Bàbá Fẹ́ràn Rẹ láti ọwọ́ Pete BriscoeÀpẹrẹ

Ọjọ́ 15
Àbùdá Baba tí ó Jàjú
Ó ya ni ní ẹnu pé Ọlọ́run fẹ́ràn ẹlẹ́ṣẹ̀, síbẹ̀ òtítọ́ ni. Ọlọ́run fẹ́ràn àwọn ẹ̀dá tí wọ́n ti di òǹrorò àti (bí ènìyàn ṣe lè ní ní èrò) tí wọn kò ṣeé fẹ́… A máa ń ru ìfẹ́ láàrin àwọn ènìyàn sí òkè nípasẹ̀ ǹkan tí ó wà nínú olùfẹ́, ṣùgbọ́n ọ̀fẹ́ ni ìfẹ́ Ọlọ́run, lójú ẹsẹ̀, láìròtẹ́lẹ̀, láìnídìí. Ọlọ́run fẹ́ràn ènìyàn nítorípè Ó yàn láti fẹ́ wọn. —J. I. Packer, Mí-mọ Ọlọ́run
Ọlọ́run tóbi, àwámárìdí sì ni. Ọlọ́run ju ohun gbogbo tí a lè ní ní èrò láti ní òye rẹ̀ ní ayé yìí lọ. Ó dùn mọ́ni pé, nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ara Rẹ̀, Ó yàn láti fi àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù tí ó sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó jù nípa ara Rẹ̀ hàn wá. Àbùdá kan sì wà tí Ó fi hàn tí ó ya'ni ní ẹnu jùlọ.
“…ó pọ̀ ní oore … ó ń pa àánú mọ́ fún ẹgbẹgbẹ̀rún…” (Ẹ́ksódù 34:6-7)
Ó jẹ́ onífẹ̀ẹ́.
Àbùdá Ọlọ́run yìí wà láàrin gbùngbùn ohun gbogbo tí à ń wá; ìdáhùn sí gbogbo ìbéèrè tí à bèèrè nípa mímọ́ Ọ́, àtí sí sọ Ọ́ di mímọ̀.
Olùfẹ́, ẹ jẹ́ kí á fẹ́ràn ara wa, nítorí ìfẹ́ ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Gbogbo ẹnití ó bá ní ìfẹ́, a bí i nípa ti Ọlọ́run, ó sì mọ̀ Ọlọ́run. Ẹnití kò bá ní ìfẹ́ kò mọ Ọlọ́run, nítorípé ìfẹ́ ni Ọlọ́run. Nípa èyí ni a gbé fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn nínú wa: nítorítí Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí Rẹ̀ nìkanṣoṣo sí ayé, kí àwa kí ó lè yè nípasẹ̀ Rẹ̀. Nínú èyí ni ìfẹ́ wà: kìí ṣe pé àwa fẹ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n Òún fẹ́ wa, Ó sì rán Ọmọ Rẹ̀ láti jẹ́ ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wa. (1 Jòhánù 4:7-10)
Nínú ọkàn gbogbo wa lóhùn-ún ní òǹgbẹ̀ ìfẹ́ wà. Bí ó sì ti jẹ́ pé a rí ìfẹ́ ní ìwọ̀nba díẹ̀ nínú àwọn ohun tí ayè fi lọ̀ wá, nínú Rẹ̀ nìkan ni a ti lè rí ìfẹ́ òtítọ́ tí í à ń wá, nítorípé Òun ni ìfẹ́ tí à ń wá.
Ọlọ́run ò, èmí kò lè dúpẹ́ tó fún ohun tí O ti ṣe fún mi! Ìfẹ́ Rẹ kò ní òpin, ó sì jẹ́ aláìnídìí. Mo gbàdúrà pé Ìwọ yíó sọ ìfẹ́ yìí di mímọ̀ nínú ayé mi bí mo ti ń bá àwọn ẹlòmíràn kó ẹgbẹ́ pọ̀. Ṣáájú ìfẹ́ Rẹ, mo ti sọnù, ṣùgbọ́n ní báyìí a ti wá mi rí! Máa gbé ní inú mi ní ọ̀nà tí ìfẹ́ Rẹ yíó fi fa àwọn ẹlòmíràn wá sí ọ̀dọ̀ ara Rẹ! Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

A ti kọ́ wa láti kékeré pé Ọlọ́run ni Bàbá wa àti pé àwa jẹ́ ọmọ Rẹ̀. Ṣùgbọ́n níní ìbátan pẹ̀lú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Bàbá kì í rọrùn nígbà gbogbo—àgàgà bí àwọn bàbá wa ti orí ilẹ̀ ayé bá ń sapá láti fi ìfẹ́ tí a ń fẹ́ hàn wá. Nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́rìndínlógún yìí, Pete Briscoe fa àfiyèṣí wa ṣọ́dọ̀ Ọlọ́run tó ń tẹ́ gbogbo àwọn èròngbà ìfẹ́ lọ́rùn—ó ń fi hàn bí Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé ó jẹ́ Bàbá wa rere àti Bàbá wa pípé.
More