Bàbá Fẹ́ràn Rẹ láti ọwọ́ Pete BriscoeÀpẹrẹ

The Father Loves You by Pete Briscoe

Ọjọ́ 7 nínú 16

Ọjọ́ 7

Ó Ní Ìfẹ̀ẹ́ Wa, Ó sì ń Fi Iyè Sí Wa

Máa gba àdúrà nígbàkíìgbà tí a bá ru ó s'ókè. Ó lè wù ẹ́ l'áti gba àdúrà ní ìgbà tí o bá ń ka ìwé tàbí ní ìgbà tí o bá ń ronú l'órí ẹsẹ̀ kan. Máa sọ èyí di òfin tí kò ní àbùlà—gbọ́ràn sí èrò bẹ́ẹ̀ ní ìgbà gbogbo.— Martyn Lloyd-Jones

Báwo ni ó ṣe máa ṣe pàtàkì tó bí bàbá rẹ bá ní nóńbà tẹlifóònù àwọn ọmọ bílíọ̀nù mẹ́ta nínú iPhone rẹ̀, tí tìrẹ náà sì jẹ́ ọ̀kan l'ára wọn? Báwo ni ọkùnrin kan ṣe lè b'ójú tó àwọn ọmọdé tí ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ lè máà sí. Àmọ́, agbára Baba wa ọ̀run kò ní ààlà, kò sí ibi tí agbára rẹ̀ mọ, tàbí òdiwọ̀n agbára Rẹ̀ láti wà ní ibi gbogbo fún gbogbo ènìyàn ní ẹ̀ẹ̀kan náà! Ó mú èyí hàn kedere nínú ìjíròrò rẹ̀ pẹ̀lú Mósè ní ìgbà tí Ó wí pé:

“Inú mi dùn sí ọ, mo sì mọ orúkọ rẹ.” (Ẹ́kísódù 33:17)

Ọ̀pọ̀ ọdún s'ẹ́yìn, mo wà pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ìkàwé gíga ní ìlú Urbana ní Yunifásítì Illinois. Àwọn ènìyàn kún pápá náà dé góńgó. Ní ìgbà kan nínú ètò náà, wọ́n ní kí gbogbo àwa tí iye wa jẹ́ 20000 gba àdúrà... s'ókè ketekete. Kì í ṣe ìró tí mò ń gbọ́ tàbí bí gbogbo nǹkan ṣe ń yí padà ní yà mí l'ẹ́nu, bí kò ṣe òtítọ́ pé Ọlọ́run lè gbọ́ àdúrà kọ̀ọ̀kan, kí Ó sì dáhùn rẹ̀ ní ọ̀nà pípé.  

Fún Ọlọ́run Baba, gbogbo àdúrà tí à ń gbà nìkan ṣoṣo ni Ó ń gbọ́. Kò sí irú nnkan bíi àdúrà ìsàlẹ̀. Kí ló dé? 

Ní'torí pé Ó kàn-án. 

“Mo ṣebí kọbọ meji ni wọ́n ń ta ológoṣẹ́ marun-un. Sibẹ kò sí ọ̀kan ninu wọn tí Ọlọrun fi ojú fò dá. Àní sẹ́, gbogbo irun orí yín ni ó níye. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ níye lórí pupọ ju ológoṣẹ́ lọ.” (Luku 12:6-7)

Ọlọ́run mọ orúkọ rẹ, Ó sì máa ń rántí rẹ ní ìgbà gbogbo. Bí o bá ní ẹ̀gún kan ní ẹsẹ̀ rẹ, Ó bìkítà nípa rẹ̀—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé omíyalé àti ìyàn wà ní àwọn ibòmíràn ní àgbáyé. Ó lè fún ọ ní gbogbo àfiyèsí Rẹ̀, láì ní èyí tí ó dín kù fún ẹlòmíràn. Ìyẹn ni ìjẹ́pàtàkì rẹ ní ojú Ọlọ́run!

Baba, mo dúpẹ́ pé Ò ń gbọ́ àdúrà yìí, O sì lè fún mi ní àfiyèsí Rẹ ní kíkún! Mo dúpẹ́ l'ọ́wọ́ Rẹ pé O kà mí sí, pé O bìkítà nípa mi, pé O ní ìfẹ́ẹ̀ mi. Àmín.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

The Father Loves You by Pete Briscoe

A ti kọ́ wa láti kékeré pé Ọlọ́run ni Bàbá wa àti pé àwa jẹ́ ọmọ Rẹ̀. Ṣùgbọ́n níní ìbátan pẹ̀lú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Bàbá kì í rọrùn nígbà gbogbo—àgàgà bí àwọn bàbá wa ti orí ilẹ̀ ayé bá ń sapá láti fi ìfẹ́ tí a ń fẹ́ hàn wá. Nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́rìndínlógún yìí, Pete Briscoe fa àfiyèṣí wa ṣọ́dọ̀ Ọlọ́run tó ń tẹ́ gbogbo àwọn èròngbà ìfẹ́ lọ́rùn—ó ń fi hàn bí Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé ó jẹ́ Bàbá wa rere àti Bàbá wa pípé.

More

A fẹ́ dúpẹ́ l'ọ́wọ́ Pete Briscoe fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ si, jọ̀wọ́ lọ sí: http://petebriscoe.org/