilẹ̀ ayé bá ń sapá láti fi ìfẹ́ tí a ń fẹ́ hàn wá. Nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́rìndínlógún yìí, Pete Briscoe fa àfiyèṣí wa ṣọ́dọ̀ Ọlọ́run tó ń tẹ́ gbogbo àwọn èròngbà ìfẹ́ lọ́rùn—ó ń fi hàn bí Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé ó jẹ́ Bàbá wa rere àti Bàbá wa pípé.

More

A fẹ́ dúpẹ́ l'ọ́wọ́ Pete Briscoe fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ si, jọ̀wọ́ lọ sí: http://petebriscoe.org/