Ọkùnrin Orí Àgbélébùú Àárín: Ètò Bíbélì Ọlọ́jọ́ Méje Tí ÀjíndeÀpẹrẹ

The Man on the Middle Cross: A 7-Day Easter Reading Plan

Ọjọ́ 2 nínú 7

ÒKÙNKÙN BIRIBIRI

“Ó sì tó ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́, òkùnkùn sì ṣú bo gbogbo ilẹ̀ títí ó fi di wákàtí kẹsàn-án ọjọ́. Òòrùn sì ṣú òòkùn.” LÚÙKÙ 23:44-45 (YCE)

Lẹ́yìn tí wọ́n kan Jésù mọ́ àgbélébùú, ní nǹkan bíi ọ̀sán gangan, òkùnkùn ṣú bo gbogbo ilẹ̀. Fi ojú inú wo bí ó ṣe máa tì rí! Ní òjijì, àwọn ènìyàn ní ìmọ̀lára àìní agbára. Ó lè jẹ́ pé àwọn ọ̀kan wà ní ibi tí wọ́n ti mú Jésù, tí wọ́n sì rántí pé Ó ti kìlọ̀ pé, “Ṣùgbọ́n àkókò tiyín ni èyí, àti agbára òkùnkùn n jẹ ọba.” (Lúùkù 22:53). Àmọ́ ó ṣeé ṣe kí èyí tí ó pọ̀ jù lọ ní ára bi ara wọn pé, Irú kí ni òkùnkùn yìí jẹ́? Kí ni ìdí tí èyí fi n ṣẹlẹ̀?

Ní ọ̀nà kan, ó yẹ kí wọ́n mọ ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn. Ikú Jésù wáyé ní àkókò àjọyọ̀ Ìrékọjá ní Jerúsálẹ́mù, ìyẹn àjọyọ̀ tí ó máa ń wáyé ní ọdọọdún fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún. Ní àárín àkókò yìí, àwọn Júù á rántí pé ìyọnu ìkẹyìn tí Ọlọ́run rán sí orí Íjíbítì kí áńgẹ́lì ikú tó dé àti ikú àwọn ọmọkùnrin àkọ́bí ni ìyọnu òkùnkùn tí ó bo gbogbo ilẹ̀ náà. Wọ́n á rántí pé lẹ́yìn òkùnkùn biribiri, ikú dé: pé ní àkókò yẹn, kìkì àwọn tí ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ àgùntàn Ìrékọjá dá ààbò bò ni ó jí ní òwúrọ̀ láti rí àkọ́bí wọn pẹ̀lú wọn. Àti nísinsìnyí, níhìn-ín, nínú ìjádelọ tí ó tóbi jù lọ tí ẹni àkọ́kọ́ ṣe àkọ́wò rẹ̀, òkùnkùn tí ó ṣíwájú ikú Kristi, Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ìrékọjá pípé.

Gẹ́gẹ́ bíi ẹni tí ń ru ẹ̀ṣẹ̀—gẹ́gẹ́ bí Ọ̀dọ́ Àgùntàn pípé, tí kò ní àbàwọ́n—ni Jésù wọ ọ̀dọ̀ Ọlọ́run aláìlẹ́ṣẹ̀. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, kò ru ẹbọ àfidípò kankan àfi ara Rẹ̀. Ṣíwájú àkókò yìí nínú ìtàn, láti wọ ibi mímọ́ Ọlọrun nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù, àlùfáà àgbà ní láti rú ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀, kí ó sì rú ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí ó ń ṣe aṣojú fún. Ṣùgbọ́n Olórí Àlùfáà yìí wọ iwájú Ọlọ́run mímọ́, láì gbé ohun kan. Kí ni ìdí? Nítorí pé Òun fúnra Rẹ̀ kò nílò ìrúbọ, nítorí tí Ó jẹ́ pípé, láì ní ẹ̀ṣẹ̀; àmọ́ síbẹ̀síbẹ̀ Òun fúnra Rẹ̀ ni ìrúbọ. Jésù ni Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà. Kò sí ohun míràn tí Ó gbé àti ohun míràn tí Ó yẹ kí Ó gbé. Gẹ́gẹ́ bí Pétérù ṣe ṣe àlàyé, “Ẹni tí òun tìkára rẹ̀ fi ara rẹ̀ ru ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí igi àgbélébùú” (1 Pétérù 2:24).

Ní ìkẹyìn, òkùnkùn ti ìdájọ́ Ọlọ́run kọ́ ni ó jọ'ba. Nítorí pé Jésù ti di ẹ̀ṣẹ̀, tí Ó ru ìbínú kíkún Ọlọ́run, a lè fi wa sínú ìjọba Ọlọ́run, “sínú ìmọ́lẹ̀ ìyanu rẹ̀” (1 Pétérù 2:9). Kò sí ohun míràn ní gbogbo àgbáyé tí o ṣe àfihàn bí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe jẹ́ òtítọ́ fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ àti bí ẹ̀ṣẹ̀ wà ṣe hàn kedere sí Ọlọ́run.

Ó tó kí òòrùn s‘òkùnkùn
Kí ó fi ògo rẹ̀ pa mọ́
Ní ìgbà tí Kristi Ẹlẹdàá nlá kú
Fún ẹ̀ṣẹ̀ àwa ẹ̀dá.[1]
  • Báwo ní Ọlọ́run ṣe ń pè mí láti ronú yàtọ̀?
  • Báwo ní Ọlọ́run ṣe ń yí àwọn ìfẹ́ ọkàn mi padà—àwon ohun tí mo fẹ́ràn?
  • Kí ni Ọlọ́run ń pè mí láti ṣe bí mo ṣe ń ṣe iṣẹ́ òòjọ́ mi ní òní?

[1] Isaac Watts, “Ó ṣe! Olùgbàlà mi ta ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀ sílẹ̀” (1707).

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

The Man on the Middle Cross: A 7-Day Easter Reading Plan

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ènìyàn ni ó gbà pé ayé yìí ti di ìdíbàjẹ́. Àmọ́ tí ọ̀nà àbáyọ bá wà nkọ́? Ètò àjínde ọlọ́jọ́ méje yìí bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìrírí àrà ọ̀tọ̀ tí olè orí àgbélébùú, ó sì ṣe àgbéyẹ̀wò ìdí tí ìdáhùn tòótọ́ kan ṣoṣo sí ìdíbàjẹ́ fi wà ní inú pípa ọkùnrin aláìsẹ̀ kan: ìyẹn Jésù, Ọmọ Ọlọ́run.

More

A mú ìfọkànsìn láti inú ‘Truth For Life,’ ìwé ìfọkànsìn ojoojúmọ́ tí Alistair Begg kọ, tí The Good Book Company sì tẹ̀ jáde, thegoodbook.com. Truth For Life lò ó pẹ̀lú àṣẹ. Àṣẹ-Olóhun (C) 2022, The Good Book Company. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://tfl.org/365