Tún Ọkàn Rẹ Tò: Ọjọ́ 10 Láti Ba Ẹ̀ṣẹ̀ JàÀpẹrẹ

Rewire Your Heart: 10 Days To Fight Sin

Ọjọ́ 9 nínú 10

Ohun Gbogbo Wá Láti Inú Ọkàn

Ohun gbogbo tí à ń ṣe ń ti inú ọkàn wa wá.

Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí Bíbélì gbà láti sọ òtítọ́ yìí ní kedere ni a lè rí nínú Ìwé-owe 4:23. A lè fi ìdí èrò yìí múlẹ̀ ní kedere nítorípé ó ní àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ méjì nínú. Àkọ́kọ́ rẹ̀ kò ṣe àjèjì sí wa - ọkàn rẹ.

Nínú ọkàn òǹkọ̀wé Ìwé-òwe àti àwọn tí wọ́n tẹ́tí gbọ́ ọ ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, ọkàn gan an ni kókó ohun tí ènìyàn jẹ́. Ọkàn jẹ́ àkópọ̀ èrò, ìfẹ́-inú, ẹ̀rí-ọkàn àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ.

Àfiwé kejì kò ṣòro láti mọ̀ pẹ̀lú. Ó ṣe àkópọ̀ ọ̀rọ̀ méjì ní èdè àkọ́lò ti Hébérù. Ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ ń sọ nípa ibi tí ǹkan ti bẹ̀rẹ̀: orísun wọn, ibi ìbẹ̀rẹ̀, tàbí ibi tí àwọn ńkan ti ń tú jáde wá. Ọ̀rọ̀ kejì ń sọ nípa ìyè. Àfiwé yìí dàbí í odò ìyè tàbí ibi tí ó jẹ́ orísun tí gbogbo ẹ̀mí-ààyè ti ṣẹ̀ wá.

Ìwọ pá àfarawé méjèèjì yìí pọ̀, ìwọ yíó sì rì àwòràn gbogbo ẹ̀mí tí ó ń ṣàn wá láti ibi orísun ọkàn.

Gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ Bíbélì yìí, àwọn ohun tí a fẹ́, àti tí a kórira, ìtẹ̀sí-èrò àtí ìmọ̀lára ní ń rú ohun gbogbo tí a ń ṣe sókè.

Látàrí èyí, òǹkọ̀wé Ìwé-òwe rọ̀ wá láti pa ọkàn wa mọ́. Báwo ni a ó ṣe ṣe èyí? Nínú ìwé yìí, ìdáhùn rẹ̀ rọrùn: ṣe àwárí ọgbọ́n.

Ìwé-òwe kún fún àwọn ohun tí a gbọ́dọ́ ta kété sí tàbí ohun tí a gbọ́dọ̀ lépa. Ṣùgbọ́n lékè gbogbo rẹ̀, a ní láti kíyèsí pé, “ọgbọ́n” nínú Ìwé-òwe jẹ́ ènìyàn. Òun ní a gbọ́dọ̀ lépa àti ẹni tí ó ń tọ̀ wá wá.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí sọ tipẹ́tipẹ́ pé Jésù ni ògidì àpẹẹrẹ arabìnrin ọgbọ́n yìí. Òun ni ẹní tí ó ń fi Ọlọ́run hàn wá. Òun ni ẹni tí ó ń yí ọkàn wá padà pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ̀. Òun ni Ọ̀rọ Ọlọ́run tí ó ń tọ̀ wá wá. Òun ní ojú Ọlọ́run tí à ń wá.

Báwo ni a ṣe lè pa ọkàn wa mọ́? A ó wàá Jésù. A ó yọ̀ nínú òtítọ́ Ìhìnrere. A ó ṣe àṣàrò lórí ẹ̀bùn àgbélélèbú. A ó yọ̀ nínú agbára àjíńde. A ó fetísí ẹ̀kọ́ ẹnu rẹ̀. A ó tèlé ohùn Ẹ̀mí Rẹ. A ó dúró ní ìrètí ìpadàbọ̀ Rẹ̀ ní kíkún àti ní àkótán.

Ohun gbogbo tí ò ń ṣe wá láti inú ọkàn. Ṣe o fẹ́ yí ohun tí ò ń ṣe padà? Tèlé Jésù, Òun yìó sì pa ọkàn rẹ mọ́.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Rewire Your Heart: 10 Days To Fight Sin

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Kristiẹni gbàgbọ́ pé ọ̀nà kan ṣoṣo láti borí ẹ̀ṣẹ̀ ni láti fi ara mọ́-ọn kí a sì má ṣubú sí inú ìdánwò. Ṣùgbọ́n ìwọ kò lè fi ọkàn rẹ ja ẹ̀ṣẹ̀; o gbọ́dọ̀ fi ọkàn rẹ jà á. Ètò ọjọ́ mẹ́wàá yìí da l'órí ìwé Rewire Your Heart, ó sì wo díẹ̀ nínú àwọn ẹsẹ̀ tí ó pàtàkì jù lọ nípa ọkàn rẹ tí yoo ràn ọ́ l'ọ́wọ́ l'áti ṣe àwárí bí o ṣe lè k'ojú ẹ̀ṣẹ̀ nípa gbígba Ìhìnrere ní ààyè láti tún ọkàn rẹ ṣe.

More

A fẹ́ dúpẹ́ ní ọwọ́ Spoken Gospel fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé sí iwájú síi, ṣe àbẹ̀wò sì:https://bit.ly/2ZjswRT