Tún Ọkàn Rẹ Tò: Ọjọ́ 10 Láti Ba Ẹ̀ṣẹ̀ JàÀpẹrẹ

Májẹ̀mú Láíláí Tábí Májẹ́mú Tuntun
Kíni ìyàtọ̀ tí ó wà láàrín Májẹ̀mú Láíláí àti Májẹ́mú Tuntun?
Ohun àkọ́kọ́ tí a gbọ́dọ̀ kíyèsí ni pé ọ̀rọ̀ yìí “májẹ̀mú” túmọ̀ sí “ìmùlẹ̀.” Nítorínáà ìbéèrè pàtó ni wípé, kíni ìyàtọ̀ tí ó wà láàrín májẹ̀mú láíláí àti májẹ́mú tuntun?
Òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyàtọ̀ ni ó wà. Ṣùgbọ́n ìyàtọ̀ tí ó jù níbẹ̀, tí Jeremáyà 31:31-34, mú wá ni ọkàn.
Májẹ̀mú láíláí ni èyí tí a fi fún Mósè àti àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì lẹ́hìn ìjádelọ wọn kúrò ní Íjíbítì. Májẹ̀mú yìí wá pẹ̀lú òfin. Òfin yìí pẹ̀lúu òfin mẹ́wàá tí ó gbajúgbajà. Bí Ísírẹ́lì bá pa òfin yìí mọ́, a ó gbà wọ́n láàyè láti wá níwájú Ọlọ́run ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀.
Ẹ̀wẹ̀, Ísírẹ́lì kò pá májẹ̀mú yìí mọ́. Gbogbo ìgbà ni wọ́n ń rú òfin Ọlọ́run.
Kíni ìdí tí wọn kò fi lè pá májẹ́mú yìí mọ́? Nítorípé òde-ara ni òfin yìí wà. Kò sí ní inú wọn.
Májẹ̀mú tuntun yìí yíó yàtọ̀. Ọlọ́run yíó kọ òfin májẹ̀mú yìí sí ọkàn àwọn ènìyàn Rẹ̀. Yíó wà nínú wọn.
Òfin òde-ara kò lè yí inú padà. Ìyípadà ní láti ti inú wá kí a tó lè gbọ́ràn sí òfin ní òde.
A máa ń gbìyànjú láti yí ara wa padà pẹ̀lú ipá òde-ara ní gbogbo ìgbà. Nípa orísirísi ìlànà, ìséra, ètò, àti àkámọ́, à ń gbìyànjú láti yí ìṣe wa padà. À ń gbìyànjú láti kọ ojú-ìjà sí ẹ̀ṣẹ̀, láti di mímọ́ àti láti yí ìhùwàsí wa padà nípa òfin òde-ara. Ṣùgbọ́n eléyìí kò lè ṣiṣẹ́ láíláí.
Òfin kìí yí ọkàn padà.
Nítorínáà báwo ni Ọlọ́run ṣe ń fi májẹ̀mú tuntun yí ọkàn wa padà? Òun ní ó pa gbogbo ìlànà májẹ̀mú mọ́ fún wa nínú Jésù. Jésù kú lábẹ́ ègún òfin tí ó tọ́ sí wa, Ó sì fún wa ní ìbùkún májẹ̀mú tí ó tọ́ sí Òun. Èyí ná an ní ẹ̀mí Rẹ̀ lórí àgbélèbú. Irú ìfarajìn báyìí ń mi ọkàn wa ní ọ̀ná tuntun.
Ṣùgbọ́n kìí ṣe ní kìkì kí a gbọ́ ìtàn Ìhìnrere nìkan ní ìyípadà ṣe ń dé bá ọkàn wa. Ohun mìíràn ní láti ṣẹlẹ̀. Ṣebí, a gba àwọn ọmọ̀ Ísírẹ́lì là kúrò ní Íjíbítì tí ọkàn wọn sì wà bákannáà ní yíyigbì sí Ọlọ́run.
Ohun kan ní láti ṣelẹ̀ nínú wa. Ìdí nìyìí tí Ọlọ́run fi fún wa ní Ẹ̀mí-mímọ́. Ẹ̀mí ń yí wa ní ọkàn padà kí a baà lè gbà ìhìnrere gbọ́, gbádùn ìhìnrere, kí a sì dá Ọlọ́run lóhùn nítorí Ìhìnrere.
Ìyàtọ̀ tí ó wà láàrín Májẹ̀mú láíláí àti Májẹ́mú Tuntun ni pé májẹ́mú tuntun ń yí ọkàn wa padà kí a baá lè gbọ́ràn sí Ọlọ́run ní àìnì akùdé.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Kristiẹni gbàgbọ́ pé ọ̀nà kan ṣoṣo láti borí ẹ̀ṣẹ̀ ni láti fi ara mọ́-ọn kí a sì má ṣubú sí inú ìdánwò. Ṣùgbọ́n ìwọ kò lè fi ọkàn rẹ ja ẹ̀ṣẹ̀; o gbọ́dọ̀ fi ọkàn rẹ jà á. Ètò ọjọ́ mẹ́wàá yìí da l'órí ìwé Rewire Your Heart, ó sì wo díẹ̀ nínú àwọn ẹsẹ̀ tí ó pàtàkì jù lọ nípa ọkàn rẹ tí yoo ràn ọ́ l'ọ́wọ́ l'áti ṣe àwárí bí o ṣe lè k'ojú ẹ̀ṣẹ̀ nípa gbígba Ìhìnrere ní ààyè láti tún ọkàn rẹ ṣe.
More