Tún Ọkàn Rẹ Tò: Ọjọ́ 10 Láti Ba Ẹ̀ṣẹ̀ JàÀpẹrẹ

Ohun Rere tàbí Búburú Wá Láti Inú Ọkàn
Kíni ohun tí ó ń mú wa ṣe rere tàbí búburú? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni wọ́n rò pé ó dá lé orí àwọn ìpinnu tí à ń ṣe. Bí o bá gbé ẹ̀mí lé e láti ṣe rere, ìwọ yíó ṣe é. Bí o bá yàn láti ṣe búburú, ohun nàá ni ìwọ yíó ṣe.
Ṣùgbọ́n Jésù kọ́ wa pé orísun àwọn ìṣe wa jinnú ju èyí lọ. Gbogbo rẹ̀ wá láti inú ọkàn.
“Ènìyàn rere láti inú ìṣúra rere ọkàn rẹ̀ ní í mú ohun rere jáde wá, àti ènìyàn búburú láti inú ìṣúra búburú ọkàn rẹ̀ ní í mú ohun búburú jáde wá, nítorí láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọkàn ni ẹnu rẹ̀ ń sọ.” (Lk. 6:45).
Ohunkóhun tí ó bá wà nínú ọkàn rẹ yíó jẹyọ ní ayé rẹ̀.
Ohun tí o káràmásìkí, náání, ṣògo nínú rẹ̀, tí o sì gbádùn yíó y'ọrí sí ohun tí ò ń ṣe. Bí o bá náání ohun rere nínú ọkàn rẹ, nígbánáà ìwọ yíó ṣe rere. Bí o bá náání ohun búburú, nígbánáà ìwọ yíó ṣe búburú.
Ní báyìí, báwo ni a ó ṣe yí ìsúra ọkàn wa padà? Ìdáhùn, nínú ọ̀rọ̀ Jésù, yàtọ̀ sí ohun tí a ní ní èrò. A lè máa retí àkọsílẹ̀ gbọọrọ tí ìsẹ́ra-ẹni, ìhùwàsí, tàbí àṣàrò tí yíó yí ohun tí ọkàn wa náání padà.
Ẹ̀wẹ̀, ipò ọkàn rẹ kò dá lé orí ohun tí o ṣe, ṣùgbọ́n ẹni tí ọ jẹ́. Jésù kọ́ wa wípé igi rere kò lè mú èso búburú jáde wá bẹ́ẹ̀ni igi búburú kò lè so èso rere. Igi rere nìkan ni ó lè so èso rere.
Nítorínáà, a ní láti bèèrè, báwo ni a ṣe lè di igi rere?
Iṣẹ́ Ìhìnrere ni ìyẹn. Jésù sọ wá di igi rere láìlákàsí èso búburú. Ó gbà wá là, Ó sí yí wa padà kí a tóó ṣe ohunkóhun láti yẹ fún ìyípadà yìí.
Ohun tí a ní láti ṣe ni kí a rí ara wa bí í igi rere tí Jésù tí fi wá ṣe, kí ọkàn wa sì náání Rẹ̀ lékè ohunkóhun.
Ṣe o fẹ́ pa ìṣe rẹ dà? Mọ rírì Jésù fún sísọ ọ́ di igi rere kóda nígbàtí ó jẹ́ pé ìwọ ni igi tí ó burú jù láyé.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Kristiẹni gbàgbọ́ pé ọ̀nà kan ṣoṣo láti borí ẹ̀ṣẹ̀ ni láti fi ara mọ́-ọn kí a sì má ṣubú sí inú ìdánwò. Ṣùgbọ́n ìwọ kò lè fi ọkàn rẹ ja ẹ̀ṣẹ̀; o gbọ́dọ̀ fi ọkàn rẹ jà á. Ètò ọjọ́ mẹ́wàá yìí da l'órí ìwé Rewire Your Heart, ó sì wo díẹ̀ nínú àwọn ẹsẹ̀ tí ó pàtàkì jù lọ nípa ọkàn rẹ tí yoo ràn ọ́ l'ọ́wọ́ l'áti ṣe àwárí bí o ṣe lè k'ojú ẹ̀ṣẹ̀ nípa gbígba Ìhìnrere ní ààyè láti tún ọkàn rẹ ṣe.
More