Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 98 nínú 106

Kíni o sọ?

Nígbà tí onísáàmù náà ń sọkún, àwọn ará Bábílónì tí wọ́n kó nígbèkùn nwípé kíó kọ orin Síónì.

Kíni o túmọ si?

Àwọn ọ̀rọ̀ Sáàmù yìí ni a kọ pẹlú ìbànújẹ́ ọkàn nígbà tí Ísírẹ́lì wà ní ìgbèkùn. Ó ṣe pàtàkì láti rántí wípé Ọlọ́run jẹ́ kí a lé àwọn ènìyàn Rẹ̀ kúrò ní ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn nítorí wípé wọ́n kọ̀ léraléra láti ronú pìwà dà. Nítorí náà, ṣe òǹkọ̀wé náà hára gàgà fún Jerúsálẹ́mù nítorí wípé o jẹ ìlú mímọ́ ti Ọlọ́run ń gbé tàbí nítorí wípé ó pàdánù ìgbé ayé ẹ̀ṣẹ̀ èyí tí ó ń gbé níbẹ̀? Ó gbé háàpù rẹ̀ kọ́, ó sì kọ̀ láti kọrin ní àkókò náà gan-an tí àwọn orin Síónì ò ba jẹ́ iranléti ìṣòtítọ́ Ọlọ́run, ohún tí yíò yi ọkàn Ísírẹ́lì padà sí Olúwa, àti ohún ijẹ́rì Ọlọ́run wọn níwájú àwọn kèfèrí tí ó kó wọn ní ìgbèkùn.

Báwo ni ó ṣe yẹ kín dáhùn?

O rọrùn púpọ láti jùmọ̀ kọrin ìyìn lori ẹ̀rọ rédio nígbàtí Ìbùkún Ọlọ́run ń han nínú ìgbésí ayé rẹ ju ìgbà ìbànújẹ tàbi ìgba ìbínú. Njẹ ohun kán jí ayọ rẹ? Máṣe dúró títí iwọ yíò fi rílara - tẹ́tísi orin lóni tí yóò rán ọ létí ifẹ àti òtítọ Ọlọ́run. Bí agbára rẹ láti yín Olúwa bá dá l'órí ipò rẹ, lẹhinna awọn akóko wa ti ọkàn rẹ yóò tútù. Bí ayọ̀ rẹ bá ńṣàn nípasẹ̀ mimọ Kristi ati ìgbe ayé èyí tí ó ṣe itẹlọ́run Rẹ̀, iwọ kì yóò jẹ aláìní orin kàn nínu ọkàn rẹ (Iṣe Àwọ́n Àpọ́stélì 16:25). Ìwọ yiò jẹ ìwúrí fún àwọ́n onígbàgbọ mìíràn àti ẹlẹ́rì ti o lágbára sí àwọ́n ti kò si nínu Kristi.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org