Ayọ̀ fún Ìrìnàjò náà: Wíwá Ìrètí ní Àárín ÌdánwòÀpẹrẹ

Joy for the Journey: Finding Hope in the Midst of Trial

Ọjọ́ 5 nínú 7

Ìwé Jákọ́bù sọ fún wa wípé kí a kà á sí ayọ̀ gidi ní ìgbà tí a bá bọ́ sí inú ìdánwò. Ṣùgbọ́n kíni ayọ̀? Báwo ni a sì ṣe leè rí ì nínú àwọn ìdánwò náà?

Láìpẹ́ yìí, mo lo bí i ìwọ̀n oṣù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ láti kà àti láti ṣe ìwádìí nípa ayọ̀, lẹ́yìn gbogbo ìwádìí náà, mo rí ìtumọ̀ tí ó rọrùn yìí:

A máa ń ní ayọ̀ ní ìgbà tí a bá fi ÌRÈTÍ wa sí inú Jésù tí a sì ní ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀.

Ayọ̀ máa ń wá láti inú níní ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run, ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ètò Ọlọ́run fún ìdánwò náà, àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run ní ìrìnàjò náà. Kì í ṣe pé kí á kàn gbẹ́kẹ̀ lé E nìkan, ṣùgbọ́n kí á gbà Á gbọ́, kí á sì ní ìgbàgbọ́ pé Ó mọ gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, Ó sì ń mú wa la ìrìnàjò náà kọjá fún ète àti ògo rẹ̀.

Ǹjẹ́ o fi ọkàn tán Ọlọ́run nínú ìdánwò rẹ? Ṣé o ní ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀? Jẹ́ olóòótọ́ sí ara rẹ.

Ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, mo máa ń bá ọ̀pọ̀ ènìyàn tí wọ́n ń d'ojú kọ ìdánwò níní ìfẹ̀ẹ́ ẹni tí ó ní ìwà bárakú sọ̀rọ̀. Gbogbo wa ni a máa ń bẹ̀rù ohun kannáà nípa àwọn ènìyàn wa: ìlò àlòjù. Mo gbàgbọ́ pé èyí wà ní ara ìdí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyá, bàbá, àti ọkọ tàbí aya fi gbàgbọ́ pé ìjà tí ẹni tí wọ́n fẹ́ràn ń jà jẹ́ ìjà tí àwọn alára ní láti jà. A ń bẹ̀rù pé wọ́n lè di alárìnkiri kí wọ́n sì kú sí ojú pópó!

Òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé, ó ṣeé ṣe kí ẹni tí ó ti sọ oògùn líle di bárakú bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀, kí ó di èrò ilé ìwòsàn tàbí kí ó kú. Ṣùgbọ́n bí ó bá tilẹ̀ ṣẹlẹ̀ wípé wọ́n lo oògùn àlòjù, a gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ nínú ètò Ọlọ́run. A gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀lé E. Nítorí pé nínú ìgbẹ́kẹ̀lé náà ni ayọ̀ wà.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Joy for the Journey: Finding Hope in the Midst of Trial

A lè má rí i tàbí ní í l'érò ní ìgbà gbogbo, ṣùgbọ́n Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa ní ìgbà gbogbo... kódà ní ìgbà tí a bá ń la àwọn ìṣòro kọjá. Nínú ètò yìí, Amy LaRue Olùdarí Finding Hope ṣe àkọsílẹ̀ àtọkànwá nípa ìjàkadì ìdílé rẹ̀ pẹ̀lú ìwà bárakú àti bí ayọ̀ Ọlọ́run ṣe jẹyọ ní àwọn àkókò tí ó nira jùlọ.

More

A fẹ́ dúpẹ́ l'ọ́wọ́ Ilé-iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Hope Is Alive fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: https://www.hopeisalive.net