Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 93 nínú 106

Kíni o sọ?

Onísáàmù náà ké pe Olúwa, Ẹlẹ́dàá Ọ̀run àti Ayé, láti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ Ísírẹ́lì nínú ìdààmú àti láti fi àánú ṣọ́ wọn. Lílọ sí ilé Olúwa mú ayọ̀ wá.

Kíni ó tún mọ̀n sí?

Orin Dáfídì 120-134 ni Àwọn orin tí ń lo sí òkè(Àwọn ipele). Orin Dáfídì, Sólómọ́nì, àti Hesekáyà tí ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Hesekáyà yìí ni wọ́n kọ nígbà ìrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù fún àjọyọ̀ ọdọọdún. Nígbà tí àwọn ìdílé Israẹli bojú wo àwọn òkè tí ó yí Jerusalẹmu ká, wọ́n gbé ojú wọn sókè sí Olúwa, ẹni tí ó ń gbé inú tẹ́mpílì ìlú mímọ́ náà. Wọ́n lè rìn pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀ nítorí pé Ẹni tí wọ́n ń jọ́sìn tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ sí nínú irú ìdààmú èyíkéyìí ni Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo – Olùrànlọ́wọ́, Olùtọ́jú, àti Olùgbèjà wọn. Àǹfààní láti jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà ní gbangba mú ayọ̀ ńláǹlà wá.

Báwo ni kí ṣe dáhùn?

Níbo ni o kọjú sí fún ìrànlọ́wọ́? Kò sí ìṣòro tó le jù fún Olúwa. Ó ń dúró dè ọ́ láti wo ọ̀dọ̀ Rẹ̀ fún ohun gbogbo tí o nílò. Ọ̀nà kan láti gbé ojú rẹ sí Olúwa gẹ́gẹ́ bí Olùràn lọ́wọ́, Olùtọ́jú, àti Olùgbèjà ni nípa lílọ sí ilé ìjọsìn nígbà gbogbo. Ìjọsìn àjọṣe jẹ́ orísun okun ńlá fún ọ̀sẹ̀ tí ń bọ̀ bí ẹ ṣe ń pé jọ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ yín láti yin Ọlọ́run, kí ẹ sì jọ́sìn rẹ̀, tí ẹ sì ń fún ara yín níṣìírí. Ṣé o fi taratara dúró de àyè láti jọ́sìn ní gbangba pẹ̀lú àwọn ará ilé ìjọsìn rẹ bí? Ìdojúkọ àwọn èrò rẹ ní àárín ọ̀sẹ̀ lori ìhùwàsí Ọlọ́run àti òtítọ́ tí ó ti kọjá yóò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ ní ìfojúsọ́nà pẹ̀lú ayọ̀ láti fún ní ìyìn ní gban gba

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org