Ọkùnrin Orí Àgbélébùú Àárín: Ètò Bíbélì Ọlọ́jọ́ Méje Tí ÀjíndeÀpẹrẹ

A TI YI OKUTA KURO
“Eéṣe ti ẹ̀yin fí nwa aláàye láàrin àwọn okú? Kò si níhin, ṣùgbọ́n ó ti jínde.” LÚÙKÙ 24:5-6
Nígbà tí a bá wo Jésù gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà, ọ̀pọ̀ lára wa máa ń kọkọ ronú lójú ẹsẹ̀ nípa tí ara wa: Jésù jẹ́ Mèsáyà mí. O dari ẹṣẹ mí ji mi. Òun gbé inú mí. Gbogbo èyí náà ló jẹ́ òtítọ. Ṣùgbọ́n ìfojúsọ́nà àwọn Júù ìṣáájú nípa jíjẹ́ mesáyà ti Jésù gbòòrò ju ìyẹn lọ. Tí a bá bi ọ̀kan nínú àwọn Júù ìṣáájú sọ̀rọ̀ nípa kilojẹ́ àwọn ìfojúsọ́nà Mèsáyà rẹ̀, lọ́nà kan, a ò bá ṣàwárí àwọn ìrètí tí ó tóbi lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.
Àwọn Júù fojú sọ́nà pé Mèsáyà tí wọ́n ti ń retí tipẹ́tipẹ́ ni yóò wá ṣẹ́gun àwọn kèfèrí tí wọ́n ti ń ṣàkóso lé wọn lórí, yóò tún tẹ́mpìlì kọ́, yóò sì fì ìdí ìṣàkóso òdodo Ọlọ́run múlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Ìrèti wọn jẹ́ ti ẹni tí ó nífẹ orílẹ̀-èdè wọn wípé Mèsáyà yóò wá láti dá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì láre. Dídé Jésù, pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Ó ṣe, àwọn ìtàn tí Ó sọ, àti àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Ó nmúṣẹ, mú kí ìfojúsọ́nà láàárín àwọn ọmọlẹ́yìn Rẹ̀ tunbo kún sí. Ṣùgbọ́n lọ́gán tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní èrò pé òun ni yóò jẹ́ olùràpadà ìṣèlú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ni wọ́n rí gbogbo ìrètí Mèsáyà wọn yìí lórí igi ẹ̀sín àwọn ará Róòmù ní Kalfari. Ati nigbati Jesu kigbe pe, "O ti pari" (Jòhánù 19:30), ọ̀pọlọ́pọ nínú wọn ní yóò ti gbà bẹ́ẹ.
Báwo, nígbà náà, ni àwùjọ àwọn onígbàgbọ́ yìí, tí a ti sin ìrètí Mèsáyà wọn sí inú ibojì àwọn ará Palestine, wọn ò kàn tẹra mọ́ ìgbàgbọ wípé Jésù ni Mèsáyà náà nìkan, ṣùgbọ́n wọ́n dúró ní àwọn òpópónà nítòsí ibi tí wọ́n ti pa á, tí wọ́n sì nṣe ìkéde àìnítìjú nípa jíjẹ́ Mèsáyà Rẹ̀? Idahun ti a rí tí ó mi ilẹ̀ tìtì ninu wọn oju-iwe Majẹmu Titun ni a ri nínú àjíǹde nínú ara ti Jésù. Ìkéde áńgẹ́lì sí àwọn arábìnrin tí wọ́n mú èròjà atasánsán wá láti fi ṣe ìsìnkú ní o mú kí wọ́n ṣ'àtúnyẹ̀wò ìjìnlẹ̀ nípa ohun tí àwọn tí ó gbàgbọ́ ti rí ní ọjọ́ Ẹtì àti ìyípadà tó pé nínú ojú tí wọ́n fi ń wo ìgbésí ayé wọn àti ọjọ́ ọ̀la wọn. Nígbà tí Mèsáyà tún fara hàn láàárín wọn, gẹ́gẹ́ bí ti ìwàláàyè Rẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n wà ninu ìbànújẹ́, ìsoríkọ́, ìrẹ̀wẹ̀sì, àti ìrora ọkàn wá di ẹlẹ́rìí onígboyà àti aláyọ̀. Wọ́n wá jẹ́rìí sí òtítọ́ tí Krísti tí a jí dìde pẹ̀lú ara tí a lè rí, tí a fọwọ́ mú, tí a sì fọwọ́ kàn, tí ó sì ní agbára láti ṣe ohun tí ara rẹ̀ ṣáájú àjíǹde kò leè ṣe. Iṣẹ ìgbàlà Rẹ ti pari; Ìgbésí ayé Rẹ̀ àti ìjọba Rẹ̀ jìnà sí ìparí!
Nípasẹ̀ ìmòye awọn ọmọ-ẹ̀hìn níti àjínde ará tí Kristi, ní o pápa wa fí ìtumọ̀ sí wipe Krísti ni Mèsáya. Ní tòótọ́, ohun tí ó hàn gbangba sí àwọn Júù onígbàgbọ́ akọkọ́ nígbà tí wọ́n “rí òkúta tí a ti yí kúrò ní ibojì náà” (Lúùkù 24:2) tí wọ́n sì rí i pé “Jésù tìkára rẹ̀ dúró láàárín wọn” (v36) ni wípé ìrètí ayérayé, ayọ̀, àti agbára ti tàn sínú oókan-àyà wọn. Èyí sì ṣì wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún gbogbo àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jésù, Mèsáyà tí a ti jíǹde. Àjínde nì àti àjínde nìkan ní ó ṣe ayípadà ìbànújẹ́, ìsoríkọ́, ìrẹ̀wẹ̀sì, àti ìrora ọkàn si ireti, ayọ, ati agbara. Àjíǹde ni, àti àjíǹde nìkan, ni ó kéde wípé Mèsáyà wa yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá Rẹ̀, yóò mú àwọn ènìyàn Rẹ̀ padàbọ̀sípò, yóò sì ṣàkóso láti òkun dé òkun. Àjíǹde Jésù yóò ṣe ayípadà ohùn gbogbo nipa bi oó ṣe lo ọjọ rẹ loni.
- Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń pe mi láti ronú yàtọ?
- Báwo ni Ọlọ́run ṣe n ṣe àtúnṣe àwọn àfẹ́rí ọkàn mi—ohun tí mo n'ifẹ?
- Kíni Ọlọ́run n pé mi láti ṣe nípa ọjọ́ mi l'oni?
A ṣe àtúnṣe Ètò yìí láti inú orísun miyiran. Kọ́ ẹ̀kọ́ díẹ síi nípa Truth For Life àti Alistair Begg.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ènìyàn ni ó gbà pé ayé yìí ti di ìdíbàjẹ́. Àmọ́ tí ọ̀nà àbáyọ bá wà nkọ́? Ètò àjínde ọlọ́jọ́ méje yìí bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìrírí àrà ọ̀tọ̀ tí olè orí àgbélébùú, ó sì ṣe àgbéyẹ̀wò ìdí tí ìdáhùn tòótọ́ kan ṣoṣo sí ìdíbàjẹ́ fi wà ní inú pípa ọkùnrin aláìsẹ̀ kan: ìyẹn Jésù, Ọmọ Ọlọ́run.
More