Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kíni o sọ?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣe inúnibíni sí onísáàmù náà láì nídìí, ó rí àlàáfíà nínú òfin Ọlọ́run. Ó ní kí Ọlọ́run gbọ́ ẹ̀bẹ̀ Òun láti wà láàyè kí òun lè kọrin ìyìn àwọn òfin òdodo Ọlọ́run.
Kíni ó tún mọ̀ sí?
Jálẹ̀ ìwé orin Dáfídì 119, ọ̀rọ̀ àti ìbéèrè òǹkọ̀wé náà jẹ́ ọ̀kan náà. Ó nífẹ̀ẹ́, ó gbẹ́kẹ̀ lé, ó sì ṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; àwọn tí kò kọbi ara sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lòdì sí i; ó bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run fún ìdáǹdè ó sì yin Olúwa láì bìkítà. Láàárín ìdàrúdàpọ̀ náà àti láìka inúnibíni sí, onísáàmù náà pinnu láti máa gbé ìgbé ayé ìgbọràn, kí ó máa gbàdúrà tọkàntọkàn, àti láti máa yìn ín nígbà gbogbo. Àlàáfíà àti ayọ̀ tí ó rí nípa mímọ́ àti ìfẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ju ohunkóhun mìíràn lọ dájúdájú ó kọjá òye ènìyàn - ó jẹ́ ohun tí ó ga julọ.
Báwo ni kí ṣe dáhùn?
Oun tí ó ti wà ní ọkàn wa gẹ́gẹ́bí ọmọlẹ́yìn Krístì tí ń lọ sí ilé ìjọsìn ni láti béèrè lọ́wọ́ àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ kékeré láti gbàdúrà fún wa nígbàtí àwọn ǹkan bá le, àti lẹ́hìn náà á fi ìyìn fún Olúwa ní kíákíá nígbàtí ọ̀rọ̀ náà bá yanjú. Ní báyìí ná, a sábà máa ń jẹ̀bi àníyàn tàbí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ dípò àdúrà onítara. Nínú ipò wo ni o ti rí kí onísáàmù náà kígbe fún ìrànlọ́wọ́ bí ase gbe yẹ̀wò ninu Psalm 119? Ṣé ìwọ yóò tẹ́lẹ̀ àpẹẹrẹ rẹ̀ láti gbé ní ìgbọràn, gbàdúrà pẹ̀lú ìtara, àti yín Ọlọ́run nígbà gbogbo - láì bìkítà ohun tí o dojúkọ àti bí ó ṣe pẹ́ tó láti dúró de Olúwa láti dáhùn? Àwọn àyídáyidà rẹ le darí rẹ kí o jinlẹ̀ sínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ju tí o ti wà tẹ́lẹ̀ lọ, láti fún ọ ní ìfẹ́ tí ó lágbára fún kíkà ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti fífún ọ ní àlàáfíà àti ayọ̀ tí ó ga jùlọ. Máse dẹ́kun gbígbàdúrà sí Olúwa àti ìgbọràn sí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀; máse dúró kí o tọ́ Yin
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More