Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 99 nínú 106

Kíni ó sọ?

Dáfídì yín Ọlọ́run fún òtítọ́ àti ìfẹ́ Rẹ̀ láàrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà.

Kíni ó túmọ̀ sí?

Kò sí ìdánilójú pàtó ìgbà tí Dáfídì kọ Sáàmù yìí, ṣùgbọ́n àwọn ohun tí ó là kọjá dá'ni l'ójú. Àwọn ọ̀tá yí i ká, ó sì wà ní ibi tí ó jìnà réré sí Jerúsálẹ̀mú ní ilẹ̀ tí ó kún fún ọlọ́run àjèjì. Sibẹsibẹ náà láàrin wàhálà, ìgbé-ayé Dáfídì nínú ẹ̀mí ń lọ geere. Ìfẹ́ Ọlọ́run tí kìí yẹ̀ ní àkókò ìṣòro yìí fún un ní okun àti ìwúrí láti jọsin fún Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ẹ̀mí rẹ̀. Irú ohun tí ó ń lá kọjá kò yí ìpinnu Ọlọ́run fún ayé rẹ̀ padà ṣùgbọ́n ó fún un ni ìdí pàtàkì láti túnbọ̀ yin Ọlọ́run Ísráẹ́lì níwájú àwọn ọba tí kò mọ Ọlọ́run. Àwọn ìdojúkọ tí Dáfídì ní ń peléke síi éléyi túnbọ̀ ṣe àlékún òye Dáfídì nípa bí Ọlọ́run ṣe ni ótítọ́, àánú, ìwà-mímọ́ àti ìfẹ́.

Báwo ni kí ń ṣe dáhùn?

Àwọn ìdààmú ayé le koko; bí ó ti wù kí ó rí, wọn kò gbọdọ́ jẹ́ kó rẹ̀wẹ̀sì. Ohunkóhun tí ì bá jẹ́, àwọn ìdíwọ́ tí ó wù kó dojú kọ ní láti fún ọ ní àǹfààní ńlá síi láti ní òye nípa ìwà Ọlọ́run. Ìrírí bí Ọlọ́run ṣe ń ṣiṣẹ́ ni ìgbé ayé ẹni kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ sí kíkà nípa oore-ọ̀fẹ́ àti àánú Rẹ̀ tàbí títẹ etí sí àwọn ìtàn láti ẹnu àwọn ọrẹ nípa òtítọ́ Rẹ̀. Inú irú àwọn wàhálà ayé wo ni o bá ara rẹ lónìí? Ǹjẹ́ o gbà wọ́n láàyè láti mú idà-dúró bá ìjọ́sìn àti ìrìn rẹ pẹ̀lú Olúwa? Ohun tí o níílò ni ìṣípòpadà tí ó yàtọ̀ pátápátá. Kọ̀ láti má wo ohun tí ó lòdì, kí o sì máa fi ojú sí ọ̀nà fún ọwọ́ ìfẹ́ àti òtítọ́ Ọlọ́run.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org