Ọkùnrin Orí Àgbélébùú Àárín: Ètò Bíbélì Ọlọ́jọ́ Méje Tí ÀjíndeÀpẹrẹ

ÌLÉRÍ PÁRÁDÍSÈ
“Ó sì wí pé, “Jesu, rántí mi nígbà tí ìwọ bá dé ìjọba rẹ.”Jesu sì wí fún un pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Lónìí ni ìwọ ó wà pẹ̀lú mi ní Párádísè!’” LUKU 23:42-43 (YCB)
A kan Jésù mọ́ àgbélébùú ní àárin àwọn ọ̀daràn méjì tí wọ́n dá ní ẹ̀bi—àwọn ọ̀daràn náà sì gbọ́ ọ̀rọ̀ Kristi, síbẹ̀ ìdáhùn wọn yàtọ̀ sí ara wọn. Ẹni àkọ́kọ́ tí ó ń kú náà ka àgbélébùú sí ohun tí ó tako ara rẹ̀. Ó gbàgbọ́ wí pé nítorí Jésù wà ní orí àgbélébùú, Jésù kì í ṣe Olùgbàlà. Nítorí náà, ó fi ọkùnrin tí ó wà ní àárín àgbélébùú náà ṣe yẹ̀yẹ́: “Àti ọ̀kan nínú àwọn arúfin tí a gbé kọ́ ń fi ṣe ẹlẹ́yà wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Kristi, gba ara rẹ àti àwa náà là.” (Luku 23:39). Ṣùgbọ́n ọkùnrin kejì rí àgbélébùú náà gẹ́gẹ́ bíi ìmúṣẹ. Ó mọ̀ pé nítorí pé Jésù wà ní orí àgbélébùú, òun ni Olùgbàlà.
Ọ̀daràn tí ó jẹ́ òǹrorò tẹ́lẹ̀ rí yìí ti rí Jésù ó sì ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ìkẹyìn rẹ̀ láti mọ̀ pé Jésù kò jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ kankan. Ẹ̀mí Mímọ́ sì ti la ojú rẹ̀ l'áti mọ̀ pé ìṣòro rẹ̀ pọ̀ ju bí ó ṣe rò tẹ́lẹ̀. Kì í ṣe pé wọ́n ń fì ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jẹ ẹ́ ní ọ̀nà tí ó tọ́ nìkan, àmọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ á máa bá a lọ títí ayérayé bí kò bá rí ìdáríjì gbà, èyí tí Jésù sọ nípa rẹ̀.
Lẹ́yìn tí ọkùnrin tí wọ́n dájọ́ ikú fún yìí ti rí i pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí, ó bẹ Jésù tìrẹ̀lẹ̀ tìrẹ̀lẹ̀ fún ohun tí ó mọ̀ wí pé kò tọ́ sí òun: “Jesu, rántí mi ní ìgbà tí ìwọ bá dé ìjọba rẹ.” Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ó ti ṣe àyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí náà, tí ó sì ti parí èrò sí pé, Bí ọkùnrin yìí bá jẹ́ mèsáyà, á jẹ́ ọba tí a ti ṣe ìlérí tipẹ́tipẹ́. Bí ó bá jẹ́ pé Òun ni Ọba náà, ní ìgbà náà yóò ní ìjọba kan—ìjọba ayérayé ti Ọlọ́run. Ní ìgbà tí Ó bá sì dé ìjọba Rẹ̀, bóyá ó lè rántí mi.
Ìdáhùn Jésù jẹ́ ìyanu: “Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, lónìí ni ìwọ ó wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.” Kì í ṣe pé Jésù ṣe ìlérí pé ọkùnrin yìí—àní ọkùnrin yìí— yóò lọ sí ọ̀run nìkan, ṣùgbọ́n Ó tún t'ẹnu mọ́ bí ó ṣe tètè wáyé tó: “lónìí”! A lè fi ọkàn ya àwòrán wọn bí wọ́n ti n parí ìjíròrò wọn, kìí ṣe ní orí àgbélébùú ní Kálífárì, ṣùgbọ́n ní ìjókòó ní ìjọba Ọlọ́run.
Ọ̀daràn yìí kò fún Ọba ní nǹkankan, ó sì béèrè fún ohun gbogbo. Ó sì gbà. Kò yẹ kí èyí máà kọ wá ní ominú, kí ó sì fi wá ní ọkàn balẹ̀, nítorí pé ipò tí ọ̀daràn yẹn wà ni àwa náà wà. Kò sí ohun tí a lè mú wá fún Jésù, bí ẹni pé àwọn ohun tí a ṣe lè jẹ́ kọ́kọ́rọ́ tí ó máa jẹ́ kí á wọ ìjọba Rẹ̀. Gbogbo ohun tí a mú wá ni ohun tí ọ̀daràn náà mú wá: ẹ̀ṣẹ̀ wa. ṣùgbọ́n ìdí nìyí tí a fi kan Jésù mọ́ àgbélébùú: kí àwa lè mú ẹ̀ṣẹ̀ wa tọ̀ Ọ́ wá kí Òun lè gbé e, kí Ó sì rù ú. Ìdí nìyẹn tí ìlérí tí Jésù ṣe fún ọ̀daràn náà fi jẹ́ ìlérí Rẹ̀ fún gbogbo onígbàgbọ́ tí ó bá kú: "Lónìí ni ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.” Jẹ́ kí ìmọ̀ yẹn jẹ́ ayọ̀ rẹ àti ohun tí ó ń fún ọ ní okun láti máa yin Ọlọ́run ní ònì yìí. Ní ọjọ́ kan, ìwọ pàápàá yóò wà pẹ̀lú Ọba rẹ ní Párádísè.
- Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń pè mí láti ronú ní ọ̀nà mìíràn?
- Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń tún ọkàn mi ṣe—ohun tí mo fẹ́ràn?
- Kí ni Ọlọ́run ń pè mí láti ṣe bí mo ṣe ń ṣe iṣẹ́ ọjọ́ mi ní òní yìí?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ènìyàn ni ó gbà pé ayé yìí ti di ìdíbàjẹ́. Àmọ́ tí ọ̀nà àbáyọ bá wà nkọ́? Ètò àjínde ọlọ́jọ́ méje yìí bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìrírí àrà ọ̀tọ̀ tí olè orí àgbélébùú, ó sì ṣe àgbéyẹ̀wò ìdí tí ìdáhùn tòótọ́ kan ṣoṣo sí ìdíbàjẹ́ fi wà ní inú pípa ọkùnrin aláìsẹ̀ kan: ìyẹn Jésù, Ọmọ Ọlọ́run.
More