Neh 8:9-12

Neh 8:9-12 YBCV

Ati Nehemiah ti iṣe bãlẹ, ati Esra alufa, akọwe, ati awọn ọmọ Lefi, ti o kọ́ awọn enia wi fun gbogbo enia pe, Ọjọ yi jẹ mimọ́ fun Oluwa Ọlọrun nyin; ẹ má ṣọ̀fọ ki ẹ má si sọkún. Nitori gbogbo awọn enia sọkún, nigbati nwọn gbọ́ ọ̀rọ ofin. Nigbana ni o wi fun wọn pe, Ẹ lọ, ẹ jẹ ọ̀ra ki ẹ si mu ohun didùn, ki ẹ si fi apakan ipin ranṣẹ si awọn ti a kò pèse fun: nitori mimọ́ ni ọjọ yi fun Oluwa: ẹ máṣe banujẹ; nitori ayọ̀ Oluwa on li agbàra nyin. Bẹ̃ni awọn ọmọ Lefi mu gbogbo enia dakẹ jẹ, wipe, ẹ dakẹ, nitori mimọ́ ni ọjọ yi; ẹ má si ṣe banujẹ. Gbogbo awọn enia lọ lati jẹ ati lati mu ati lati fi ipin ranṣẹ, ati lati yọ ayọ̀ nla, nitoriti ọ̀rọ ti a sọ fun wọn ye wọn.