Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kí ni ó sọ?
Onísáàmù náà ké pe Ísráẹ́lì láti yin orúkọ Olúwa àti láti fi ìyìn fún Ọlọ́run Ọ̀rún. Ìfẹ́ Rẹ̀ (anu) dúró láíláí.
Kí ni ó túmọ̀ sí?
Òǹkọ̀wé náà kò leè ní àmúmọ́ra ọkàn ayọ̀ rẹ̀ tí ó bú yọ ní ìgbà tí ó p'èrò títóbi Ọlọ́run. Olúwa ni Ó dá ohún gbógbó, Ó sì jẹ́ Ọbá l'órí ohún gbógbó. Àwọn èrò ìwà ìyanu Ọlọ́run, àwọn iṣẹ̀da agbára nlá Rẹ̀, ohun ìtúsílẹ̀ ìyanu Rẹ̀, ààbò àti àbójútó Ísráẹ́lì mú kí ó gbé ohùn àwọn orin ìyìn àti ọpẹ́ s'ókè. Ó rí kìkì ìwà òmùgọ̀ pátápátá tí sísin àwọn ọlọ́run tí a fi ọwọ́ ènìyàn ṣe jásí. Ísírẹ́lì sìn Ọlọ́run tí Ó ń k'àánú, Onífẹ̀ẹ́, Aláàánú, àti Ọlọ́run ayérayé. Onísáàmù náà rọ àwọn tí ó yí i ká wípé kí wọ́n yín Ọlọ́run fún Ẹni tí Ó jẹ́, kí wọ́n sì máa dúpẹ́ fún ohun tí Ó ṣe.
Báwo ni kí ń ṣe dáhùn?
Ìyìn àti ìdúpẹ́ rẹ fi ìbùkún fún Ọlọ́run. Kò nílò rẹ̀, sùgbọ́n Ó nífẹ́ láti gbọ. Lo àkókò díẹ̀ láti ronú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ àti ohún tí Ó ti ṣe fún ọ tìkárárẹ. Ǹjẹ́ ìwọ, gẹ́gẹ́ bíi òǹkọ̀wé sáàmù wọ̀nyí, rí ìṣòtítọ́ Ọlọ́run bí Ó ti bá ọ rìn bí? Àwọn orin wo ní ó máa ń mú ọ wá rìrì, ṣí ọ létí láti jọ́sìn, àti láti yin Ọlọ́run lógo? Kọ àwọn orín wọ̀nyí s'ókè fún ara rẹ ní àkókò ìdájọ́sìn rẹ ní àárín ọ̀sẹ̀ yìí ní ilé tàbí nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ. Ní òní, jẹ́ kí àwọn ìṣesí, àwọn ọ̀rọ̀, àti àwọn ìṣé rẹ fi hàn wí pé o ṣe ìdánimọ̀ àwọn ìwà nlá ràbìtì Ọlọ́run pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún iṣẹ́ tí Ó gbé ṣe nínú ìgbésí ayé rẹ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More