Bàbá Fẹ́ràn Rẹ láti ọwọ́ Pete BriscoeÀpẹrẹ

The Father Loves You by Pete Briscoe

Ọjọ́ 5 nínú 16

Ọjọ́ Kárùn-ún

Ìpèsè Rẹ Tó Pé

Tí ó bá jẹ́ wípé Ọlọ́run ló ni ohun gbogbo tó sì mọ ohun gbogbo, tí ó bá fẹ́ràn wa tí Ó pé tí Ó sì jẹ́ mímọ́ nínú ìṣe Rẹ̀ gbogbo, nígbànáà a lè sọ wípé ohun gbogbo tí Ó bá fún wa àti èyí tí Kò fifún wa jẹ́ ẹ̀bùn tó dára láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, bí a kò tilẹ̀ ri bẹ́ẹ̀. —T. A. Hillard

Nígbà míràn àwọn ènìyàn a máa ní ìrètí tí kò yẹ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Wọ́n á máa ní ìrètí àwọn ǹkan tí kò ṣèlérí rẹ̀ fún wọn àti wípé wọn yóò wá máa ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn nígbà tí wọn kò bá ríi lójú ẹsẹ̀. Àmọ́ kìíṣe gbogbo ohun tí a bá fẹ́ ni Ọlọ́run ńṣe fún wa. Ohun tí a nílò nìkan ni ó máa fún wa.

Mósè mọ àìní ńlá tí òhun àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní fún ìwàláàyè Ọlọ́run. Wọn ò kàn ní ìfẹ́ síi lásán; Mósè mọ̀ wípé kòṣeémánìí ló jẹ́.

Nígbà náà ni Mósè sọ fún Un wípé... “‭‭Báwo ni ẹnikẹ́ni yóò ṣe mọ̀ pé inú rẹ dùn pẹ̀lú mi àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ àyàfi ti o bá bá wa lọ? Kí ni yóò lè yà mí àti àwọn ènìyàn rẹ kúrò lára gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ayé? Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Èmi yóò ṣe ohun gbogbo tí ìwọ ti béèrè...” (Ẹ́kísódù 33:16-17)

Ọlọ́run mọ̀ wípé ẹ̀bẹ̀ Mósè ṣe àfihàn ohun tí ó nílò fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀—èyí tí í ṣe ìwàláàyè Rẹ̀. Nítorí náà Ọlọ́run ṣe ìlérí láti ṣe é, bẹ́ẹ̀ni ó pèsè fún àìní wọn nítorí Ó jẹ́ Olùpèsè tó pé. Ìdí nìyí:

  • Ọlọ́run ló ni ohun gbogbo. (Orin Dáfídì 50:10-12)
  • Ọlọ́run jẹ́ onínúrere. (Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì 14:16-17)
  • Ọlọ́run mọ àìní wa gbogbo. (Mátíù 6:31-32)

Fún ìdí yìí, a kìí bèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ohun tí à ń retí nìkan Ó máa pèsè, àmọ́ a lè ní ìdánilójú wípé Ó ń pèsè àwọn ǹkan tí a nílò lọ́wọ́ lọ́wọ́!

Ǹjẹ́ o tilẹ̀ mọ ìyàtọ̀ láàárín ìfẹ́ ọkàn rẹ àti ohun tí Baba mọ̀ wípé o nílò? Ǹjẹ́ o ní ìgbàgbọ́ wípé Ọlọ́run ń pèsè fún gbogbo ǹkan tí o nílò ní tòótọ́ lọ́wọ́ lọ́wọ́, ni ìlànà pẹ̀lú bí yóò ti pèsè fún ọ ní ọjọ́ iwájú ?

Ọlọ́run, O ṣeun fún bí O ti ń pèsè gbogbo ǹkan tí mo nílò lónìí. Mo gbàdúrà wípé kí O ṣe ìyàtọ̀ tó mọ́lẹ̀ gedegbe láàárín ǹkan tí mo fẹ́ àti èyí tí mo nílò. O ṣeun fún ìlérí Rẹ láti pèsè fún mi ní ọjọ́ iwájú, gẹ́gẹ́ bí O ti ṣe ní àná, àti ìjẹ́ta. Àmín.

Nípa Ìpèsè yìí

The Father Loves You by Pete Briscoe

A ti kọ́ wa láti kékeré pé Ọlọ́run ni Bàbá wa àti pé àwa jẹ́ ọmọ Rẹ̀. Ṣùgbọ́n níní ìbátan pẹ̀lú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Bàbá kì í rọrùn nígbà gbogbo—àgàgà bí àwọn bàbá wa ti orí ilẹ̀ ayé bá ń sapá láti fi ìfẹ́ tí a ń fẹ́ hàn wá. Nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́rìndínlógún yìí, Pete Briscoe fa àfiyèṣí wa ṣọ́dọ̀ Ọlọ́run tó ń tẹ́ gbogbo àwọn èròngbà ìfẹ́ lọ́rùn—ó ń fi hàn bí Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé ó jẹ́ Bàbá wa rere àti Bàbá wa pípé.

More

A fẹ́ dúpẹ́ l'ọ́wọ́ Pete Briscoe fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ si, jọ̀wọ́ lọ sí: http://petebriscoe.org/