Ayọ̀ fún Ìrìnàjò náà: Wíwá Ìrètí ní Àárín ÌdánwòÀpẹrẹ

Ní ọdún 2015, mo wà nínú ìpòrúúru ọkàn àti ìbẹ̀rù nípa ohun tí ọjọ́ iwájú yíó jẹ́ fún ìdílé mi. Mi ò mọ ohunkóhun nípa ìwa bárakú tàbí bóyá ọ̀mùtí paraku ni ọkọ mi. Ohun ti mo ṣáà mọ̀ ni wípé ayé t'ojú sú mí, mo sì gbàgbọ́ nítòòtọ́ wípé ìdààmú yìí ni màá máa bá yí ní gbogbo ọjọ́ ayé mi.
Ọlọ́run ti mú mi la ìrìnàjò ayọ̀ kọjá nípa ìgbẹ́kèlé nínú Rẹ̀, àti gbígbà Á láàyè láti jẹ́ atọ́nà mi lójoojúmọ́. Lónìí, mo ní ìdùnnú, ìrètí, okun àti ayọ̀.
Àwọn kan nínú yín lè máa ròó pé, Báwo ni mo ṣe lè ní ayọ̀ ní ìgbà tí ọkọ mi ń mu ọtí para ní gbogbo ọjọ́? Báwo ni mo ṣe lè ní ayọ̀ ní ìgbà tí ọmọ mi obìnrin wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n? Báwo ni mo ṣe lè ní ayọ̀ ní ìgbà tí ọmọ mi ọkùnrín di ààrè àti alárìnkiri?
Bóyá ìrìnàjò tí o wà yìí dàbí èyí tí ọ̀nà rẹ̀ kò tọ́, o sì ń wòó pé, Ọlọ́run, níbo ni ojú rẹ wà? Kíni ìdí tí a fi wà nínú ìrìnàjò yìí? Báwo ni mo ṣe lè ní ayọ̀ kankan lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí? Ó sú mí bí mo ti ń da aṣọ bo gbogbo rẹ mọ́'ra bí ẹnipé gbogbo ǹǹkan ń lọ déédéé.
Mo ti kọ́ láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn wá wípé Ọlọ́run wà ní ibí, nínú ìrìnàjò yìí—Ó ń bá wa rìn papọ̀ ní ẹ̀gbẹ̀ẹ́ wa gan gan—àti wípé a ṣì lè rí ayọ̀ ní ìgbà tí a bá fi ÌRÈTÍ wa sínú Jésù, tí a sì ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.
Orúkọ mì ni Amy LaRue. Ní àwọn ọjọ́ méèló kan tí ó ń bọ̀, màá sọ díẹ̀ nípa ìtàn mi àti bí mo ṣe rí ìrètí tí ó ní agbára tí mo ní nínú Jésù. Mo ní ìrètí pé ìwọ yíó rí ìrètí nínú ìtàn mi, ìwọ yíó sì rí i pé ìwọ náà lè ní ayọ̀ nínú ìrìnàjò náà.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

A lè má rí i tàbí ní í l'érò ní ìgbà gbogbo, ṣùgbọ́n Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa ní ìgbà gbogbo... kódà ní ìgbà tí a bá ń la àwọn ìṣòro kọjá. Nínú ètò yìí, Amy LaRue Olùdarí Finding Hope ṣe àkọsílẹ̀ àtọkànwá nípa ìjàkadì ìdílé rẹ̀ pẹ̀lú ìwà bárakú àti bí ayọ̀ Ọlọ́run ṣe jẹyọ ní àwọn àkókò tí ó nira jùlọ.
More