Ọkùnrin Orí Àgbélébùú Àárín: Ètò Bíbélì Ọlọ́jọ́ Méje Tí ÀjíndeÀpẹrẹ

LÁTI INÚ ÒJÌJI
“Ọkùnrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jósẹ́fù, ará Arimatea tí àwọn Júù. Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀, ènìyàn réré àti olódodo, tí kò gba ìpinnu àti ìṣe wọ́n; ó sì ń wá ìjọba Ọlọ́run. Ọkùnrin yìí lọ sọ́dọ̀ Pílátù ó sì béèrè fún òkú Jésù.” LUKU 23:50-52 (ESV)
Isinku Jesu kii ṣe òún tí a ti parí tàbí gbàgbé sẹ́hìn fun awọn ìdí pàtàkì méjì. Àkọ́kọ́, kíkàn àwọn ọ̀daràn mọ́ àgbélébùú kì í sábà máa ńjẹ́ ìparí ìtìjú wọn; Wọ́n sábà máa ń jẹ́ kí wọ́n má bọlá tó yẹ fún ìsìnkú wọn. Ìkejì, ìyọ̀ǹda òkú náa sinmi lé ìbátan tàbí ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan tí ó béèrè fún àye láti sin òkú náà—àti ta ni ó ṣẹ́ku láti sìn Jésù? Àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà ti sá, ogúnlọ́gọ̀ náà ti fọ́n ká, àwọn obìnrin kò sì múra sílẹ̀ láti ṣe irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀.
Ní àkókò itàn-akọọ́lẹ yìí, ènìyàn kán farahàn l'ojijì àti ní ìdakẹjẹ—ẹníkan tí o “jẹ́ ọmọ-ẹ̀hin Jésù, ṣùgbọ́n ní ìkọkọ nítorí ìbẹrù àwọn Ju.” (John 19:38).
Ẹ̀rù ti pa Jósẹ́fù ará Arimatia lẹ́nu mọ́ títí di àkókò yìí. Ìgbésí ayé Jésù àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ ti fà á mọ́ra ó sì mú un wá sínú ìgbàgbọ́ ìgbàlà, ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣì wà ní ìkọ̀kọ̀. Ó ń ṣe iṣẹ́ ẹ̀mí rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀—ìyẹn ni, títí tí àgbélébùú fi mú un jáde sí gbángba. Nítorí náà, lẹ́yìn píparọ́ nínú òjìji fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, Jósẹ́fù “lọ sí ọ̀dọ̀ Pílátù ó sì béèrè fún òkú Jésù.”
Ìtàn Ìhìn Rere ṣàpèjúwe bí Jósẹ́fù ṣe fọwọ́ pàtàkì mú òkú Jésù bí ó ṣe “sọ̀ ọ́ kalẹ̀” kúrò lórí àgbélébùú, “fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dì í, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì tí a gbẹ́ sínú òkúta, níbi tí a kò tíì tẹ́ ẹnì kan sí rí.” (Luku 23:53). Bákan náà ni a kà nípa Nikodémù, “ẹni tí ó ti wá sọ́dọ̀ Jésù ní òru tẹ́lẹ̀ . . . o mú àdàpọ̀ òjíá àti álóè wá” láti ran Jósẹ́fù lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìnkú náà. (John 19:39).
Ìrísí kúkúrú àti ẹyọkan ṣoṣo tí Jósẹ́fù ní tún jẹ́ ìránnilétí tó ṣe kedere sí wa nípa iṣẹ ìpèsè Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà àti ní ibi gbogbo. Ọlọ́run ṣe ìpèsè Jósẹ́fù sílẹ fún àkókò yíì gan-an. Jósẹ́fù bẹrù o sì farapamọ, ṣùgbọ́n Ọlọ́run lo fún réré, gẹgẹ bí O ti ńṣe fún wa. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àǹfààní ni Jósẹ́fù tí pàdánù láti dúró ti Ọba rẹ̀; o lè ti pa ẹnu mọ ní ọ̀pọlọpọ ìgbà nígbàtí o yẹ ki o ti s'ọ̀rọ̀ síta. Síbẹ ọkùnrin yìí ni Ọlọ́run rí dájú wípé yóò wà ni ọjọ́ yii fún iṣẹ́ pàtàkì yìí. Jósẹ́fù sí dìde sí i, o fi ohùn gbogbo wéwu—ipò rẹ̀, okiki rẹ̀, ati ààbò—láti bu ọlá fún Jésù nípa ríridaju wípé Òun ní ìsìnkú titọ.
O lè rí i wípé o nfi ojú jọ Jósẹ́fù: o ń gbé gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn ìkọ̀kọ̀, pẹlú igbàgbọ́ ṣùgbọ́n ó bẹ̀rù láti jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ní àdúgbò tàbí níbi iṣẹ́ mọ̀ nípa ìgbàgbọ́ rẹ. Ti o ba jẹ bẹ́ẹ, nigbanà lóni, béèrè l'ọwọ Olúwa Jésù Krísti láti d'áríjì ìbẹrù rẹ́ ati fún ọ l'anfààní, gẹgẹbí Jósẹ́fù nínú imọlẹ̀ àgbélèbú, kí o le dúró ni ìgboyà fún Krísti nínú ifẹ Rẹ̀. O le ti pàdánù àwọn àkókò tí o ti rekọjá nígbàti o ni ayé láti dúró fún Obá rẹ, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ṣe'tán nígbàgbogbo láti fún ọ ní iṣẹ́ bíbu-ọlá fún Ọmọ Rẹ̀, àti wípé iwọ ko ní láti pàdánù ànfàní míràn.
- Báwo ní Ọlọ́run ṣe ń pe mí láti ronú yàtọ̀?
- Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń ṣe atúnto àwọn òun ìfẹ ọkàn mi—ohun tí mo nífẹ̀ẹ́?
- Kí ni Ọlọ́run ń pè mí láti ṣe bí mo ṣe ń lọ l'ọjọ́ óní?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ènìyàn ni ó gbà pé ayé yìí ti di ìdíbàjẹ́. Àmọ́ tí ọ̀nà àbáyọ bá wà nkọ́? Ètò àjínde ọlọ́jọ́ méje yìí bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìrírí àrà ọ̀tọ̀ tí olè orí àgbélébùú, ó sì ṣe àgbéyẹ̀wò ìdí tí ìdáhùn tòótọ́ kan ṣoṣo sí ìdíbàjẹ́ fi wà ní inú pípa ọkùnrin aláìsẹ̀ kan: ìyẹn Jésù, Ọmọ Ọlọ́run.
More