Tún Ọkàn Rẹ Tò: Ọjọ́ 10 Láti Ba Ẹ̀ṣẹ̀ JàÀpẹrẹ

Ẹ̀ṣẹ̀ Kò Tinú Ìdánwò Wá
Èrò mi bí mo ṣe ń dàgbà nipé ìdánwò ni orísun ẹ̀ṣẹ̀. Ní ọjọ́ yówù kó jẹ́, tí mo ń bá iṣẹ́ mi lọ lẹ́sẹ̀ kannáà ni ìdánwò yóò yọ jáde: ọmọbìnrin arẹwà á rìn kọjá, ọ̀rẹ́ kan bẹ̀rẹ̀ àwàdà ìsọkúsọ, ẹ̀dà àyẹ̀wò ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ bọ́ sí mi lọ́wọ́. Ó di ojúṣe fún mi, lójúkannáà, láti ja ìjàkadì pẹ̀lú ìdánwò nípa sí sọ rárá síi tàbí kí ń sá fún pátápátá. Ìdánwò ni ọ̀tá náà. Ìjákulẹ̀ túmọ̀sí ẹ̀ṣẹ̀.
Ṣùgbọ́n ìṣòro bè gan kọ́ ni ìdánwò. Ìṣòro ibẹ̀ gangan wá láti inú ọkàn tí àwọn ìfẹ́ ara ti ń wá.
Ìdánwò kò lè yọjú láì ṣe pé ìfẹ́ ara ti kọ́kọ́ wà. A kò le dán ènìyàn wò láti ṣe ohun tí kò ti kọ́kọ́ ní lọ́kàn láti ṣe.
Bíbélì kọ́ wa wípé ìfẹ́kúfẹ́ ara ni ó máa ń mú ìdánwò wá. “Ṣugbọn olukuluku ni a ndanwò, nigbati a ba ti ọwọ́ ifẹkufẹ ara rẹ̀ fà a lọ ti a si tàn a jẹ. Njẹ, ifẹkufẹ na nigbati o ba lóyun, a bí ẹ̀ṣẹ: ati ẹ̀ṣẹ na nigbati o ba si dagba tan, a bí ikú.” (1:14–15). Nígbà wo ni ẹ̀ṣẹ̀ máa ń wáyé? Lẹ́yìn tí ìfẹ́kúùfẹ́ ara bá ti fà wá mọ́ra. Ìdánwò kọ́ ló ún bí ìfẹ́kúùfẹ́ bíkòṣe ìfẹ́kúùfẹ́ ló ún bí ìdánwò.
Ìdánwò kò leè yọjú láì sí ìfẹ́kúùfẹ́ ara. Nkò le gbà ọ níyànjú láti jẹ konkéré, láìṣepé ìwọ tìkára ti ún ní èròńgbà láti jẹ. Níwọ̀n ìgbà tí o sì mọ̀ pé jíjẹ konkéré kò mọ ní ohun tí kò rọrùn nìkan ṣùgbọ́n ó tún lè mú ìpalára wá, irú ìdánwò báyìí kò leè rí ọwọ́ mú. Kódà, àṣìsọ làti pe irú bẹ́ẹ̀ ní ìdánwò. A kò le pe ohunkóhun ní ìdánwò èyítí tí kò ní àfijọ kankan mọ́ ìdánwò. Kí ìdánwò tó le wà, ìfẹ́ ara gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ wà.
Kìkì oun tí ìdánwò lè ṣe ni láti tọ́ka àǹfààní lati mú ìfẹ́kúùfẹ́ tó wà nínú ṣẹ. Ronú sí bí àwọn adánniwò ṣe ń sábà ṣẹ̀tàn, “O mọ̀ pé o fẹ́ẹ.” Ìdánwò a mú ohun tí ó máa ń ru ìfẹ́kúùfẹ́ sókè á tún wá mú u kí ó dùn ún wò síi.
Ó di ìgbà tí a bá fojú sí ìfẹ́ ara láti inú ọkàn wá dípò àwọn ìdánwò láti òde ni a ó tó lè dojúkọ ẹ̀ṣẹ̀ láti gbòǹgbò rẹ̀ wá. Ó dìgbà tí a bá wo ohun tí a fẹ́, yàtọ̀ sí ohùn tí a ṣe, nígbànáà ni a ó sún mọ́ góńgó ibi tí ogun ẹ̀ṣẹ̀ ti ń jà.
Báwo sì ni áyípadà ṣe ń ṣẹlẹ̀ ní ọ̀nà tó jinlẹ̀ gidi? Báwo ni a ṣe ń ṣe ìsọdọ̀tun ìfẹ́ ara inú ọkàn wa? Bí a ṣe ti ríi nínú gbogbo ẹ̀kọ́ yí, ọ̀nà kan ṣoṣo tí ọkàn wa ṣe lè ní àyípadà ni nípa Ìhìnrere. Gbádùn Jésù, Òun yóò sì yí ọkàn rẹ padà.
Ọlọ́run nìkan ni Ó lè mú ìyípadà yí wá. Nítorínà kí á tẹ̀lé ọ̀rọ̀ Jákọ́bù ní òpin ìwé rẹ̀, “Ẹ sunmọ Ọlọrun, on o si sunmọ nyin” (4:8).
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Kristiẹni gbàgbọ́ pé ọ̀nà kan ṣoṣo láti borí ẹ̀ṣẹ̀ ni láti fi ara mọ́-ọn kí a sì má ṣubú sí inú ìdánwò. Ṣùgbọ́n ìwọ kò lè fi ọkàn rẹ ja ẹ̀ṣẹ̀; o gbọ́dọ̀ fi ọkàn rẹ jà á. Ètò ọjọ́ mẹ́wàá yìí da l'órí ìwé Rewire Your Heart, ó sì wo díẹ̀ nínú àwọn ẹsẹ̀ tí ó pàtàkì jù lọ nípa ọkàn rẹ tí yoo ràn ọ́ l'ọ́wọ́ l'áti ṣe àwárí bí o ṣe lè k'ojú ẹ̀ṣẹ̀ nípa gbígba Ìhìnrere ní ààyè láti tún ọkàn rẹ ṣe.
More