Tún Ọkàn Rẹ Tò: Ọjọ́ 10 Láti Ba Ẹ̀ṣẹ̀ JàÀpẹrẹ

Ọkàn wà nílò Ọlọ́run
Òní jẹ́ ọjọ́ kẹ̀wá àti ọjọ́ tí ó kẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ wà lóríi "ọkàn". Lẹ́yìn gbogbo àwọn nkàn tí a ti gbé yẹ̀wò, ìbéèrè ìparí kan wà tí ó yẹ kí á bèèrè. Ǹjẹ́ a le ṣe ìyípadà ọkàn tiwa?
Ṣé a kún ojú òṣùwọ̀n láti ṣe isẹ́ ìyípadà ọkàn wa láti inú èyí tí ó ṣe pàtàkì láti tẹ̀lé Ọlọ́run, júbà Jésù, àti láti fetí sí Ẹ̀mi Ọlọ́run? Ìdáhùn ìbéèrè yií jẹ́ rárá.
A rí àlàyé kan tí ó ṣe àjèjì ní inú ìwé Deuteronomi lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti fún àwọn ọmọ Israẹli ní gbogbo òfin tí wọ́n yíò nílò láti pamọ́ kí wọ́n lè dúró nínú ìbásọ̀rẹ́ pẹ̀lú Rẹ̀.
“Ṣùgbọ́n títí di àsìkò yìí Olúwa kò fi ọkàn ìmòye tàbí ojú tí ó ń rí tàbí etí tí ó n gbọ́ fún ọ.” (29:4).
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò yé àwọn ọmọ Israẹli, wọn kò sì le fetí sí àwọn àsẹ Rẹ̀ ní tòótọ́ ní ònà tí wọn yíò fi lè gbọ́ràn sí àwọn àsẹ yìí. Kíni ìdí èyí? Nítorí pé ọkàn wọn kò mọ́.
Lẹ́yìn ẹsẹ Bíbélì yìí, Ọlọ́run sọ fún wọn wípé, láìpẹ́, wọn yíò lòdì sí òfin Rẹ̀ wọn yíò sì subú sábẹ́ ìbínú Rẹ. Bẹ́ẹ̀ ni ó rí, bí a ṣe ń ka ìyókù Bíbélì, a rí wípé gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ó sẹlẹ̀.
Nítorí nà, kíni ìrètí tí wọ́n ní? Kíni ìrètí tí àwa gan náà ní? Tí a kò bá lè tẹ̀lé òfin Ọlọ́run àti pé kí á dúró nínú ìbásọ̀rẹ́ tòótọ́ pẹ̀lú Rẹ̀, kíni kí àwọn àti àwa ṣe?
A nílò ọkàn tuntun.
Pẹ̀lú ọpẹ́, ní ese tí ó tẹ̀lẹ́e ní inú ìwé Deuteronomi Ọlọ́run ṣe ìlérí láti tún ọkàn wa ṣe. Èyí ni kókó ọ̀rọ̀ wa lónìí.
Ọlọ́run sọ wípé òhun yíò ṣe ìkọlà ọkàn wa, kí á lè fẹ́ràn Rẹ̀. Ọlọ́run fúnra Rẹ̀ gbọ́dọ̀ àti pé yíó ṣe iṣẹ́ abẹ nínú ọkàn wa. Òhun yíò yí ọkàn wa padà.
Èyí ni ohun tí Jésù ṣe fún wa nípasẹ̀ iṣé Ẹ̀mí mímọ́. Tí o bá ti ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù àti ìhìn rere Rẹ̀, nígbà náà o ti ní ìrírí apákan nínú isẹ́ yìí. A kò le gbàgbọ́ nínú Jésù láìsí isẹ́ ọkàn ti Ẹ̀mí mímọ́ yìí.
Ọlọ́run tèsíwájú láti ṣe isẹ́ lórí wa lójoojúmọ́ pẹ̀lú. Ó ń ṣe iṣẹ́ abẹ lórí ọkàn wa lójoojúmọ́. Àti wípé a sọ ibi iṣé abẹ yìí fún wa nínú ẹsẹ Bíbélì yìí: wípé kí a fẹ́ràn Rẹ̀ pèlú gbogbo ọkàn wa.
Ǹjẹ́ ìwọ́ fẹ́ ṣe ìyípadà ọkàn rẹ? Ké pe Ọlọ́run kí o sì bèèrè lọ́wọ́ọ Rẹ̀ wípé kí Ó ṣe ìyípadà ọkàn rẹ. Òhun nìkan ni ó lè ṣe é.
Ohun kan ṣoṣo míràn tí o lè ṣe ni kí o fi gbogbo ìfẹ́ rẹ ṣí Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi. Ro gbogbo ohun tí ó ti ṣe fún ọ l'órí igi àgbélèbú. Rò ó wí pé Ó ń padà bọ̀ láti gbé pẹ̀lú rẹ̀ títí ayérayé. Bí ìfẹ́ rẹ fún Ọlọ́run ṣe ń dàgbà, ọkàn rẹ yíò máa yípadà.
Ṣe ìjọyọ̀ nínú ìyìn rere, Ọlọ́run yíò sì tún ọkàn rẹ ṣe.
Fún díẹ̀ síi nínú èrò yìí, mo pè ọ́ pé kí o wo ìwé mi yìí “Rewire Your Heart.”
Nípa Ìpèsè yìí

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Kristiẹni gbàgbọ́ pé ọ̀nà kan ṣoṣo láti borí ẹ̀ṣẹ̀ ni láti fi ara mọ́-ọn kí a sì má ṣubú sí inú ìdánwò. Ṣùgbọ́n ìwọ kò lè fi ọkàn rẹ ja ẹ̀ṣẹ̀; o gbọ́dọ̀ fi ọkàn rẹ jà á. Ètò ọjọ́ mẹ́wàá yìí da l'órí ìwé Rewire Your Heart, ó sì wo díẹ̀ nínú àwọn ẹsẹ̀ tí ó pàtàkì jù lọ nípa ọkàn rẹ tí yoo ràn ọ́ l'ọ́wọ́ l'áti ṣe àwárí bí o ṣe lè k'ojú ẹ̀ṣẹ̀ nípa gbígba Ìhìnrere ní ààyè láti tún ọkàn rẹ ṣe.
More