Tún Ọkàn Rẹ Tò: Ọjọ́ 10 Láti Ba Ẹ̀ṣẹ̀ JàÀpẹrẹ

Bíbá È̩ṣẹ̀ Jà Pẹ̀lú Ìdùnnú
Nígbà tí àkókò bá le gan an, ó rọrùn púpọ̀ láti dá ẹ̀sẹ̀. Orin Dáfídì 37 sọ nípa bí a ṣe lè ní ìfaradà ní àkókò tí nǹkan bá le gidi gan an.
Dáfìdì, Onísáàmù, kọ nípa bí àwọn ènìyàn búburú ṣe ń ṣe aburú. Báwo ni kí Dáfìdì àti àwọn ènìyàn náà ṣe dáhùn? Dáfìdì sọ pé kí á dáhùn pẹ̀lú ìdákẹ́jẹ́, sùúrù, àti ìgbàgbọ́.
Ṣùgbọ́n báwo ni ìyẹn pàápàá ṣe ṣeé ṣe? Báwo ni a ṣe lè kàn jókòó kalẹ̀ kí á sì gbà á? Báwo ni a ṣe lè jókòó jẹ́ẹ́ nígbà tí gbogbo nnkan ń pòòyì ní àyíkáa wa? Báwo ni a ṣe lè ní sùúrù nígbà tí gbogbo nnkan kò lọ déédéé? Báwo ni a ṣe lè ní ìgbàgbọ́ nígbà tí ó dàbíi pé gbogbo ìrètí ti dé òpin?
Ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn rere ló wà nínú Sáàmù yìí láti dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí. Àmọ́ ọ̀kan lára àwọn tó lẹ́wà jùlọ, tó ṣe ìrànwọ́, tó sì gbajú-gbajà jùlọ wà nínú Orin Dafidi 37:4.
“Jẹ́ kí inú rẹ máa dùn ninu OLUWA; yóo sì fún ọ ní ohun tí ọkàn rẹ ń fẹ́.”
Ẹsẹ yìí ṣe ìrànlọ́wọ́ gan an fún ìdí méjì pàtàkì.
Ní àkọ́kọ́, ìfaradà àti bíbá ẹ̀ṣẹ̀ jà kò nílò láti jẹ́ nǹkan ìbànújẹ́. A pè wá láti ṣe àwárí ìdùnnú ni! Ṣùgbọ́n ibo ni a ti lè rí ìdùnnú yìí nígbà tí gbogbo nǹkan kò ní ojútùú? A kò lè rí wọn ní agbègbèe wa. A kò lè rí wọn nípa pé kí á máa fi ọ̀kàn sí nǹkan tí ó ń dán nìkan. Rárá.
À ń rí ìdùnnú nínú Olúwa. À ń dun ara wa nínú nínú Ọlọ́run. Fún wa gẹ́gẹ́ bí Krìstẹ́nì, ọ̀nà tí ó dára jùlọ láti ṣe èyí ni kí á máa ṣe àtúnsọ ìròhìn rere tí ó wà nínú Ìhìnrere fún ara wa. Jésù ti gbà ọ́ là kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ó ti gba ìjìyà rẹ. O ti bá Bàbá làjà. A ti sọ ọ́ di tẹ́mpìlì Ọlọ́run alààyè. Ní inú didùn sì gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún ọ.
Ìdí kejì tí ẹsẹ yìí fi ṣe ìrànlọ́wọ́ ni pé a rí nǹkan kan gbà. Kìí ṣe pé a kò nílò láti ba inú jẹ́ nìkan, ṣùgbọ́n a tún rí ohun kan tí ó dára gbà. A rí àwọn ìfẹ́ ọkàn wa gbà.
Kínni àwọn ìfẹ́ ọkàn wa tí a ó fi fún wa ní àwọn àkókò ìdààmú? Ó dára, ohun tí a ti ń ní inú dídùn sí yẹn gan an ni. A ó bá Ọlọ́run pàdè!
Láìbìkítà ipò náà àti láìbìkítà ẹ̀ṣẹ̀ náà, tí o bá ní inú dídùn nínú Ọlọ́run Ìhìnrere ìwọ yóò rí Ọlọ́run Ìhìnrere gbà. Yọ̀ nínú Jésù Jésù yóò sì fi ara Rẹ̀ hàn ọ́.
Bí a ṣe ń bá ẹ̀ṣẹ̀ jà nìyẹn ní àkókò ìṣoro. Ja ìjà náà pẹ̀lú ọkàn rẹ. Ní inú dídùn sí Ọlọ́run.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Kristiẹni gbàgbọ́ pé ọ̀nà kan ṣoṣo láti borí ẹ̀ṣẹ̀ ni láti fi ara mọ́-ọn kí a sì má ṣubú sí inú ìdánwò. Ṣùgbọ́n ìwọ kò lè fi ọkàn rẹ ja ẹ̀ṣẹ̀; o gbọ́dọ̀ fi ọkàn rẹ jà á. Ètò ọjọ́ mẹ́wàá yìí da l'órí ìwé Rewire Your Heart, ó sì wo díẹ̀ nínú àwọn ẹsẹ̀ tí ó pàtàkì jù lọ nípa ọkàn rẹ tí yoo ràn ọ́ l'ọ́wọ́ l'áti ṣe àwárí bí o ṣe lè k'ojú ẹ̀ṣẹ̀ nípa gbígba Ìhìnrere ní ààyè láti tún ọkàn rẹ ṣe.
More