Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 100 nínú 106

Kí ni ó sọ?

Oluwa wá Dáfídì, ó sì mọ̀ ọ́ patapata, kódà kí á tó bí i.

Kí ni ó túmọ̀ sí?

Sáàmù yìí bẹ̀rẹ̀ ó sì parí pẹ̀lú Olúwa tí ó ń wá ọkàn Dáfídì. Ọlọ́run mọ ohun gbogbo nípa rẹ; Ọlọ́run kọ̀ ìgbé ayé rẹ ojoojúmó sílẹ̀. Èrò rẹ̀, ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀ hàn kedere pátápátá níwájú Ọlọ́run. Dáfídì mọ̀ pé Ọlọ́run mọ̀ òun dáadáa ju bí òun ti mọ ara òun lọ, nítorí náà ó pe Olúwa láti wádìí òun dé lẹ̀ kí Ó tọ́ka sí ohunkóhun nínú ayé òun tí kò wù Ú. Ó fẹ́ rí ara rẹ̀ bí Ọlọ́run ṣe rí i kí ó lè ṣe àtúnṣe ohun tí kò tọ́. Dáfídì pa rọ́rọ́ ní ìyanu ìmọ̀ Ọlọ́run àti ìkópa Rẹ̀ nínú ayé rẹ̀.

Báwo ni kí n ṣe dáhùn?

Ọlọ́run mọ ohun gbogbo nipa igbesi aye rẹ. Ó wà níbẹ̀ kódà kí o tó mí èémí àkọ́kọ́ rẹ ó sì wà pẹ̀lú rẹ lónìí. Kíni èrò rẹ láti mọ̀ pé Ọlọ́run ríí, gbọ, Ó sì bìkítà nípa ohun gbogbo tí o rò, sọ, ati ṣe? Ìdáhùn náà dá lóríi bóyá òún gbé ní ìgbọràn lọ́wọ́ lọ́wọ́ sí Krístì. Ṣé wà á pe Ọlọ́run láti ṣàwárí ọkàn rẹ lónìí? Bíbẹ́ẹ̀kọ́, o lè di afọ́jú sí ibi tí o ti kùnà kí o sì gbiyanju lati fi ojú kéré awọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Ó gba ìgboyà láti wo ìgbésí ayé rẹ ní òtítọ́, gba àwọn àṣìṣe rẹ, kí o sì wá ìdáríjì Ọlọ́run. Ọkàn ati inú rẹ hàn kedere sí Olúwa, kíni idi tí o kò fi ní rí ara rẹ ní ọ̀nà tí Ó rí ọ? Nígbà tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, àgbàrá Rẹ̀ láti rí ohun gbogbo, mọ̀ ohun gbogbo jẹ́ ìtùnú - kìí ṣe àníyàn.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org