Ọkùnrin Orí Àgbélébùú Àárín: Ètò Bíbélì Ọlọ́jọ́ Méje Tí ÀjíndeÀpẹrẹ

The Man on the Middle Cross: A 7-Day Easter Reading Plan

Ọjọ́ 4 nínú 7

Ó MÍ ÈÉMÍ ÌKẸYÌN

“Jésù sì kígbe si ní ohùn rara, Ó ní, Baba, ní ọwọ́ Rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé! Nígbàtí Ó sì wí èyí tan, o jọ̀wọ́ ẹ̀mí Rẹ̀ lọ́wọ́.” LÚKÙ 23:46 (YBCV)

Òkodoro àwọn ọ̀rọ̀ yìí tọ́ka wa sí àwọn òtítọ́ tí ó jinlẹ̀.

Lúkù, pẹ̀lú àkíyèsí tí ó ṣe, fún wa ní “àlàyé lẹ́sẹẹsẹ” nípa ikú Jésù— àlàyé tí ó jẹ́ wípé, ó yànàná ní ìbẹ̀rẹ̀ ìhìnrere rẹ pé, ó wá látàrí ìtọpinpin fínnífínní kí àwọn òǹkàwé òun “lè ní ìdánilójú ohun tí wọ́n tí kọ́” (Lúkù 1:3-4). Kò wá láti jẹ́ kí á káànú fún àwọn ohun tí ó kọ. Dípò èyí, ó kọ wọ́n kí á baà lè ní òye òtítọ́. Nítorínáà a kọ àkọsílẹ̀ èémí ikú Jésù fún wa báyìí pé: “Ó mí èémí ìkẹyìn.”

Ohun tí Lúkù fẹ́ kí a ronú lé ní orí ni pè Jésù ní agbára lórí èémí ìkẹyìn Rẹ̀. Ó yàn láti fi ẹ̀mí Rẹ̀ lé ọwọ́ ìfẹ́ Baba Rẹ̀. Ó mọ̀ pé iṣẹ́ Òun ti parí. A ti san ìdíyelé fún ẹ̀ṣẹ̀, aṣọ ìkélé ti fàya, àwọn ènìyàn Rẹ̀ sì ti lè wá sí iwájú Baba títí láí. Ní àfikún ohun gbogbo tí Jésú sọ ṣáájú ikú Rẹ̀, ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Rẹ̀ tako èrò pé ikú Rẹ̀ jẹ́ ti aláìgbára ènìyàn kan ṣáá tí ipò búburú tí ó wà borí ẹ̀mí rẹ̀. Ó ti sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀ ní bíi oṣù mèlòó kan sẹ́yìn pé Òun ń lọ sí Jerúsálẹ́mù àti pé “Ọmọ-ènìyàn ní láti jìyà ohun púpọ̀ kí á sì … pa Á” (Lúkù 9:22). Jòhánù sọ fún wa pé Ó ti ṣe àlàyé fún wọn, “Mo fi ẹ̀mí mi lélẹ̀, kí Èmi kí ó lè tún gbà á. Ẹnìkan kò gbà á lọ́wọ́ mi, ṣùgbọ́n mo fi í lélẹ̀ fún ara mi. Mo ní agbára láti fi í lélẹ̀, mo sì ní agbára láti tún gbà á.” (Jòhánù 10:17-18).

Jésù lọ sí orí àgbélébù kìí ṣe bíi aláìlágbára ṣùgbọ́n fúnraraarẹ̀. Ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Baba, Ó yàn àkókò náà gan-an tí yíó fí ẹ̀mí Rẹ̀ lélẹ̀ fún àwọn àgùntàn Rẹ̀ (Jòhánù 10:11). Ní ibí bayìí, a rí Olùpilẹ̀ṣẹ̀ ìyè, tí ó finúfíndọ̀ mí èémí ìkẹyìn rẹ̀ tí ó sì ń ràn wá ní etí àṣẹ amúbíiná Rẹ̀ àti ìfẹ́ àìlópin Rẹ̀. “Ó mí èémí ìkẹyìn” kí ìwọ ba à lè mí èémí tuntun tí a wẹ̀ mọ́, tí a ṣe ètò rẹ̀ fún ọ ní kété tí o dí àtúnbí. “Ó mí èémí ìkẹyìn” kí ó lè jẹ́ pé ní ọjọ́ kan ìwọ yíó dúró ní ẹ̀dà tuntun tí a ràpadà, ìwọ yíó sì mí èémi sí inú ẹ̀dọ̀fóró tí kò ní díbàjẹ́ láí. Aláṣẹ ní orí èémí tí ò ń mí fí t'àṣétàṣẹ mí èémí ìkẹyìn Rẹ̀. Kò sí ohun mìráàn tí ó yẹ fún Un ju ìyìn àti ìjúbà rẹ lọ.

  • Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń pè mí láti ronú ni ọ̀nà ọ̀tun?
  • Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń tún àwọn ìfẹ́ ọkàn—àwọn ohun tí mo fẹ́ tò?
  • Kíni Ọlọ́run ń pè mí láti ṣe bí mo ṣe ń lọ nínú ọjọ́ mí lónìí?

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

The Man on the Middle Cross: A 7-Day Easter Reading Plan

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ènìyàn ni ó gbà pé ayé yìí ti di ìdíbàjẹ́. Àmọ́ tí ọ̀nà àbáyọ bá wà nkọ́? Ètò àjínde ọlọ́jọ́ méje yìí bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìrírí àrà ọ̀tọ̀ tí olè orí àgbélébùú, ó sì ṣe àgbéyẹ̀wò ìdí tí ìdáhùn tòótọ́ kan ṣoṣo sí ìdíbàjẹ́ fi wà ní inú pípa ọkùnrin aláìsẹ̀ kan: ìyẹn Jésù, Ọmọ Ọlọ́run.

More

A mú ìfọkànsìn láti inú ‘Truth For Life,’ ìwé ìfọkànsìn ojoojúmọ́ tí Alistair Begg kọ, tí The Good Book Company sì tẹ̀ jáde, thegoodbook.com. Truth For Life lò ó pẹ̀lú àṣẹ. Àṣẹ-Olóhun (C) 2022, The Good Book Company. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://tfl.org/365