Ọkùnrin Orí Àgbélébùú Àárín: Ètò Bíbélì Ọlọ́jọ́ Méje Tí ÀjíndeÀpẹrẹ

ÀGBÉLÈBÚ LA OJÚ WA
“Nígbàtí balógun ọ̀gọ́rún náà rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó yin Ọlọ́run lógo, ó ní, ‘Nítòótọ́ ọkùnrin yìí jẹ́ aláìlẹ́bi!!’” LÚÙKÙ 23:47 (ESV)
A kò lóyé àgbélèbú àyàfi tí o ba tí yí àwa tìkalárawa padà.
Lẹ́yìn tí Jésù “mí èmí ìgbẹ̀yìn rẹ̀” (Luku 23:46), Luku ṣàkọsílẹ̀ ìṣesí àwọn tí wọ́n rí kíkàn mọ́ àgbélèbú fún wa. “Gbogbo ogúnlọ́gọ̀ tí wọ́n péjọ fún àwòkẹ́kọ̀ọ́ yìí, nígbà tí wọ́n rí ohun tó ṣẹlẹ̀, wọ́n padà sílé, wọ́n fí ọwọ́ ńlu ayàá wọn.” (v 48). Bẹ́ẹ̀ni, wọ́n banújẹ́, ṣùgbọ́n ní kété tí ìwòrán náà parí, wọ́n tẹ̀síwájú ìgbésí ayé wọn. Ẹsẹ 49 lẹhinná sọ fún wá wípe “gbogbo àwọn ojulùmọ rẹ… tá kété sí òkèèrè n' wo ìran,” a kàn le fi ojú inú wo ohún ti ó ńlọ nínú ọkàn wọn. Ṣùgbọ́n ìhùwàpadà tí ó gbámúṣé jù lọ tí Lúùkù fihàn ni ti balógun ọ̀gọ́rún ará Róòmù náà, ẹni tó rí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó “yìn Ọlọ́run, ó sì wí pé, ‘Dájúdájú, ọkùnrin yìí jẹ́ aláìlẹ́bi! — tàbí, bí NIV ṣe àkọsílẹ rẹ, “Dájúdájú, olódodo ènìyàn ni èyí!”
Níhìn, láàárín òkùnkùn àwọn asíwájú ẹ̀sìn alágàbàgebè, àwọn alákóso oníyemeji, àti àwọn arìnrìn-àjò aláiláànu tí ń kọjá lọ, ìtànsán ìmọ́lẹ̀ yọ. Ẹni tí a óò retí láti rí òtítọ́—ọkùnrin kan tí kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú Jésù tẹ́lẹ̀, kò sí ìpìlẹ̀ nínú àwọn ẹ̀kọ́ Májẹ̀mú Láéláé, tí kò sì ní ìtẹ̀sí sí àwọn ohún ti Ọlọ́run—kò nìkàn ní oyé ohun ti o ṣẹlẹ̀ ṣugbọn o tikalarẹ f'èsì tí ó yẹ. Ó rí “ohun tí ó ṣẹlẹ̀”—ọ̀rọ̀ Jésù, òkùnkùn biribiri, ípásẹ̀ ikú Rẹ̀—ó sì mọ̀ wípé, Eléyìí kìí ṣe ènìyàn lásán. Arákùnrin kàn tí ó yàtọ sí ẹnikẹ́ni ni. Èyí ní arákùnrin kàn tí o jẹ alaiṣẹ̀ pátápátá, olódodo loju méjèèjì. Máàkù pàápàá, fi kún un pé balógun ọ̀gọ́rún náà jẹ́wọ́ wípé “Ọmọ Ọlọ́run” ni ọkùnrin tó wà lórí àgbélébùú náà ńṣe. (Máàkù 15:39).
Pẹ̀lú ojú fún àlàyé rẹ̀, Lúùkù t'ẹnu mọ́ rírí ohún tíó ṣẹlẹ̀ lórí àgbélébú. Ohun tí kò bá jẹ́ ìrètí rẹ̀ ni wípé àwọn tí wọ́n k'ẹ̀kọ́ yóò rántí wípé nígbàtí Jésù ka ìwé Aísáyà ṣáájú ní àkókò iṣẹ́ ìsìn Rẹ̀, Ó ti sọ wípé, “Ẹ̀mí Olúwa . . . ti fi àmì òróró yàn mí láti kéde ìhìnrere fún àwọn òtòṣì… láti kéde òmìnira fún àwọn òǹdè àti ìríran àwọn afọ́jú” (Luku 4:18). Ní tòótọ́, kókó pàtàkì kán tí a rí jákèjádò Ìhìnrere Lúùkù ní bí ìmọ́lẹ̀ kọlu òkùnkùn — agbára ìdáǹdè òtítọ́ Ọlọ́run ṣe ngbógun tì ìdàrúdàpọ̀ àti ọkàn líle òun èrò inú àwọn ènìyàn.
Ìgbìyànjú èyíkéyìí láti sọ àsọye ẹsìn ọmọlẹyìn Krísti ṣùgbọ́n tí ó kẹ̀hìnsi pàtàkì àgbélèbú gẹ́gẹ́bí àárín gbòngbò rẹ̀, ko lé já si ìgbàgbọ tí ó ngbàlà. Ní pẹlú bí o tilẹ̀ jẹ wípé a ko fí ìgbàgbogbo lóyé bi Ẹmi ṣe ń daríi ọkùnrin àti obìnrin láti di àtúnbi, síbẹ̀ iṣẹ-ìranṣẹ wa gbọ́dọ̀ jẹ́ ikanná nígbàgbogbo: “Kristi ti a kàn mọ agbelebu” (1 Kor 1:23). Wíwo àgbélébú ní ńmú ìyè wá fún ẹnikẹ́ni tí ó bá dáhùn sí ọkùnrin tí ó so kọ́ síbẹ̀ nípa jíjẹ́wọ́ ẹni tí Ò jẹ́ àti yíyin Ọlọ́run fún iṣẹ́ ìgbàlà Rẹ̀. Àyàfi, àti, ó di'gbà tí àgbélèbú bá jẹ ohun tí a gbàmọ́ra, kò lé wúlò fún wa. Nígbà wo ni o ṣàdédé kàn wo Olùgbàlà rẹ lórí àgbélèbú kẹhìn, ti o si fí íyin fún Ọlọ́run?
- Báwo ní Ọlọ́run ṣe ńpe mí láti ronú yàtọ?
- Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń ṣe atúnto àwọn ohun àfẹ́rí ọkàn mi—ohun tí mo nífẹ̀ẹ́?
- Kí ni Ọlọ́run ń pè mí láti ṣe bí mo ṣe ń lọ l'ọjọ́ óní?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ènìyàn ni ó gbà pé ayé yìí ti di ìdíbàjẹ́. Àmọ́ tí ọ̀nà àbáyọ bá wà nkọ́? Ètò àjínde ọlọ́jọ́ méje yìí bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìrírí àrà ọ̀tọ̀ tí olè orí àgbélébùú, ó sì ṣe àgbéyẹ̀wò ìdí tí ìdáhùn tòótọ́ kan ṣoṣo sí ìdíbàjẹ́ fi wà ní inú pípa ọkùnrin aláìsẹ̀ kan: ìyẹn Jésù, Ọmọ Ọlọ́run.
More