Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kí ni ó sọ?
Olódodo li Olúwa; àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ jẹ́ òtító, Ó ṣeé gbẹ́kẹ̀lé, àti títí ayérayé. Òǹkọ̀wé náà da omijé lójú nítorí àìgbọràn sí òfin Ọlọ́run, ó fi ayé rẹ̀ lé àwọn ìlérí àti ìyọ́nú Ọlọ́run lọ́wọ́.
Kí ni ó túmọ̀ sí?
Ní gbogbo àyọkà yíì, Òǹkọ̀wé sọ ohun tí ó mọ̀ pé ó jẹ́ òtító nípa Ọlọ́run àti ọ̀rọ̀ Rẹ̀: Olúwa jẹ́ Olódodo tí Ó ṣì wà títí ayérayé; òtítọ́ ni àwọn ìlérí Rẹ̀; òfin Rẹ̀ tọ̀nà, a sì lè gbẹ́kẹ̀ lé ìtọ́ni Rẹ̀. Àdúrà àti ipò onísáàmù náà tako àwọn tí kò kọbi ara sí àwọn àṣẹ Ọlọ́run. O ní ìdí láti ní ìgboyà, bí ó ti lè jẹ́ pé àdúrà rẹ̀ wà láàrin ìfẹ́ Ọlọ́run ní'torí pé ó bèèrè lọ́wọ́ Olúwa láti ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ àti ìhùwàsí Rẹ̀. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ – tí ó sì ń bá a lọ láti jẹ́ – onígbọràn sí àwọn òfin àti àṣẹ Ọlọ́run, àwọn èrò àti ipò rẹ̀ tọ̀nà.
Báwo ni kí n ṣe dáhùn?
Àwọn èrò òṣèlú àti ìwà rere tí wọ́n ń gbé lárugẹ ń yí padà pẹ̀lú èrò inú ọjọ́ náà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ kò yí padà. Ọjọ́ kan ń bọ̀ ní ìgbà tí gbogbo ohun tí Ọlọ́run sọ nínú Bíbélì yóò wá sí imúṣe àti pé yóò jẹ́ òtítọ́. Títí di ìgbà yẹn, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní láti pinnu bóyá a óò lòdì sí ìgbì omi tí ó ń lọ lọ́wọ́, kí a sì dúró lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Iwọ ha ń kẹ́dùn nítorí aìbìkítà orílè-èdè wa fún àwọn òtítọ́ tí a ṣí payá nínú Ìwé Mímọ́ bí? Èrò, ìpinnu, tàbí ipò òṣèlú wo ni o nílò láti tẹrí ba fún ọlá-àṣẹ Ọ̀rọ̀ òdodo, Ọ̀rọ̀ ayérayé Ọlọ́run? Òtítọ́ ni Ọlọ́run, láì ka ohun tí àwùjọ rò sí. O lè fi ìgboyà gbé ìgbésí ayé rẹ lé àwọn ìlérí Rẹ̀ nígbà tí o bá yàn láti gbé nípa àwọn òfin Rẹ̀.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More