Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 96 nínú 106

Kí ni ó sọ?

Dáfídì búra láti kọ́ ibùgbé fún Ọlọ́run, Ọlọ́run sì ṣe ìlérí wí pé àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ ọba títí láé bí wọ́n bá tẹ̀lé E. Ó yẹ kí àwọn ènìyàn Ọlọ́run máa yìn ín nínú ibi mímọ́ Rẹ̀, kí wọ́n sì wà ní ìṣọ̀kan.

Kí ni ó túmọ̀ sí?

Àwọn Sáàmù mẹ́ta tí ó kẹ́yìn nínú Àwọn Orin Gíga Jù Lọ darí àfiyèsí Ísírẹ́lì sí àárín gbùngbùn ìjọsìn Ísírẹ́lì—tẹ́ńpìlì. Ẹ̀jẹ́ Dáfídì láti kọ́ ilé fún Ọlọ́run wúwo ní ọ́kàn rẹ̀ ní àwọn ọdún àkọ́kọ́ ìjọba rẹ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ kọ́ tẹ́ńpìlì náa, ibi gbígbé Ọlọ́run, ní ibi tí àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ń pé jọ ní ìṣọ̀kan láti jọ́sìn. Idí ti wọ́n fi ń wọ́pọ̀ ni láti kọ orin ayọ̀, wá Ìbùkún Olúwa, àti láti yìn Ín gẹ́gẹ́ bíi Ẹlẹ́da ọ̀run òun aye. Onísáàmù náà tún àwọn ìlérí Ọlọ́run sọ nípa ígbà tí Ó yan Ísírẹ́lì láti jẹ́ ènìyàn Rẹ̀, àti Dáfídì láti jẹ́ ọba Rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ipò tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbọràn àti níní ìfẹ́ Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Olúwa ìyè wọn.

Báwo ni kí ń ṣe f'èsì?

Àwọn ohun nlá lè ṣeéṣe ní ìgbà tí ìdílé tàbi àwon ọmọ ẹgbẹ́ agbègbè bá ńgbé pẹ̀lú ìpinnu ìṣọ̀kán. Èyíkéyìí àwùjọ tí ó bá fi irúfẹ́ àlàáfíà àti ìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀ hàn, ó yẹ kí ó jẹ́ ìjọ Jésù Kristi. Ìdí wo ni o ní lọ́kàn bí o ṣe ńlọ sí ilé ìjọsìn ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀? Njẹ́ ọkàn rẹ kún fún àníyàn ẹbi, àwọn iyàtọ̀ kékèèké láàrín àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ijọsin, tàbi àwọn àyè nẹtiwọki fun ìṣòwò rẹ? Gẹ́gẹ́ bíi ènìyàn Ọlọ́run, ó yẹ kí a mọ iyì àkókò tí à ń lò papọ̀ nínú ìjọsìn. A lè máa ní òmìnira ẹsìn ní ìgbà gbogbo láti kó jọ ní orúkọ Jésù. Súnmọ́ ìjọsìn ní ọ̀sẹ̀ yìí pẹ̀lú ayọ̀ àti ní ẹ̀mi àlàáfíà òún ìṣọ̀kan pẹ̀lú áwọn onígbàgbọ́ míràn. Ní àpapọ̀, a lè ṣe àwọn ohun nlá fún Olúwa.

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org