Bàbá Fẹ́ràn Rẹ láti ọwọ́ Pete BriscoeÀpẹrẹ

Ọjọ́ kẹta
Ìtùnú tí kò ní fi Ìgbà Kankan Fi Ẹ́ Sílẹ̀
O ti dá wa fún ara Rẹ̀, Olúwa; bẹ́ẹ̀ni ọkàn wa kò lè sinmi láì ṣe pé ó sinmi nínú Rẹ. —Augustine
Ìjàkadì ni ayé tí a wà yí. Gbogbo ènìyàn ló ma sọ èyí fún ọ. Ibi yìówù tí a bá ara wa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro àti ìpènijà ni a máa ń bá wọ ìyá ìjà—nípa ìṣúná, ìmọ̀lára, ara, abbl. Àti pé fún gbogbo ìṣòro tí a bá d'ojú ko, onírúurú ojútùú ni àwọn ènìyàn máa fi lọ̀ wá. Díẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ni “yanjú rẹ̀ fún ara rẹ” tàbí “tẹ apá mọ́ iṣẹ́.”
Àmọ́ ní ìlòdì sí àwọn ìmọ̀ràn yìí, Baba wa ní ọ̀run sọ ohun kan fún wa tí ó kọjá ìṣòrokíṣòro tí a bá d'ojú ko:
OLÚWA fèsì, “Ìwàláàyè Mi ma lọ pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì fún ọ ní ìsinmi. (Ẹ́kísódù 33:14)
Ọlọ́run yíò fún wa ní ìsinmi? Òpò nínú wa ní baba tí ó tì wá títí dé ibi ìrẹ̀wẹ̀sì ọpọlọ àti ara. Ọlọ́run Baba wa kò rí bẹ́ẹ̀. Ó máa ń tù wá nínú. Ní ọ̀títọ́, Ó ní àwọn ǹkan tí Ó fẹ́ kí a ṣe—àwọn ǹkan náà ṣe pàtàkì—àmọ́ Ìwé Mímọ́ fi yé wa pé nípa ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ipá Ọlọ́run tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú wa ni a fi lè ṣiṣẹ́ fún-Un, dípò ìgbẹ́kẹ̀lé ipá ti ara wa.
“Èmi ni [Ọlọ́run]ẹni tí ó kọ́ Éfúráímù bí a ti ń rìn, tí ó sì ń fà wọ́n ní ọwọ́; àmọ́ àwọn kò mọ̀ pé Èmi ni ó wò wọ́n sàn. Mo fi okùn enia fà wọn, ati idè ifẹ: mo sì rí sí wọn bí àwọn tí ó mú àjàgà kúrò lí ẹ̀rẹ̀kẹ́ wọn, mo sì gbé oúnje ka lẹ̀ ní iwájú wọn.” (Hósià 11:3-4)
Ní ibi àyọkà yìi láti inú ìwé Hósià, a ríi pé kìí kàn gba àwọn àjàgà wa lásán, àmọ́ ó FẸ́ láti gbà wọ́n nítorí ìfẹ́ aláìlópin fún wa! Kò sí òdiwọ̀n fún ǹkan tí Ó lè yanjú, tàbí fún ǹkan tí Ó máa ṣe fún wa. Èyí wá mú ìbéèrè kan tí ó jinlẹ̀ jẹ yọ:
Kí ni ǹkan náà tí o ti ń bá jìjàkadì pẹ̀lú ipá tìrẹ, dípò jíjọ̀wọ́ gbogbo rẹ̀ fún Baba náà tí ó fẹ́ràn rẹ?
Baba, gbé àwọn àjàgà tí mo ti gbé wọ ara à mi kúrò. N kò lè dá d'ojú ko àwọn ǹkan wọ̀nyí. Mo jọ̀wọ́ fún Ọ àwọn ǹkan tí mo ti gbìyànjú láti ṣe fún ara mi. Mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ipá Rẹ kí n lè máa sinmi nínú ìtùnú Rẹ ní gbogbo ìgbà. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

A ti kọ́ wa láti kékeré pé Ọlọ́run ni Bàbá wa àti pé àwa jẹ́ ọmọ Rẹ̀. Ṣùgbọ́n níní ìbátan pẹ̀lú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Bàbá kì í rọrùn nígbà gbogbo—àgàgà bí àwọn bàbá wa ti orí ilẹ̀ ayé bá ń sapá láti fi ìfẹ́ tí a ń fẹ́ hàn wá. Nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́rìndínlógún yìí, Pete Briscoe fa àfiyèṣí wa ṣọ́dọ̀ Ọlọ́run tó ń tẹ́ gbogbo àwọn èròngbà ìfẹ́ lọ́rùn—ó ń fi hàn bí Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé ó jẹ́ Bàbá wa rere àti Bàbá wa pípé.
More