Ayọ̀ fún Ìrìnàjò náà: Wíwá Ìrètí ní Àárín ÌdánwòÀpẹrẹ

Joy for the Journey: Finding Hope in the Midst of Trial

Ọjọ́ 4 nínú 7

Ní inú ayé yí, awa yíó rí ìdánwò. Jésù tilẹ̀ sọ èyí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ nínú ìwé Jòhánù 16:33, Jákọ́bù ṣì ṣe àkọsílẹ̀ wípé a ní láti "Ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀ ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi, nígbàkúgbà tí ẹ̀yin bá bọ́ sì inú onírúurú ìdánwò nítorí pé ẹ̀yin mọ̀ pé ìdánwò ìgbàgbọ́ yín ń ṣíṣẹ́ ìpamọ́ra."

Ayọ̀. Báwo ni mo ṣe lè ní ayọ̀ ní ìgbà tí ọ̀dọ́mọkùnrin tàbí ọ̀dọ́mọbìrin mi bá di alárìnkiri? Báwo ni mo ṣé lè ní ayọ̀ ní ìgbà tí ọkọ mi jẹ́ ọ̀mùtí tí ó sì ń mú ọtí p'ara ní ojoojúmọ́, tí ó ń wọlé lóru-lóru? Báwo ni mo ṣe lè ní ayọ̀ ní ìgbà tí àyànfẹ́ mi kò bá fẹ́ ìmúláradá? Báwo ni ayọ̀ ṣe lè kún ọkàn mi ní ìgbà tí arákùnrin mi bá wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n?

Ọlọ́run fúnra Rẹ̀ mọ àwọn ìdánwò wá kí a tó là wọn kọjá, Ó sì mọ pàtó àkókò náà gan-gan tí wọn yíó kọlù wá. Kò sí ìdánwò náà tí a fi ara dà tí ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún-Un.

A lè má mọ àwọn ìdí tí tàbí bí wọn ṣe ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n Ọlọ́run mọ̀. Ó mọ ÌDÍ tí a fi ń la eléyìí kọjá, Ó sì ní ètò àti ète, ṣùgbọ́n ó kù sí wa lọ́wọ́ irú ìhà tí a ó kọ sí àwọn ìdánwò wọ̀nyìí.

Títẹ́wọ́gbà àti fífi ara mọ́ ìdánwò kò lè yọrí sí ìróni-lágbára pàtàkì láti takò wọn. A wà ní abẹ́ àkóso wọn gẹ́gẹ́ bí àwọn elòmíràn pẹ̀lú. Ní àárín ìdánwò, a lè jèrè ìwòye tí ó yàtọ̀ kí a sì fọ èsì tí ó dára sí àwọn irú ipò tí ó lè gbá ẹ̀mí àti ìrètí wa sọnù

A tilẹ̀ lè ní ìrírí ayọ̀ tí a bá ń lá òkè ìṣòro kọjá ní ìgbà mìíràn

A lè yàn láti jókó sí inú ìdánwò wá kí a sì gbìyànjú láti "yanjú rẹ̀" fúnra wa nítorí pé a gbàgbọ́ pé ìmọ̀ wa tayọ, ṣùgbọ́n èyí yíó kàn sọ wá di ẹni ìkórìíra, ìbànújẹ́ àti àláìsàn pẹ̀lú. Ohun tí ó dára jù fún wa láti ṣe ni kí a fi ohun gbogbo lè Ọlọ́run lọ́wọ́ kí a sì fi I ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ìdánwò náà.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Joy for the Journey: Finding Hope in the Midst of Trial

A lè má rí i tàbí ní í l'érò ní ìgbà gbogbo, ṣùgbọ́n Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa ní ìgbà gbogbo... kódà ní ìgbà tí a bá ń la àwọn ìṣòro kọjá. Nínú ètò yìí, Amy LaRue Olùdarí Finding Hope ṣe àkọsílẹ̀ àtọkànwá nípa ìjàkadì ìdílé rẹ̀ pẹ̀lú ìwà bárakú àti bí ayọ̀ Ọlọ́run ṣe jẹyọ ní àwọn àkókò tí ó nira jùlọ.

More

A fẹ́ dúpẹ́ l'ọ́wọ́ Ilé-iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Hope Is Alive fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: https://www.hopeisalive.net