Bàbá Fẹ́ràn Rẹ láti ọwọ́ Pete BriscoeÀpẹrẹ

Day 2
Ojú mi yóò máa bá ọ lọ
Bàbá gidi àkọ́kọ́ ní Ẹ́ksódù jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ fún èyíkèyí irú ìbáṣépọ̀: Ó wà ní àyíká wa .
Olúwa dáhùn wí pé, “Ojú mi yóò máa bá ọ lọ, èmi yóò sì fún ọ ní ìsinmi. (Exodus 33:14)
Nígbàtí Mósè béèrè pé ta ni yóò bá òun lọ, Ọlọ́run sọ pé, “Èmi yíò bá ọ lọ.” A rí èyí jákèjádò gbogbo inú Ìwé Mímọ. Níbikíbi tí o bá lọ, Ọlọ́run yóò wà níbẹ̀.
Bàbá mi rin ìrìn-àjò lọ́pọ̀lọ́pọ̀ nígbàtí mo wà ní ọ̀dọ́mọde. Nígbà tá a wà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, bàbá mi máa ń wà ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà fún àwọn oṣù púpọ̀ lẹ́ẹ̀kanṣoṣo. A mọ àìsí nílé bàbá mi lára gidigidi. Ọ̀kan lára àwọn ìdí tí a fí kó lọ sí Milwaukee lọ́dún 1970 ni pé kí bàbá mi lè túbọ̀ máà kó ipa pupọ ni ìgbé ayé àwa ọmọ —kí ó lè “wà nítòsí ” sí i. Láàárín àwọn ọdún tí bàbá mi kò sí ní àyíká, màmá mi tọ́ka mi sí "Ọlọ́run tí Ó tó bàbà í ṣe” Ó kọ́ mi pé Òún wànígbà gbogboní àyíká, níbikíbi tí mo wà tàbí ohun tí mo ń ṣeNí ákòkó tí bàbá ti lọ, á fi agbára mú mi láti wá Ọlọ́run ti í se Ọlọ́run Bàbá nínú ìgbésí ayé mi… àti pé bí Ó ṣe wá pẹ̀lú mi di òtítọ́ fún mi.
Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ nísìsinyì, pàápàá bí o ṣe ń ka àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Ó ni í ṣe nínú ìgbésí ayé ẹni kọ̀ọ̀kan ni ọ̀nà tí ó rúnilójú gẹ́gẹ́bí Bàbá tí ó wà láyìká rẹ nígbàkúgbà. Kò sí ókè tí ó ga jù, Kò sí àfonifojì tí ó jìn jù, Kò sí odò ńlá tí yíò mú ọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ. Pàápàá o lè gbìyànjú láti sá kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run tàbí yí ẹ̀hìn rẹ padà sí, ṣùgbọ́n ní kété tí o bá dúró, ìwọ yíò mọ̀ pé Ó tún wà níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ.
Wo èyí:
Olúwa Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ, ológun ńlá julọ tí Ó ń gbánílá. Òun yíò ni ìdùnnú pupọ ni ori rẹ; nínú ìfẹ́ Rẹ̀ kò ní bá ọ wí mọ, ṣùgbọ́n yíò fí orin yọ li orí rẹ. (Sefaniah 3:17)
Kìí ṣe pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ nikan, ṣùgbọ́n Ó TUN GBÁDÙN wíwà pẹ̀lú rẹ! Ó ńfẹ́ láti nífẹ̀ rẹ ní gbogbo ọ̀nà tí ó ṣeéṣe.
Ọlọ́run, O ṣeun fún wíwà pẹ̀lú wa nígbàgbogbo. O ṣeun fún bí O ṣe fẹ́ mi tó láti má kọ̀ mí sílẹ̀ rárá. Jọ̀wọ́ ràn mí lọ́wọ́ láti rántí pé O wà pẹ̀lú mi ní gbogbo ìgbà. Àmín.
Nípa Ìpèsè yìí

A ti kọ́ wa láti kékeré pé Ọlọ́run ni Bàbá wa àti pé àwa jẹ́ ọmọ Rẹ̀. Ṣùgbọ́n níní ìbátan pẹ̀lú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Bàbá kì í rọrùn nígbà gbogbo—àgàgà bí àwọn bàbá wa ti orí ilẹ̀ ayé bá ń sapá láti fi ìfẹ́ tí a ń fẹ́ hàn wá. Nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́rìndínlógún yìí, Pete Briscoe fa àfiyèṣí wa ṣọ́dọ̀ Ọlọ́run tó ń tẹ́ gbogbo àwọn èròngbà ìfẹ́ lọ́rùn—ó ń fi hàn bí Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé ó jẹ́ Bàbá wa rere àti Bàbá wa pípé.
More