Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kí ni ó sọ?
Àwọn ọ̀tá ń fi ìgbà gbogbo ni Ísírẹ́lì lára. Onísáàmù náà ké pe àánú Ọlọ́run, ó rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti fi ìrètí wọn sínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti sínú ìfẹ́ tí kìí kùnà. Dáfídì fi ìrẹ̀lẹ̀ ṣe ìrètí nínú Olúwa, pẹ̀lú.
Kí ni ó túmọ̀ sí?
Sáàmù 129 àti 130 ni Hẹsíkáyà kọ ní ọ̀ọ́dúnrún [300] ọdún lẹ́yìn tí Dáfídì, gẹ́gẹ́ bíi ọ̀dọ́ olùṣọ́ àgùntàn, kọ Sáàmù 131. Àdúrà ọba Hẹsíkáya dá lóríi ìhalẹ̀mọ́ni méjì – sí Ísírẹ́lì àwọn ọ̀tá láti òde ibodè rẹ̀ àti ẹ̀ṣẹ̀ nínú orílẹ̀-èdè náà fúnra rẹ̀. Gbígbé sáàmù kúkúrú Dáfídì tààrà lẹ́hìn ígbé àìní ìrètí Hẹsíkáyà kìí ṣe ní àìròtẹ́lẹ; ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ tilẹ̀ yá n'inú ọ̀rọ̀ ọ̀dọ́mọ̀de Dáfídì, “Ísírẹ́lì, gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Olúwa.” Ísírẹ́lì nílò níwájú Olúwa, irúfẹ́ê ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn tí ó ta yọ nínú ọba wọ́n nlá jùlọ. Ọlọ́run olódodo àti aláàánú wọn ni ó jẹ́ tẹ́lẹ̀ – tí Ó sì jẹ́ nísinsìnyí – ẹnìkan ṣoṣo tí ó lè dáàbò bò tí yóò sì rà wọ́n padà.Bawo ni kí n ṣe dahun?
Ìgbà mélo ni o gba àdúrà fún orílẹ̀-èdè wá? A nílò àwọn aláàdúrà oníwà-bíi-Ọlọ́run ju ti àṣẹ̀hìnwá lọ. Bíi ti Ísírẹ́lì nígbà ayé Hẹsíkáyà, ojoojúmọ́ ni à ń rán wa létí àwọn orílẹ̀-èdè tí ìkórìíra wọn sí orílẹ̀-èdè wa ń sún wọn láti wá ìparun wa. Ìgbéraga àwọn ará ìlú àti ìṣọ̀tẹ̀ rírorò sí Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ jẹ́ ìparun bákan náà. Ìfẹ́ Ọlọ́run kì í kùnà, ṣùgbọ́n òdodo rẹ̀ òún ìwà mímọ́ kò ní fi ààyè gba ẹ̀ṣẹ̀. Àánú àti idáríjì Rẹ̀ nìkan ni ìrètí wa. Ẹ jẹ́ kí á se ọ̀kán nínú ìfẹ́ wa fún orílẹ̀-èdè wa, “Naijiria, fi ìrètí rẹ lé Olúwa!”
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More