Ọkùnrin Orí Àgbélébùú Àárín: Ètò Bíbélì Ọlọ́jọ́ Méje Tí ÀjíndeÀpẹrẹ

The Man on the Middle Cross: A 7-Day Easter Reading Plan

Ọjọ́ 3 nínú 7

Ìbàjẹ́ àtọ̀runwá

“Ó sì tó ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́, òkùnkùn sì ṣú bo gbogbo ilẹ̀ títí ó fi di wákàtí kẹsàn ọjọ́. Òòrùn sì ṣú òòkùn, aṣọ ìkélé ti tẹmpili sì ya ní àárín méjì"Lúùkù 23:44-45(ESV)

Bí iṣẹ́ ìránṣẹ́ Jésù ṣe ń tẹ́ síwájú, ọ̀kan lára ​àfiyèsí ńlá tí ìgbékalẹ̀ ètò ẹ̀sìn àwọn Júù ni pé, ó dàbí ẹni pe, Ó sọ pé Òun yóò wó tẹ́mpìlì palẹ̀, yóò sì tún un kọ́ ní ọjọ́ mẹ́ta (Jòhánù 2:19).Ní tòótọ́, èyí jẹ́ ọ̀kan lára ​​àwọn ẹ̀sùn pàtàkì tí wọ́n fi kàn án (Maku 14:58). Nígbà tí Jésù wà lórí àgbélébùú, nígbà náà, àwọn tí ń kọjá lọ fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì ń kígbe pé,“‭ “Ìwọ tí yóo wó Tẹmpili, tí yóo tún un kọ́ ní ọjọ́ mẹta, gba ara rẹ là. Bí Ọmọ Ọlọrun bá ni ọ́, sọ̀kalẹ̀ kúrò lórí agbelebu.”(Mátíù 27:40). Ṣùgbọ́n níbè ló wà, ní orí igi àgbélébùú, nínú òkùnkùn.

Àti pé nígbà náà, ní àárín òkùnkùn àti ìdàrúdàpọ̀ tí ó rọ̀ mọ́ àgbélébùú, lójijì, ohun àràmàǹdà àti àìròtẹ́lẹ̀ kan ṣẹlẹ̀: Ọlọ́run tìkálára rẹ̀ bá tẹ́mpìlì jẹ́.

“Aṣọ ìkélé tẹmpìlì náà sì ya sí méjì, ". Lúùkù sọ fún wa bẹ́ẹ̀. Èyí gan-an ni aṣọ ìkélé tí wọ́n sokọ́ sínú tẹmpìlì láti fi ṣe àpẹẹrẹ dídí ọ̀nà tó lọ sí iwájú Ọlọ́run. Ó jẹ́ àmì ńlá pé àwọn ènìyàn aláìpé kò le wá ní ààyè kan náà pẹ̀lú Ọlọ́run mímọ́. Jákèjádò Májẹ̀mú láéláé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe tán láti wá sí iwájú Ọlọ́run láì ṣe àkíyèsí àwọn ìlànà ìwẹ̀nùmọ́ àti ṣíṣe ayẹyẹ àwọn ìrúbọ tí ó jẹ́ ọ̀rànyàn ti kú (fún àpẹẹrẹ, Númérì 3: 2-4). Ṣùgbọ́n ní báyìí, lójijì, bí ẹ̀mí ṣe fẹ́ bọ́ lára Jésù, àmì ìyàsọ́tọ̀ ní a mú kúrò. Nípa ìmúkúrò yí, Ọlọ́run kéde pé àṣà àwọn àlùfáà àtijọ́ fún iwọle sí iwájú Rẹ̀ ti dópin, àti ìdènà ẹ̀ṣẹ̀ tí ń pín àwọn ènìyàn níyà kúrò lọ́dọ̀ Ẹlẹ́dàá wọn ti parẹ́. Kò sí ìdí kankan mọ́ láti jìnnà sí Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, “a ní ìgboyà láti wọ ibi mímọ́ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jésù, nípa ọ̀nà tuntun àti àyè tí ó ṣí sílẹ̀ fún wa nípasẹ̀ aṣọ ìkélé” (Hébérù 10:19-20).

Wíwá sì iwajuní Ọlọ́run kò ní ṣe pẹ̀lú tẹmpìlì tàbí ilé ìjọsìn, tàbí ilé èyíkéyìí, tàbí kó gbọdọ̀ jẹ́ nípàṣẹ àlùfáà tàbí ẹni tí ó kọ ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kan. Rárá, ní ẹgbẹ́wá ọdún sẹ́yìn, Ọlọ́run tún ìtàn ko láti fì ọ̀nà tí ó tọ́ tààrà sí ara rẹ lélẹ̀ nípasẹ̀ Jésù. Báyìí “Nítorí Ọlọ́run kan ní ń bẹ, onílàjà kan pẹ̀lú láàrín Ọlọ́run àti ènìyàn, àní Kristi Jesu ọkùnrin náà, ẹni ti ó fi ara rẹ̀ ṣe ìràpadà fún gbogbo ènìyàn"(1 Timothy 2:5-6). Aṣọ ìkélé tẹmpìlì tí ó ya sí méjì jẹ́ ìbàjẹ́ àtọ̀runwá fún ọ! Ìwọ kò ní láti gbójú lé àwọn àlùfáà àti àwọn ìrúbọ mọ́. Wọ́n kò le jẹ́ ǹkankan bí kò ṣe asán. Kàkà bẹ́ẹ̀, o lè wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí o ti rí, ní ìdánilójú pé ó ṣe tán láti rí wa pẹ̀lú àánú àti ìrànlọ́wọ́, gbogbo rẹ̀ nítorí Jésù.

  • Báwo ni Ọlọ́run ṣé ń pè mí láti ronú lọ́nà tí ó yàtò?
  • Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń ṣe àtúntò ìfẹ́ ọkàn mi —ohun tí mo nifẹ si?
  • Kí ni Ọlọ́run ń pè mí láti ṣe bí mo ṣe ń lọ pẹ̀lú iṣẹ́ òjó mí lónìí?

Ìdibàjẹ́ àtọ̀runwá

“Ó tó ìwọ̀n wákàtí kẹfà báyìí, òkùnkùn sì ṣú bo gbogbo ilẹ̀ títí ó fi di wákàtí kẹsàn-án, nígbà tí Oòrùn kò ràn. Aṣọ ìkélé tẹmpili sì ya sí méjì.” Lúùkù 23:44-45(ESV)

Bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù ṣe ń tẹ̀ síwájú, ọ̀kan lára ​​àwọn àníyàn ńláǹlà nínú ètò ẹ̀sìn àwọn Júù ni pé, ó farahàn, ó sọ pé òun yóò wó tẹ́mpìlì, yóò sì tún un kọ́ ní ọjọ́ mẹ́ta (Jòhánù 2:19).Ní tòótọ́, èyí jẹ́ ọ̀kan lára ​​àwọn ẹ̀sùn pàtàkì tí wọ́n fi kàn án (Maku 14:58). Nígbà tí Jésù wà lórí àgbélébùú, nígbà náà, àwọn tí ń kọjá lọ fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì ń kígbe pé,“‭ “Ìwọ tí yóo wó Tẹmpili, tí yóo tún un kọ́ ní ọjọ́ mẹta, gba ara rẹ là. Bí Ọmọ Ọlọrun bá ni ọ́, sọ̀kalẹ̀ kúrò lórí agbelebu.”(MATIU 27:40). Ṣùgbọ́n níbè ló wà, ní orí igi àgbélébùú, nínú òkùnkùn.

Àti pé nígbà náà, ní àárín òkùnkùn àti ìdàrúdàpọ̀ tí wọ́n kàn mọ́ àgbélébùú, lójijì, ohun àràmàǹdà àti àìròtẹ́lẹ̀ kan ṣẹlẹ̀: Ọlọ́run fúnra rẹ̀ tún tẹ́mpìlì paa lè.

Lúùkù sọ fún wa pé: “Aṣọ ìkélé tẹmpìlì náà sì ya sí méjì. Èyí gan-an ni aṣọ ìkélé tí wọ́n so sínú tẹmpìlì láti fi ìṣàpẹẹrẹ dí ọ̀nà tó lọ sí iwájú Ọlọ́run. Ó jẹ́ àmì ńlá pé àwọn ènìyàn tí kọ̀ mọ́ kò le wá ní ààyè kanna pẹ̀lú Ọlọ́run mí mọ́. Ní gbogbo Ìwé Májẹ̀mú láéláé, ẹnikẹ́ni tí ó bá tí ati yàn láti wá sí iwájú Ọlọ́run láì ṣe àkíyèsí àwọn ìlànà ayẹyẹ ìṣọdi mímọ́ àti ṣíṣe àwọn ìrúbọ tí ó yẹ ti kú (fún àpẹẹrẹ, Nọmba 3: 2-4). Ṣùgbọ́n ní báyìí, lójijì, bí Jésù ti sún mọ́ etí ikú, àmì ìyàsọ́tọ̀ sí pa run. Nípa pé ó ti pa run, Ọlọ́run kéde pé àṣà àwọn àlùfáà àtijọ́ fún iwọle sí iwájú Rẹ̀ ti dópin, àti ìdènà ẹ̀ṣẹ̀ tí ń pín awon ènìyàn níyà kúrò lọ́dọ̀ Ẹlẹ́dàá wọn ti parẹ́. Kò sí ìdí kankan mọ́ láti jìnnà sí Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, “a ní ìgbọ́kànlé láti wọ ibi mímọ́ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jésù, nípa ọ̀nà tuntun àti àyè tí ó ṣí sílẹ̀ fún wa nípasẹ̀ aṣọ ìkélé” (Hébérù 10:19-20).

Láti ní àyè sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kò ní ṣe pẹ̀lú tẹmpìlì tàbí ilé ìjọsìn, tàbí ilé èyíkéyìí, tàbí kó gbọdọ̀ jẹ́ nípàṣẹ àlùfáà tàbí ọmọwé kan. Rárá, ní ẹgbẹ́wá ọdún sẹ́yìn, Ọlọ́run tún ìtàn ko láti fìdí ọ̀nà tí ó tọ́ sí ara rẹ̀ múlẹ̀ nípasẹ̀ Jésù. Báyìí “alárinà kàn ló wà laarin Ọlọ́run àti ènìyàn, ọkùnrin náà ni Jésù kirisiti, ẹni tí ó fi ara rẹ̀ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà fún gbogbo ènìyàn” (1 Timothy 2:5-6). Aṣọ títa tẹmpìlì tí ó ya sí méjì jẹ́ Ìdibàjẹ́ àtọ̀runwá fún ọ! O kọ̀ ní láti ni gbójú lé àwọn àlùfáà àti àwọn ìrúbọ mọ́. Wọ́n le jẹ́ nǹkankan mọ́ bí kò ṣe asán. Kàkà bẹ́ẹ̀, o lè wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí o ti rí, ní ìdánilójú pé o le wá sí ọ̀dọ̀ rèé pẹ̀lú àánú àti ìrànlọ́wọ́, gbogbo rẹ̀ nítorí Jésù.

  • Báwo ni Ọlọ́run ṣé ń pè mí láti ronú lọ́nà tí ó yàtò?
  • Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń tún àwọn ìfẹ́ni ọkàn mi tò —ohun tí mo nífẹ̀ẹ́?
  • Kí ni Ọlọ́run ń pè mí láti ṣe bí mo ṣe ń lọ pẹ̀lú iṣẹ́ òjó mí lónìí?

Nípa Ìpèsè yìí

The Man on the Middle Cross: A 7-Day Easter Reading Plan

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ènìyàn ni ó gbà pé ayé yìí ti di ìdíbàjẹ́. Àmọ́ tí ọ̀nà àbáyọ bá wà nkọ́? Ètò àjínde ọlọ́jọ́ méje yìí bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìrírí àrà ọ̀tọ̀ tí olè orí àgbélébùú, ó sì ṣe àgbéyẹ̀wò ìdí tí ìdáhùn tòótọ́ kan ṣoṣo sí ìdíbàjẹ́ fi wà ní inú pípa ọkùnrin aláìsẹ̀ kan: ìyẹn Jésù, Ọmọ Ọlọ́run.

More

A mú ìfọkànsìn láti inú ‘Truth For Life,’ ìwé ìfọkànsìn ojoojúmọ́ tí Alistair Begg kọ, tí The Good Book Company sì tẹ̀ jáde, thegoodbook.com. Truth For Life lò ó pẹ̀lú àṣẹ. Àṣẹ-Olóhun (C) 2022, The Good Book Company. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://tfl.org/365