Ayọ̀ fún Ìrìnàjò náà: Wíwá Ìrètí ní Àárín ÌdánwòÀpẹrẹ

Joy for the Journey: Finding Hope in the Midst of Trial

Ọjọ́ 2 nínú 7

Ní ìgbà tí àwọn ọmọ mi ṣì wà ní màjèsín, mo fi àwòrán ibi tí ìdílé wa ti ń rín lọ ní ipa ọ̀nà kan nínú ọgbà-ìtura sí orí ìkànnì ìbánidọ́rẹ̀. Àwòrán náà ní ìfìfẹ́hàn tó bí i 117 àti àwọn àsọyé bii:

  • Àwòrán ìdílé aláyọ̀ tí ó gba'yì.
  • Àwòrán yìí yẹ kí ó wà nínú fọ́rán ìpolówó ọjà kan ní ibì kan
  • Mo fẹ́ràn rẹ̀!
  • Ìdílé tí o rẹwà d'ọ́ba!

Ṣúgbọ́n àwòrán náà ń ṣe àfihàn ìdílé "tí ó ń díbọ́n" pé gbogbo ǹǹkan wà ní àlááfíà. Ìbá ṣe pé o wòó pẹ̀lú ìwòye mi ni, ìwọ ìbá rí:

  • Bàbá tí ó jẹ́ pé ó ṣeéṣe kí ó ti mu ọtí yó.
  • Àwọ́n arẹwà ọmọ àti aláìṣẹ̀ tí wọn kò mọ ohun tí ó ń lọ, tí ó jẹ́ pé wọ́n ní ẹ̀tọ́ sí àwọn òbí ọlọ́pọlọ pípé ṣúgbọ́n tí ó jẹ́ pé bàbá wọn kò bìkítà fún ìgbésí ayé wọn.
  • Ìyá tí ó jẹ́ pé ó ń jẹ oró nínú ìrora àti ìbínú, tí ó kàn ń fi tipátipá rẹ́rìín músẹ́, tí ó ń díbọ́n bí i ìdílé pípé, díbọ́n bí i ẹni tí ó ní ìdùnnú. Ìyá kan tí ó jẹ́ pé ó ń ronú bóyá ìgbésí ayé òun tilẹ̀ lè dára rárá, tí kò lè dáàbá àti wo ọkọ rẹ̀ l'ójú, tí ó ń pòǹgbẹ kíkankíkan pé kí ìgbésí ayé òun dára sí i ṣùgbọ́n tí kò ní ìrètí pé ó lè rí bẹ́ẹ̀.
  • Ìdílé tí ó wà nínú ìjì líle tí à ń pè ní ìwà bárakú.

Ní àìpẹ́ yìí, mo tún fi àwòrán ìdílé wa bí a ti rí ní ìsinsìnyí. Ó ní ìfìfẹ́hàn bí i 150 àti àwọn àsọyé bí i:

  • Ẹbí tí ó rẹwà
  • Mo fẹ́ràn ẹbí yìí gan an ni.
  • Àwòrán ńlá ti ìdílé tí ó wu'yì púpọ̀
  • Àwòràn tí ó gba'yì

Ní àsìkò yìí, àwòrán yìí ṣe àfihàn ìdílé tí wọ́n ti wà ní—tí wọn yíó sì tún máa wà ní—ìrìnàjò ìmúláradá. Mo wòó mo sì rí:

  • Bàbá tí ó bìkítà fún àwọn ìgbésí ayé ọmọ rẹ̀, tí ó ń la ètò ìmúláradá kọjá, ẹnití ó ṣe àyẹ̀wò pẹ̀lú onígbọ̀wọ́ rẹ̀ ní ìṣẹ́jú díẹ̀ ṣáájú kí ó tó ya àwòrán yìí.
  • Àwọn arẹwà ọmọ tí wọ́n rí àwọn òbí wọn ọlọ́pọlọ pípé tí wọ́n ń lépa ìmúláradá nípasẹ̀ àwọn ìpàdé, ìgbàmọ̀ràn, àti ètò onígbọ̀nwọ́.
  • Ìyá tí ó ni agbára, tí kò níílò láti díbọ́n ṣùgbọ́n tí ó lè sọ ní òtítọ́ ohun tí òun ń là kọjá.
  • Ọkọ àti aya tí wọ́n ti ṣe iṣe kára láti ṣe àgbékalẹ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé àti ìgbéyàwó tí ó ní agbára lónìí jú ìgbà tí ìwà bárakú ń j'ọba lórí wọn lọ.
  • Ìdílé tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, tí wọ́n sì ń ṣe àtììlẹ́yìn fún ara wọn, tí wọ́n kò tijú láti sọ wípé ǹǹkan kò ì tíì gún régé tó nítorí pé wọ́n ń rìn ìrìnàjò ìmúpadàbọ̀sípò
  • Ìdílé tí ó tí ṣe àwárí àlááfíà, ìrètí, àti ayọ̀.

Ìdìlé rẹ lè dàbíi ti àkọ́kọ́… tí ó ń tiraka láti ṣe àwàrí àlááfíà, ìrètí, àti ayọ̀. Tàbí bóyà ìdílé rẹ dàbí i ti ẹlẹ́ẹ̀kejì… ìdílé tí ó tí ṣe àwárí àlááfíà, ìrètí, àti ayọ̀ tí wọ́n sì tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò wọn.

Láìbìkítà irú “àwòrán” tí ó bá ọ mu jùlọ, Ọlọ́run wà nínú àwọn méjéèèjì.

Ọlọ́run wà ní ibẹ̀ nínú kòtò àti gegele. Ọlọ́run wà nínú àwọn ìṣẹ́gun àti àjálú. Ọlọ́run wà pẹ̀lú ẹbí mi ní ìgbà tí a ń díbọ́n, tí à ń tiraka láti wà láàyè, Ọlọ́run ṣì wà ní ibẹ̀ pẹ̀lú wa ní ìsinsìnyí bí a ṣe ń kéde oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ nípasẹ̀ ìlera àti àìlágbára wa.

Bí Ọlọ́run bá wà nínú GBOGBO ipòkípò, a lè gba AYỌ̀ láàyè nítòótọ́ nínú ìrìnàjò náà nítorí pé AYỌ̀ wa wà pẹ̀lú Rẹ̀.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Joy for the Journey: Finding Hope in the Midst of Trial

A lè má rí i tàbí ní í l'érò ní ìgbà gbogbo, ṣùgbọ́n Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa ní ìgbà gbogbo... kódà ní ìgbà tí a bá ń la àwọn ìṣòro kọjá. Nínú ètò yìí, Amy LaRue Olùdarí Finding Hope ṣe àkọsílẹ̀ àtọkànwá nípa ìjàkadì ìdílé rẹ̀ pẹ̀lú ìwà bárakú àti bí ayọ̀ Ọlọ́run ṣe jẹyọ ní àwọn àkókò tí ó nira jùlọ.

More

A fẹ́ dúpẹ́ l'ọ́wọ́ Ilé-iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Hope Is Alive fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: https://www.hopeisalive.net