Ayọ̀ fún Ìrìnàjò náà: Wíwá Ìrètí ní Àárín ÌdánwòÀpẹrẹ

Ó fẹ́ rẹ̀ẹ́ lè jẹ́ pé ní gbogbo ìgbà tí mo bá rin ìrìnàjò, ní mó máà ń ṣe alábapàdé àwọn ìṣẹ́po ọ̀nà ati gegele ni ojú ọ̀nà mi. Ọkọ̀ òfuurufú á ní ìdádúró, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí a ń yá lò kò níí sí nílẹ̀, ojú ọjọ́ á ṣe ìdíwọ́, iṣẹ́ ojú ọ̀nà a fà sún-kẹẹrẹ-fà-kẹẹrẹ ọkọ̀ ní ojú pópó, gbogbo iná tí ń darí ọkọ̀ á tan pupa.... àtòjọ náà kò ní òpin. Mo lè ṣe àníyàn, kí gbogbo rẹ̀ tí ojú sú mi, tàbí kí n ìrẹ̀wẹ̀sì, ṣùgbọ́n lẹ́yìnọ̀rẹyìn, màá tẹ síwájú èmi kò sì níí gba àwọn gegele náà láàyé láti dí mi lọ́wọ́ láti lọ sí ibi tí mo ní láti lọ.
Ìrìnàjò wá pẹ̀lú àwọn àyànfẹ́ wa rí bákan náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé a kò lè pinnu irú ìṣẹ́po ọ̀nà tí a ó kàn ní iwájú wa, a LÈ pinnu bí a ó ṣe gbára dì fún-un.
A kò le darí bí ìrìnàjò àwọn àyànfẹ́ wa yíó ti rí, kò níí fi ṣe bí a ṣe lè gbìyànjú tó, kó níí fi ṣe bí a ṣe lè ṣe ìwádìí tó, bí a ṣe lè bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú wọn tó, tàbí iye àwọn ilé ìmúniláradá tí a lè pè. Ìrìnàjò wọn jẹ́ tiwọn fúnraa wọn.
Nínú ìrírí ni mo ti ń sọ eléyìí. Mo gbìyànjú láti ṣe àkóso ìrìnàjò ọkọ mi, ṣùgbọ́ní ni ṣe ni ó tún bọ̀ ń mú ìbínú àti ìkórira wá sí i. Mo tùú lójú, mo bẹ̀ ẹ́, mo halẹ̀ mọ, mo pariwo mọ, mo yàn án lódì.... kíni mi kò ṣe tán. Ṣùgbọ́n ju gbogbo rẹ̀ lọ, èmi ni mo fẹ́ ìyípadà náà ju bí ọkọ mi ṣe fẹ́ ẹ lọ, èyí sì mú ìkórira, ìbínú, àìní ìfọ̀kànbalẹ̀, ìbẹ̀rù, ìkorò, ìbànújẹ́, àti àìní ìrètí bá mi.
Mo fẹ́ kí ìdílé mi padà bọ̀ s'ípò. Kí ọkọ mi padà bọ̀ s'ípò Mo fẹ́ àlàáfíà. Mo fẹ́ ìrètí.
Mo fẹ́ ayọ̀.
Ṣùgbọ́n mo kọ́ ẹ̀kọ́ wípé ìrìnàjò tí mo ní agbára lórí rẹ̀ ni èyí tí ó jẹ́ ti èmi gan-an fúnraà mi. Mo sì yẹ ní ẹni tí ó ń ní àlàáfíà, ìrètí, àti ayọ̀ láì bìkítà bí ìrìnàjò ẹlòmíràn ṣe lè rí—àti ti ọkọ mi pẹ̀lú. Mo lè yàn láti ṣe ìtọ́jú ara mi nìkan. Mó sì lè yàn láti dúró lórí ọ̀nà ìmúláradá mi.
Mo sì tún gbọdọ̀ rántí wípé Ọlọ́run wà pẹ̀lú mi nínú àwọn ìṣẹ́po ọ̀nà kọ̀ọ̀kan àti gegele tí ó wà ní ojú ọ̀nà náà. Ó mọ àwọn ìṣẹ́po ọ̀nà tí mo ń da ojú kọ. Mo ní láti rántí wípé gbogbo rẹ̀ jẹ́ ara ètò Rẹ̀, ara àwòrán ńlá náà tí Ó ní fún mi, àti ara ìpinnu Rẹ̀ fún mi.
Mo lè yàn láti gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run àti láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ayọ̀.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

A lè má rí i tàbí ní í l'érò ní ìgbà gbogbo, ṣùgbọ́n Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa ní ìgbà gbogbo... kódà ní ìgbà tí a bá ń la àwọn ìṣòro kọjá. Nínú ètò yìí, Amy LaRue Olùdarí Finding Hope ṣe àkọsílẹ̀ àtọkànwá nípa ìjàkadì ìdílé rẹ̀ pẹ̀lú ìwà bárakú àti bí ayọ̀ Ọlọ́run ṣe jẹyọ ní àwọn àkókò tí ó nira jùlọ.
More









