Ayọ̀ fún Ìrìnàjò náà: Wíwá Ìrètí ní Àárín ÌdánwòÀpẹrẹ

Àjọ tí mò ń ba ṣiṣẹ́ maá ń ṣe ètò ìkówójọ fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (5,000) owó ní ọdọọdún, ní ọdún tí ó kọjá, mo pinnu pé èmi ni màá bójú tó gbogbo ètò náà. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé èmi kì í ṣe sárésáré, mo mọ̀ pé mo ní láti tètè bẹ̀rẹ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kí n lè ní ìfaradà láti sá eré ìje náà dé òpin. Àwọn sárésáré máa ń ní ìfaradà bí wọ́n bá sáré fún kìlómítà kan sí i ní ìgbà tí wọ́n bá fẹ́ já'wọ́ (tàbí ní tèmi, bí mo bá sáré fún ìṣẹ́jú kan sí i... àti ìṣẹ́jú mìíràn sí i).
Ní ọ̀nà kannáà, ìdánwò ń fún àwọn iṣan ẹ̀mí wa ní okun, ìdánwò ìgbàgbọ́ wa sì ń jẹ́ kí a ní ìfaradà. Ìrírí kọ̀ọ̀kan tí a ní ń jẹ́ kí ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Rẹ̀ túnbọ̀ ní agbára sí i. Ìdàgbàsókè máa ń wáyé ní ìgbà tí a bá b'orí ìṣòro, bí a ṣe ń f'ara dà á.
Ronú nípa ìdánwò kan tí o rò pé kò ní í sanmọna. Báwo ni Ọlọ́run ṣe lo ìdánwò náà? Báwo ni Ó ṣe ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi ara da ìdánwò náà? Kíni ohun tí o rí kọ́ bí o ṣe ń la ìdánwò náà kọjá?
Ìdánwò kì í rọrùn, wọ́n sì máa nira, síbẹ̀ Ọlọ́run máa ń lo àwọn ìdánwò náà. Ìdánwò ní agbára láti mú ohun rere jáde nínú wa, ìdí nìyìí tí ó fi jẹ́ pé àǹfààní ni wọ́n jẹ́ láti fi ayọ̀ hàn.
Fún àpẹẹrẹ, àwọn ohun rere àti ayọ̀ tí Ọlọ́run mú wá fún mi ní ààrin ìdànwò ìwà bárakú ọkọ mi rèé:
- Ìgbéyàwó tí ó ní agbára sí i.
- Òye àwọn ààlà àti ìmúṣẹ wọn.
- Mímọ ohun tí àbójútó ara ẹni túmọ̀ sí àti ṣíṣe é.
- Gbígba ara mi láàyè láti mọ̀ bí nǹkan ṣe rí ní ara mi àti bí mo ṣe lè máa fi ọgbọ́n bójútó wọn.
Ayọ̀ kìí ṣe ohun tí o fi ìdí múlẹ̀ nínú ipò ìgbésí ayé ènìyàn; ó jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó dúró ṣinṣin nínú Ọlọ́run ńlá tí ó ń ṣiṣẹ́ fún ire bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò rí ojú ọ̀nà ní kíákíá, tí ó sì jẹ́ pé a lè rí ayọ̀ ní ìgbà tí a bá b'ojú wo ẹ̀yìn.
Bí o ṣe ń ka ìwé-mímọ́ ti òní, ràntí pé ayọ̀…
- wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fúnraarẹ̀ (Gàlátíà 5:22-23)
- mọ̀ pé ète wà ní ààrin gbogbo ìdánwò. (Jeremáyà 29:11)
- wà ní iwájú Ọlọ́run (Sáàmù 16:11)
- ni agbára ìkọ̀kọ̀ wa (Nehemáyà 8:10)
Kay Warren kọ̀wé ní ìgbà kan pé, "Ayọ̀ ni ìdánilójú pé Ọlọ́run ní ó ń darí gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní ìgbésí ayé mi, ìfọ̀kànbalẹ̀ jẹ́jẹ́ pé ní ìkẹyìn ohun gbogbo yíó dára, àti ìpinnu láti yin Ọlọ́run nínú gbogbo ipò tí mo bá bá ara mi.”
A ó d'ojú kọ ìdánwò àti ìpọ́njú, ṣùgbọ́n èmi àti ìwọ ní ìpinnu láti ṣe nínú àwọn ìdánwò náà. A lè rí ayọ̀ nínú ìdánwò náà nípa kíkẹ́kọ̀ọ́, nípa títẹ̀síwájú, àti nípa gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run . . . tàbí kí á kọjú ìjà sí ìdánwò náà kí á sì báa jaguṇ - èyí yíó mú wa lọ sí ipa ọ̀nà tí ó nira, tí ó le, tí ó ṣe gbọ́ngun-gbọ̀gun, tí ó sì ń kó'ni sí yọ́ọ́yọ́ọ́.
Èwo ni ìwọ yàn?
Nípa Ìpèsè yìí

A lè má rí i tàbí ní í l'érò ní ìgbà gbogbo, ṣùgbọ́n Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa ní ìgbà gbogbo... kódà ní ìgbà tí a bá ń la àwọn ìṣòro kọjá. Nínú ètò yìí, Amy LaRue Olùdarí Finding Hope ṣe àkọsílẹ̀ àtọkànwá nípa ìjàkadì ìdílé rẹ̀ pẹ̀lú ìwà bárakú àti bí ayọ̀ Ọlọ́run ṣe jẹyọ ní àwọn àkókò tí ó nira jùlọ.
More









