Tún Ọkàn Rẹ Tò: Ọjọ́ 10 Láti Ba Ẹ̀ṣẹ̀ JàÀpẹrẹ

Ìgbàgbọ́ A Máa Yí Ọkàn Padà
Kí ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa? Bí a ti ń bá ẹ̀kọ́ yìí bọ̀, a ti ríi wípé ọkàn wa ni àárín gbùngbùn ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ìwà mímọ́. Ṣùgbọ́n kí ló ma ń kóbá ọkàn?
Jésù fihàn wá nínú Ìwàásù Rẹ̀ Lórí Òkè wípé àìgbàgbọ́ ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa.
Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn Rẹ̀ wípé wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe àníyàn ohun tí wọ́n máa jẹ, mu, tàbí wọ̀ sára. Báwo ni èyí ti ṣeé ṣe? Di òní àwọn ènìyàn ní láti làágùn pẹ̀lú ìtiraka láti rí oúnjẹ òjọ́ọ wọn, iṣẹ́ kí-ẹ̀mí-má-bọ́ ni wọn kàn ń ṣe. Báwo ni màá ṣe bọ́ ẹbí mi, san owó ilé, tún ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́ ṣe? Ìdáhùn Jésù ni láti ní ìgbàgbọ́ nínú ìpèsè Ọlọ́run (Mátíù 6:25-30). Ohun tí a bá gbàgbọ́ ló ń yí ọkàn ẹni padà.
Jésù kọ́ wa ní òtítọ́ pàtàkì kan nípa bí ọkàn wa ti ń ṣiṣẹ́. Ní ọ̀nà kan Ó ń sọ wípé, “Níwọ̀n gbà tí Ọlọ́run bá ńṣe ǹkan kéékèèké, dájúdájú Ó máa ṣe èyí tó tóbi pẹ̀lú.” Ọlọ́run ń bọ́ àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run Ó sì ńṣe aṣọ fún koríko ẹ̀bá ọ̀nà. Èyí ni àrídájú wípé yóò bọ́ ẹ bẹ́ẹ̀ni yóò fi aṣọ wọ àwọn ọmọ rẹ. Gbàgbọ́ wípé Olùpèsè ni Ọlọ́run, yíò sì mú àníyàn rẹ kúrò. Ìgbàgbọ́ rẹ ma yí ọ lọ́kàn padà.
Ṣibesibe, àínìgbàgbọ́ má ń sọ ìdàkejì fún ọkàn wa. Bí Jésù ti ṣàlàyé, ẹ̀ṣẹ̀ ìpòrúru ọkàn má ńṣe àfihàn gbòǹgbò àínìgbàgbọ́ nínú ìpèsè Ọlọ́run. A máa ńṣe àníyàn nítorí a kò ní ìgbàgbọ́ wípé Ọlọ́run ma pèsè. Gbogbo onírúurú àínìgbàgbọ́ a máa kún ọkàn wa yóò sì padà ṣe àmúwá ẹ̀ṣẹ̀ tó múgbá lẹgbẹ rẹ̀.
Agbára Ọlọ́run kò lè ṣe ìpèsè. Ìfẹ́ Ọlọ́run kò tó láti tẹ́ni l'ọ́rùn. Òfin Ọlọ́run kò sí ní ìbámu pẹ̀lú ayọ̀ mi. Ẹ̀jẹ̀ Jésù kò tó fún ìwẹ̀nùmọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi. Iṣẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́ kò tó fún ìsọdi-mímọ́ mi. Ìhìnrere kò tó láti wo ìgbéyàwó mi sàn, láti fà mí jáde kúrò nínú àṣìlò ayé, tàbí láti pa ìkorò inú ọkàn mi lẹ́nu mọ́. A ń ṣe iyèméjì pé Ọlọ́run tó fún wa
Bí a kò bá lè gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, tani a fẹ́ gbẹ́kẹ̀lé? Gbogbo wa ti fèsì sí ìbéèrè yí pẹ̀lú “Ara mi nìkan!” nípasẹ̀ àwọn ìgbésẹ̀ wa a tó sọ wípé a máa bá gbogbo àìní wa pàdé. Nígbà tí a bá gbìyànjú láti mú ìfẹ́ wa ṣẹ nípa àyídáyidà ti ara wa, ǹkan tó máa ti ẹ̀yìn rẹ̀ jáde ni ẹ̀ṣẹ̀. Nígbà tí ọkàn wa bá kún fún àìgbàgbọ́, gbogbo ìdáwọ́lé wa ló máa yọrí sí òrìṣà tí a mọ fún ìfẹ́kúùfẹ́ ọkàn wa. Àwa ẹ̀dá aláìní ìgbàgbọ́!
Báwo ni a wá ṣe lè dojú ìjà kọ ẹ̀ṣẹ̀? Yí ọkàn rẹ padà. Báwo ni o ṣe lè yí ọkàn rẹ padà? Yí àwọn ohun tí o gbàgbọ́ nínú rẹ̀ padà.
Gbàgbọ́ wípé Jésù ti pèsè gbogbo ǹkan tí o nílò nínú Ìhìnrere náà bẹ́ẹ̀ni ọkàn rẹ yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní sá fún ẹ̀ṣẹ̀ tí yóò sì ma sá tọ Ọlọ́run lọ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Kristiẹni gbàgbọ́ pé ọ̀nà kan ṣoṣo láti borí ẹ̀ṣẹ̀ ni láti fi ara mọ́-ọn kí a sì má ṣubú sí inú ìdánwò. Ṣùgbọ́n ìwọ kò lè fi ọkàn rẹ ja ẹ̀ṣẹ̀; o gbọ́dọ̀ fi ọkàn rẹ jà á. Ètò ọjọ́ mẹ́wàá yìí da l'órí ìwé Rewire Your Heart, ó sì wo díẹ̀ nínú àwọn ẹsẹ̀ tí ó pàtàkì jù lọ nípa ọkàn rẹ tí yoo ràn ọ́ l'ọ́wọ́ l'áti ṣe àwárí bí o ṣe lè k'ojú ẹ̀ṣẹ̀ nípa gbígba Ìhìnrere ní ààyè láti tún ọkàn rẹ ṣe.
More