Tún Ọkàn Rẹ Tò: Ọjọ́ 10 Láti Ba Ẹ̀ṣẹ̀ JàÀpẹrẹ

Àwọn Ìfẹ́ Tó O Ní Níwọ̀n
Kí ló ń mú ká dẹ́ṣẹ̀? Kí ló ń sún wa láti jẹ́ mímọ́? Apá wo nínú wa ló máa ń jẹ́ kéèyàn ní ìgbàgbọ́? Kí ló wà nínú wa tó ń mú ká ṣiyèméjì? Ohun kan ṣoṣo ló wà - ọkàn wa.
Nítorí náà, kí ni olórí ìṣòro tó wà nínú ìjà tí à ń jà pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ àti àìní ìgbàgbọ́ wa? Pọ́ọ̀lù sọ ọ́ báyìí nínú ẹsẹ wa fún òní:
“Ìfẹ́ tí ìwọ fúnra rẹ ní kò tó nǹkan.”
Nínú ọ̀rọ̀ ṣókí yìí, tó dà bíi pé Pọ́ọ̀lù sọ láìròtẹ́lẹ̀, ó sọ ohun tó wà nídìí ọ̀rọ̀ náà gan-an, ìyẹn ohun tó wà lọ́kàn.
Nínú orí yìí, Pọ́ọ̀lù ń bẹ àwọn ará Kọ́ríńtì pé kí wọ́n gba Ìhìn Rere gbọ́. Ó ti ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti sọ ìhìn rere nípa Jésù fún wọn, àmọ́ àwọn kan ṣì wà tí wọn ò fẹ́ gbọ́. Kí nìdí?
Ìfẹ́ tí wọ́n ní síra wọn kò jẹ́ kí wọ́n lè ṣe é.
Báwo ni ìfẹ́ ọkàn wa ṣe lè dí wa lọ́wọ́? Ó rọrùn gan-an. A kì í ṣe ohunkóhun tí kò wù wá láti ṣe. A máa ń ṣe ohun tó wù wá nìkan..
Ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé kìkì ohun tó bá wù wá la máa ń ṣe. Ó túmọ̀ sí pé ohun tó wà lọ́kàn wa la máa ń ṣe. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé inú Bíbélì lọ́hùn-ún ni Ọlọ́run ti ń wá ọkàn wa.
Gbogbo ìgbà ni ìfẹ́ ọkàn wa máa ń ká wa lọ́wọ́ kò. Ọkàn wa ò kún fún ìfẹ́. Ìdí nìyẹn tá a fi ń dẹ́ṣẹ̀. Ìdí nìyẹn tá a fi ń ṣiyèméjì. Ìdí nìyí tí a fi ń bá ìgbàgbọ́ wa jà, tí a sì ń rìn.
Nítorí náà, báwo la ṣe lè yí padà? Báwo la ṣe lè ṣẹ́gun ẹ̀ṣẹ̀ ká sì máa gbé ìgbé ayé wa fún Ọlọ́run? A gbọ́dọ̀ mú ìkálọ́wọ́kò kúrò lára ìfẹ́ wa.
Ọ̀nà kan ṣoṣo tá a lè gbà ṣe èyí ni pé ká lo Ìwé Ìhìn Rere. Ihinrere nikan ni o lẹwa to lati yi ọkàn wa pada ki o si mu ki gbogbo ifẹ ti yoo mu ki a gbe igbesi aye tuntun.
Máa ronú lórí gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún ẹ nínú Kristi. Máa yọ̀ nítorí pé ẹ̀jẹ̀ Ọmọ Ọlọ́run tó ṣeyebíye ti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ẹ́. Ẹ máa yọ̀ nínú òtítọ́ wípé a ti gbà yín wọlé sínú ìdílé Ọlọ́run ní ìnáwó gíga ti àgbélébùú.
Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ tá a ní fún wọn á máa pọ̀ sí i lọ́kàn wa. A ò lè gbógun ti ẹ̀ṣẹ̀ nípa kíkó àwọn ìfẹ́ ọkàn àti ìmọ̀lára wa níjàánu. Bá a ṣe lè gbógun ti ẹ̀ṣẹ̀ ni pé ká jáwọ́ nínú àwọn nǹkan tó lè mú ká nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Ó yẹ ká túbọ̀ máa nímọ̀lára, kì í ṣe ká máà nímọ̀lára. Àwọn èrò wọ̀nyí sì ní láti wá láti inú ìwé Ìhìn Rere.
Nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí, a óò rí i bí ohun gbogbo ṣe ń wá látinú ọkàn. Fún ìsọfúnni síwájú sí i, mo rọ̀ ọ́ pé kó o gba ìwé mi tó dá lórí kókó yìí, ìyẹn: Rewire Your Heart.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Kristiẹni gbàgbọ́ pé ọ̀nà kan ṣoṣo láti borí ẹ̀ṣẹ̀ ni láti fi ara mọ́-ọn kí a sì má ṣubú sí inú ìdánwò. Ṣùgbọ́n ìwọ kò lè fi ọkàn rẹ ja ẹ̀ṣẹ̀; o gbọ́dọ̀ fi ọkàn rẹ jà á. Ètò ọjọ́ mẹ́wàá yìí da l'órí ìwé Rewire Your Heart, ó sì wo díẹ̀ nínú àwọn ẹsẹ̀ tí ó pàtàkì jù lọ nípa ọkàn rẹ tí yoo ràn ọ́ l'ọ́wọ́ l'áti ṣe àwárí bí o ṣe lè k'ojú ẹ̀ṣẹ̀ nípa gbígba Ìhìnrere ní ààyè láti tún ọkàn rẹ ṣe.
More