Bàbá Fẹ́ràn Rẹ láti ọwọ́ Pete BriscoeÀpẹrẹ

Ọjọ́ 6
Gbogbo Ìgbádùn Náà Tirẹ̀ Ni
Ìmòye tí ó jinlẹ̀ jù lọ tí mo mọ̀ nípa ara mi ni pé Jésù fẹ́ràn mi dé inú kò sì sí ohun tí mo ṣe láti jẹ ère rẹ̀ tàbí láti mú kí ó tọ́ sí mi. — Brennan Manning, The Ragamuffin Gospel
Bóyá ní ipasẹ̀ iṣẹ́ ọnà ni, tàbí ní ipasẹ̀ ìwàásù tí ó gbóná pẹ̀lú ìbínú… n kò mọ̀ dájú, ṣùgbọ́n ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa ni a ní èròńgbà pé Ọlọ́run Baba ń bínú—àti pé Ó jókòó ní ọ̀run lórí àwọ̀ sánmà… ó ń ṣe àkọsílẹ̀… ní gbogbo ìgbà. Ó ní àkọsílẹ̀ àwọn òfin àti èèwọ̀ ní ọwọ́ kan àti ọ̀wọ̀n mọ̀nàmọ́ná ní ọwọ́ kejì. Ó ń dúró pé kí o ṣe àṣìṣe. Ní ìgbà tí o bá sì ṣe é? Gboa!
Ṣé èyí jẹ́ òtítọ́?
Rárá o. Kò tilẹ̀ súnmọ́-ọn. Wo ohun tí Ọlọ́run sọ fún Mósè ní ìgbà tí ó bèèrè pé kí Ọlọ́run fi ara hàn-án:
“N óo ṣe ohun tí o wí, nítorí pé inú mi dùn sí ọ…” (Ekisodu 33:17)
Inú Ọlọ́run dùn sí wa.
Ọlọ́run sọ fún Mósè pé Òun máa wà ní ààrin wọn nítorí pé inú Òun dùn sí i. Báyìí o lè sọ pé, "Bẹ́ẹ̀ni, nítorí pé ó jẹ́ Mósè ni. Èmi kìí ṣe Mósè.” Mósè yẹ kí ó jẹ́ asíwájú ńlá oníwà-bi-Ọlọ́run, àbí? Ó dára, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe yẹ kí ó rí, ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀. Njẹ́ o mọ nnkan tí ó ṣẹlẹ̀ gẹ́rẹ́ ṣí iwájú ibi àyọkà yìí? Àwọn ọmọlẹ́yìn Mósè mọ màálù ńlá kan pẹ̀lú wúrà wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀ dípò Ọlọ́run. Bí ó bá yẹ kí Mósè jẹ́ asíwájú ńlá, ṣé kò yẹ kí àwọ́n ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tèlé e? Ṣùgbọ́n ní òkodoro, àwọn ènìyàn rẹ̀ kò pé... gẹ́gẹ́ bí àwa kò ti pé, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti wà. Ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀, inú Ọlọ́run dùn sí wa, láì ka iṣẹ́ tí kò dára sí.
Olúwa, ó ṣòro púpọ̀ láti ní òye pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀dá ènìyàn ti bàjẹ́, O fẹ́ wa síbẹ̀—pàápàá ní àwọn àkókò tí ó burú jù. O ṣeun fún rírí ìdùnnú nínú mi nínu Krístì ní ibi tí ó jẹ́ pé ìkùnà nìkan ni ayé rí! Amín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

A ti kọ́ wa láti kékeré pé Ọlọ́run ni Bàbá wa àti pé àwa jẹ́ ọmọ Rẹ̀. Ṣùgbọ́n níní ìbátan pẹ̀lú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Bàbá kì í rọrùn nígbà gbogbo—àgàgà bí àwọn bàbá wa ti orí ilẹ̀ ayé bá ń sapá láti fi ìfẹ́ tí a ń fẹ́ hàn wá. Nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́rìndínlógún yìí, Pete Briscoe fa àfiyèṣí wa ṣọ́dọ̀ Ọlọ́run tó ń tẹ́ gbogbo àwọn èròngbà ìfẹ́ lọ́rùn—ó ń fi hàn bí Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé ó jẹ́ Bàbá wa rere àti Bàbá wa pípé.
More