Ayọ̀ fún Ìrìnàjò náà: Wíwá Ìrètí ní Àárín ÌdánwòÀpẹrẹ

Bí a ṣé ń parí ìrìnàjò aláyọ̀ wa, mo fẹ́ kí o ronú nípa ẹni tí ó ń darí rẹ nínú ìrìnàjò rẹ sí ayọ̀. Ṣé ìwọ ni? Ṣé ẹni tí o ní ìfẹ́ sí ni? Ṣé ọ̀rẹ́ kan ni?
Àbí Ọlọ́run ni?
A níílò Ọlọ́run láti jẹ́ atọ́ka-ọ̀nà wa kí ó sì tọ́ wa sí ọ̀nà nínú àwọn àdánwò tí a ń da ojú kọ, bí bẹ́ẹ̀ kọ̀ọ́ a ó sìnà ọ̀nà pàtàkì, kọlu àpáta, a ó sì ṣubú sí iwájú àti síwájú síi kúrò nínú ayọ̀, ètò, àti ète Rẹ̀.
Atọ́ka-ọ̀nà jẹ́ irinṣẹ́ tí ó se pàtàkì fun ìpàgọ́, ìrìnàjò, tàbí àwọn ìṣẹ ní ibi tí a ti ń lo àkókò púpọ̀ ní ìta gbangba, pàápàá bí ó bá jẹ́ ìwọ nìkan. Ohun èlò yìí dúró ṣinṣin ní ìgbàkígbà tí ojú ọjọ́ kò bá dára àti pé ó rọrùn láti gbé ká. Atọ́ka-ọ̀nà jẹ́ ìṣọra ààbò tí o ṣe gbẹ́kẹ̀lé fún gbogbo ènìyàn láí wo ọjọ́-orí.
Kókó iṣẹ́ atọ́ka-ọ̀nà ní láti tọ́ ọ sí ọ̀nà tí ò ń lọ ní gbogbo ìgbà, èyí tí yíó mú kí ó ṣòro fún ọ láti sọnù. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, àwọn arìnrìn-àjò aláfẹsẹ̀rin-ọ̀nà-jíjìn àti arìnrìn-àjò alápò àgbékọ́ẹ̀yìn gbé ẹ̀mí lé àwọn atọ́ka-ọ̀nà láti mú wọn dé ibi tí wọ́n ń lọ nítorí pé ìṣìnà kan ṣoṣo lè j'ọrí sí àjálù—kódà ó lè mú ẹ̀mí lọ. Ṣùgbọ́n nípa lílò atọ́ka-ọ̀nà láti wá ààrin gbùngbùn àríwá, wíwá ọ̀nà rẹ kàn ní ọgangàn rọrùn.
Olúkúlùkù wa ni ó ní ẹ̀bùn atọ́ka-ọ̀nà láti tọ́ wa sọ́nà àti láti darí ìrìnàjò wa. O ní tìrẹ, àwọn àyànfẹ́ rẹ náà ní tiwọn.
Atọ́ka-ọ̀nà a máa ṣe déédéé. . . kò yípadà; o dúró déédéé ní ìgbà gbogbo, ó ṣeé gbẹ́kẹ̀lé ní ìgbà gbogbo, ó dúró ṣinṣin ní ìgbà gbogbo, ó sì ń tọ́ka wa sì èbúté wa.
Bẹ́ẹ̀ náà ni Baba wa ọ̀run. Olóòótọ́ ni, Òun sì ni ÀÀRIN GBUNGBUN wa.
Ní ìgbà tí a bá yàn láti gbẹ́kẹ̀lé atọ́ka-ọ̀nà wa, Òun yíó darí wa ní ìgbà gbogbo sí ibi AYỌ̀… laì bìkítà ipò wa. A le rí Ayọ̀ nínú Ìrìn àjò náà
Kì í ṣe láti fi ẹ̀rín èké s'ẹ́nu tàbí kí á díbọ́n bì ẹni tí inú rẹ̀ dùn ní ìgbà tí a wà nínú ìnira. Kìí ṣe pé kí a díbọ́n pé a kò jìyà, a kò ja ìjàkadì pẹ̀lú iyèméjì, tàbí kùnà látï rí bí Olọ́run ṣe lè mú ohunkóhun ti o dára jáde láti inú ipò naa.
Ó jẹ́ yíyàn láti wá ayọ̀ Rẹ̀ láàrin ìrora ọkàn. Ó jé gbígbà láti tẹríba fún ètò Ọlọ́run dípò ètò ti ara wa àti kí á mọ̀ pé ọ̀nà Rẹ̀ kìí ṣe ọ̀nà wa… ṣùgbọ́n ọ̀nà Rẹ̀, ní ìparí, dára ní ìgbà gbogbo nítorí pé Ó dára.
Lónìí, ohunkóhun tí ó lè máa fà ọ́ s'ẹ́yìn láti rí ayọ̀ ní inú ìrìnàjò yìí, kọ ọ́ sílẹ̀. Mo fẹ́ kí o yọ̀ǹda rẹ̀ fún Ọlọ́run. Mo fẹ́ kí o ní ìgbàgbọ́, kí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run pẹ̀lú ohun tí ó ń dà ọ́ láàmú tí ó sì ń mú ọ rẹ̀wẹ̀sì.
Ìṣesí wa ní àkókò ìdánwò ṣe pàtàkì. Ní ìgbà tí ìjàkadì náà bá ń lọ lọ́wọ́, àárẹ̀ lè mú wá, kí ó sì rẹ̀ wá, kí a já wa ní tànmọ́ọ̀, kí a sì rẹ̀wẹ̀sì.
Ṣùgbọ́n ní ìgbà tí a bá rántí pé ayọ̀ jẹ́ ohun ìjà wa tí ó farasin, yíó fún wa ní okun láti fi ara dà á ní ìgbà tí a bá rò pé a kò lè tẹ̀síwájú. Nípa rírántí pé ti Olúwa ni ogun yìí, a lè mọ ayọ̀ Rẹ̀, kí a sì ní okun láti tẹpẹlẹ mọ́ ọ
Bí o bá rí i pé o níílò ìwúrí díẹ̀ sí nínú ìrìnàjò yìí, mo gbà ọ́ ní ìyànjú láti wá Finding Hope (Wíwá ìrètí), ẹgbẹ́ alátìlẹyìn fún àwọn tí àwọn àyànfẹ́ wọ́n ní ìwà bárakú kan
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

A lè má rí i tàbí ní í l'érò ní ìgbà gbogbo, ṣùgbọ́n Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa ní ìgbà gbogbo... kódà ní ìgbà tí a bá ń la àwọn ìṣòro kọjá. Nínú ètò yìí, Amy LaRue Olùdarí Finding Hope ṣe àkọsílẹ̀ àtọkànwá nípa ìjàkadì ìdílé rẹ̀ pẹ̀lú ìwà bárakú àti bí ayọ̀ Ọlọ́run ṣe jẹyọ ní àwọn àkókò tí ó nira jùlọ.
More