Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 94 nínú 106

Kí ni ó so?

A kò lè mì àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa. Pẹ̀lú omijé ni wọn yóò fi fúnrúgbìn, pẹ̀lú ayọ̀ yíyọ̀ ni wọn yóò sì ká a. Èrè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni àwọn ọmọ wọ́n jẹ́. Aláyọ̀ ni ènìyàn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀.

Kí ni ó túmọ̀ sí?

Apá yìí nínú ìwé Orin Ìgòkè ń sọ nípa ààbò, ayọ̀ àti ìbùkún tí áwọn ènìyàn àyànfẹ́ Ọlọ́run. Sáàmù 125 sọ bí Ọlọ́run ṣe máa ń dá ààbò bo àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀ lé E. Ààbò tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n wọ odi Jerúsálẹ́mù jẹ́ àpẹẹrẹ bí Ọlọ́run ṣe ń bójú tó wọn gẹ́gẹ́ bíi orílẹ̀-èdè kan. Sáàmù 126 rántí bí Ọlọ́run ṣe sọ omijé ìbànújẹ́ di orin ayọ̀ nígbà tí Ó gba Israẹli sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Asíríà (1 Àwọn Ọba 18-19). Sáàmù 127 tí Sólómọ́nì Ọba kọ, sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìbùkún tí ó wà nínú ìdílé tí ó ní Ọlọ́run àti ayọ̀ àwọn ọmọ. Ẹni tí ó kọ Sáàmù 128 ronú nípa iṣẹ́ aláyọ̀ àti ilé aláyọ̀ tí ẹni tí ó bẹ̀rù Olúwa tí ó sì ṣe ìgbọ́ràn sí Í ń gbé. Bí àwọn olùjọ́sìn ṣe ń gun òkè lọ sí orí àwọn òkè tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù, àwọn sáàmù wọ̀nyí rán wọn létí pé kí wọ́n máa bẹ̀rù Olúwa, kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé E, kí wọ́n sì máa ṣe ìgbọràn sí I nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe ní ìgbésí ayé wọn – gẹ́gẹ́ bíi ọmọ ìlú, gẹ́gẹ́ bíi ìdílé, àti gẹ́gẹ́ bíi òṣìṣẹ́.

Kí ni ó yẹ kí n ṣe?

Bí àwọn ènìyàn tí o máa ń bá pàdé lójoojúmọ́ bá sọ pé kí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa rẹ gẹ́gẹ́ bíi òbí, ọmọ, ègbọ́n tàbí àbúrò, òṣìṣẹ́, ọ̀gá, akẹ́kọ̀ọ́, tàbí ọmọ ìlú – kí ni wọ́n máa sọ? Bí o ṣe ń ṣe iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan tì a yàn fún ọ máa jẹ́ kí a mọ ẹni tí o jẹ́ gẹ́gẹ́ bíi ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi. Èwo nínú apá ìgbésí ayé rẹ ni kò fi ìdùnnú tí ó wà nínú ìgbẹ́kẹ̀lé àti ìgbọràn sí Olúwa hàn? Ronú nípa àwọn ìyípadà tí ó yẹ kí o ṣe nínú ilé, níbi iṣẹ́ tàbí ní ilé-ìwé kí o lè túbọ̀ máa fi ògo fún Ọlọ́run.

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org