Bàbá Fẹ́ràn Rẹ láti ọwọ́ Pete BriscoeÀpẹrẹ

The Father Loves You by Pete Briscoe

Ọjọ́ 4 nínú 16

Day 4
Gbogbo Rẹ̀ Jẹ́ Nípa Tani Ó Mọ̀ Ọ́

Njẹ a lè yí ìwà wa padà, kò yẹ kí á ríí ìgbésí ayé tó yàtọ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ìgbésí ayé fúnrararẹ̀ ni lati yàtọ̀. Katherine Mansfield

Mo bá wọn kọ́ ilé ìjọsìn kan fún àwọn tóó ńgbá bọ́ọ̀lù afipátákó gbá tí Milwaukee ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn. Ó jẹ́ ńkan ńlá. Ní ibi tí mo gbé rí, àwọn tó ńgbá bọ́ọ̀lù afipátákó gbá jẹ́ ogbonta-rigi ọga ti pátákó, bọ́ọ̀lù. Gbogbo àwọn olùfọkànsìn olùgbé Wisconsin máa ń wò wọ́n lóri ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán. Àwọn tí ó ní owó tíkẹ́tì yóò ṣe ìrìn àjó lọ sí pápá ìṣeré County. Ṣùgbọ́n láti wọ yàrá ìyírapadà? Ìyẹn ni “ibi mímọ́ jùlọ”—ibi mímọ́ inú tẹ́mpìlì níbi tí ènìyàn lásán kò gbọ́dọ̀ ronú láti lọ.

Mo“wọlé,” bótilẹ̀jẹ́pé. Pọ́ọ́lù Molitor ni balógun ẹgbẹ́ náà, àti nítorí pé mo, tí mọ̀òun, wọ́n tẹ́wọ́gbàmí ní yàrá ìyírapadà. Kódà wọ́n gbà mí láyè láti bá àwọn agbá bọ́ọ̀lù náà sọ̀rọ̀ lójúkojú. Mo bá wọn jíròrò láti inú Bíbélì pẹ̀lú gbogbo ẹgbẹ́, wọ́n sì tẹ́tí si... gbogbo rẹ̀ nítorí Pọ́ọ́lù. Ó gbé mi sókè sí ipele míràn tí ó yàtọ̀ ni ojú àwọn eléré àgbàyanu wọ̀nyí. Nwọn fí tọkàntọkàn tẹ́tí silẹ sì mi nítorí ìbásepọ̀ tí ó wà láàrin òun àti èmi .

Àwọn nǹkan ṣiṣẹ́ bákan náà pẹ̀lú Ọlọ́run àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì:

Lẹ́yìn náà ni Mósè sọ fún un pé... "Báwo ni àwọn eniyan yóo ṣe mọ̀ pé, inú rẹ dùn sí èmi ati àwọn eniyan rẹ àyàfi bí ó bá bá wà lọ? Kini o tún kù tí yóò mú èmi ati àwọn eniyan rẹ yàtọ̀ sí àwọn ènìyàn miran tí ó kú ní orílẹ̀ èdè ayé?" (Ẹ́kísódù 33:16)

Ọlọ́run Baba wa náà ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ fún wa. Wíwà pẹ̀lú wa nínú ìgbésí ayé wa mú wá yàtọ̀ sí àwọn ènìyàn miran.Ó yàwá sótò. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Rẹ̀, a ti yí wa padà nípa ẹ̀mí a sì ṣe àrà ọ̀tọ̀ ní ayé yìí... àti pé èyí mú kí ìwàásù wa ti Ìyè tòótọ́ nínú Kristi jẹ èyí tí ó fà àwọn tí ń ṣe ìwádìí òtítọ́ àti ìtumọ̀ mọ́ra.

Baba, Mo gbàdúrà pé kí O gbé ìgbésí ayé mi ga ní ònà tí ó hàn gbangba pé èmi yàtọ̀ sí ayé. Jẹ́ kí n jẹ́ àpẹẹrẹ ohun rere tí ìgbésí ayé jẹ nínú Rẹ̀ kí àwọn mìíràn le mò. bí Ó ṣe níyì tó. Àmín.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

The Father Loves You by Pete Briscoe

A ti kọ́ wa láti kékeré pé Ọlọ́run ni Bàbá wa àti pé àwa jẹ́ ọmọ Rẹ̀. Ṣùgbọ́n níní ìbátan pẹ̀lú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Bàbá kì í rọrùn nígbà gbogbo—àgàgà bí àwọn bàbá wa ti orí ilẹ̀ ayé bá ń sapá láti fi ìfẹ́ tí a ń fẹ́ hàn wá. Nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́rìndínlógún yìí, Pete Briscoe fa àfiyèṣí wa ṣọ́dọ̀ Ọlọ́run tó ń tẹ́ gbogbo àwọn èròngbà ìfẹ́ lọ́rùn—ó ń fi hàn bí Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé ó jẹ́ Bàbá wa rere àti Bàbá wa pípé.

More

A fẹ́ dúpẹ́ l'ọ́wọ́ Pete Briscoe fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ si, jọ̀wọ́ lọ sí: http://petebriscoe.org/