Tún Ọkàn Rẹ Tò: Ọjọ́ 10 Láti Ba Ẹ̀ṣẹ̀ JàÀpẹrẹ

Ọ̀nà Àìtọ́ Láti Kojú Ẹ̀ṣẹ̀
Tí o bá fẹ́ dẹ́kun dídá ẹ̀ṣẹ̀ kan pàtó, kí ni ǹkan tí o lè ṣe?
Ṣé o máa fi ǹkan dun ara rẹ ní, sá jìnà kúrò níbi ìdánwò, tàbí fi àwọn iṣẹ́ mìíràn mú àkíyèsí rẹ kúrò níbi ǹkan ẹ̀ṣẹ̀ náà?
Ó ṣeé ṣe kí o ti máa ṣe èyí láti ẹ̀yìn wá, àmọ́ kò sí ìkankan nínú àwọn ìgbésẹ̀ yí tó máa ṣiṣẹ́ láéláé. O kò lè ṣé ara à rẹ, fojú fo ìfẹ́ ọkàn rẹ, tàbí pa ìfẹ́ ọkàn rẹ lẹ́nu mọ́. Kí ló fà á? Nítorí ọkàn rẹ àti ìfẹ́ ọkàn rẹ kọ́ ni àárín-gbùngbùn ìṣíṣẹ̀ ìpínu-ṣíṣe rẹ. Oókan àyà rẹ ni èyí ti ń ṣé yọ. Bí o kò bá fẹ́ràn ohun kàn ó máa nira fún ọ láti ṣeé. Bí o kò bá korira ǹkan o kò ní fi sílẹ̀.
Síbẹ̀ pẹ̀lú pẹ̀lú àwọn ìwé oní-ọ̀rọ̀-ìyànjú àti ìwàásù lónìí, àwọn ènìyàn ń polongo ìṣe yìí. Gbogbo ìgbà ni “ọgbọ́n” titun kan tàbí òmíràn nípa bí a ti lè dẹ́kun ìwà búburú àti bí a ti lè bẹ̀rẹ̀ èyí tí ó dára ma ń jẹyọ. Púpọ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀-ìyànjú yìí a máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ bíi àwẹ̀. F'ebi pa èyí tí kò dára. Bọ́ èyí tí ó dára. Àmọ́ ẹ̀ṣẹ̀ kò rí bẹ́ẹ̀.
Nínú àyọkà wa t'òní, Pọ́ọ̀lù ń ní ìdojúkọ pẹ̀lú àwọn àyídáyidà ẹ̀sìn ní ayé ìgbà a nì. Ó ń gbìyànjú láti ran àwọn olùgbọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ láti dojú ìjà kọ àwọn ìdánwò ẹran-ara ẹ̀ṣẹ̀ (Kólósè 2:23) àti ohun ti ayé yìí (3:5). Àmọ́ kí ó tó sọ ọ̀nà tí wọ́n máa gbé e gbà, ó sọ ìgbésẹ̀ tí wọn kò gbúdọ̀ gbé fún wọn.
Nígbà ayé Pọ́ọ̀lù àwọn èèyàn ń sọ wípé ọ̀nà tó tọ́ láti fa gbòǹgbò ẹ̀ṣẹ̀ tu ni láti fi ebi pá á. “Má ṣe dìímú, má ṣe tọ́ ọ wò, má ṣe fọwọ́ kàn án” (2:21). Wọ́n ṣẹ̀dá ẹ̀sìn titun tó dá lórí fífi ǹkan dáradára dun ara wọn - “sísé ara ẹni” (2:23)- àti fífi ìyà jẹ ẹran ara - “pípọ́n ẹran ara lójú” (2:23). Ọ̀nà tí àwọn ń gbà láti kojú ẹ̀ṣẹ̀ ni líle jáde lára wọn pẹ̀lú kùmọ̀ àti fífi ìyà jẹ ara nígbà tí wọn kò bá ṣe èyí.
Èyí lè ní pọn ju ǹkan tí à ńṣe lóde òní. Fún àpẹrẹ, bí ẹnikan bá ń tiraka láti jáwọ́ nínú wíwo ìwòkuwò, wọn lè fi àǹfààní sí ayélujára àti àwọn ẹ̀rọ rẹ̀ dun ara wọn. Nígbà tí wọ́n bá ṣe lòdì sí ìpinnu yìí, wọn máa fi ẹ̀bi àti ìtìjú jẹ ara wọn níyà. Ìṣòro kan tí èyí ní ni wípé fífi ǹkan dùn ara ẹni kò lè yí ọkàn ènìyàn padà bí fífi ebi pa inú kò ṣe lè mú ebi kúrò.
Bóyá ìwọ kò fi taratara gba èyí wọlé. Bóyá ìwọ ti gbà wípé ọ̀nà kan tó wà láti kojú ẹ̀ṣẹ̀ nìyí. Kò ya ni lẹ́nu ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ wípé, “Ní tòótọ́ àwọn ǹkan wọ̀nyí ní àpẹrẹ ọgbọ́n” (2:23). Àmọ́, kò ní ṣiṣẹ́ láé. Irú àyídáyidà láti kojú ẹ̀ṣẹ̀ yí “kò ní ìwúlò láti dá iṣẹ́ ẹran-ara dúró” (2:23).
Bí èyí bá jẹ́ ọ̀nà tí a kò gbúdọ̀ gbà kojú ẹ̀ṣẹ̀, báwo ni ó yẹ fún wa láti dojú kọ ẹ̀ṣẹ̀?
Pọ́ọ̀lù ní ìdáhùn fún wa. “Ṣe àwárí àwọn nǹkan tó wà lókè, níbi tí Kristi wà, ní ìjókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. Ẹ dá ọkàn yín lórí àwọn nǹkan tí òkè” (3:1-2).
Báwo ni a ti lè kojú ẹ̀ṣẹ̀? Nípa dídá èrò wa lórí Kristi. O kò lè yí ọkàn rẹ padà nípasẹ̀ sísọ wípé rárá sí àwọn nǹkan tí o fẹ́. Àmọ́ o lè yí ọkàn rẹ padà nípasẹ̀ dídá gbogbo èrò rẹ lórí Kristi.
Nígbà tí o bá rán ara rẹ létí wípé “a ti jí ọ dìde pẹ̀lú Kristi” (3:1), ọkàn rẹ ma kún fún àwọn ìfẹ́ ńlá. Àwọn ìfẹ́ yìí ni yóò wá ṣe àtúntò ọkàn rẹ láti ṣe ǹkan tí sísẹ́-ara-ẹni kò lè ṣe láéláé. Dídá èrò ọkàn rẹ lórí Kristi àti Ìhìn Rere Rẹ̀ yóò pa ẹ̀ṣẹ̀ nínú ayé rẹ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Kristiẹni gbàgbọ́ pé ọ̀nà kan ṣoṣo láti borí ẹ̀ṣẹ̀ ni láti fi ara mọ́-ọn kí a sì má ṣubú sí inú ìdánwò. Ṣùgbọ́n ìwọ kò lè fi ọkàn rẹ ja ẹ̀ṣẹ̀; o gbọ́dọ̀ fi ọkàn rẹ jà á. Ètò ọjọ́ mẹ́wàá yìí da l'órí ìwé Rewire Your Heart, ó sì wo díẹ̀ nínú àwọn ẹsẹ̀ tí ó pàtàkì jù lọ nípa ọkàn rẹ tí yoo ràn ọ́ l'ọ́wọ́ l'áti ṣe àwárí bí o ṣe lè k'ojú ẹ̀ṣẹ̀ nípa gbígba Ìhìnrere ní ààyè láti tún ọkàn rẹ ṣe.
More