O. Daf 16:1-11

O. Daf 16:1-11 YBCV

ỌLỌRUN, pa mi mọ́: nitori iwọ ni mo gbẹkẹ mi le. Ọkàn mi, iwọ ti wi fun Oluwa pe, Iwọ li Oluwa mi: emi kò ni ire kan lẹhin rẹ. Si awọn enia mimọ́ ti o wà li aiye, ani si awọn ọlọla, lara ẹniti didùn inu mi gbogbo gbe wà. Ibinujẹ awọn ti nsare tọ̀ ọlọrun miran lẹhin yio pọ̀: ẹbọ ohun mimu ẹ̀jẹ wọn li emi kì yio ta silẹ, bẹ̃li emi kì yio da orukọ wọn li ẹnu mi. Oluwa ni ipin ini mi, ati ti ago mi: iwọ li o mu ìla mi duro. Okùn tita bọ́ sọdọ mi ni ibi daradara; lõtọ, emi ni ogún rere. Emi o fi ibukún fun Oluwa, ẹniti o ti nfun mi ni ìmọ; ọkàn mi pẹlu nkọ́ mi ni wakati oru. Emi ti gbé Oluwa kà iwaju mi nigbagbogbo; nitori o wà li ọwọ ọtún mi, a kì yio ṣi mi ni ipò. Nitorina ni inu mi ṣe dùn, ti ogo mi si nyọ̀; ara mi pẹlu yio simi ni ireti. Nitori iwọ kì yio fi ọkàn mi silẹ ni ipò-okú; bẹ̃ni iwọ kì yio jẹ ki Ẹni Mimọ́ rẹ ki o ri idibajẹ. Iwọ o fi ipa ọ̀na ìye hàn mi; ni iwaju rẹ li ẹkún ayọ̀ wà: li ọwọ ọtún rẹ ni didùn-inu wà lailai.